ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/04 ojú ìwé 1
  • Túbọ̀ Sún Mọ́ Àwọn Tí O Nífẹ̀ẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Túbọ̀ Sún Mọ́ Àwọn Tí O Nífẹ̀ẹ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 10/04 ojú ìwé 1

Túbọ̀ Sún Mọ́ Àwọn Tí O Nífẹ̀ẹ́

1 Àwọn wo ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó dájú pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Máàkù 12:30) Bí a bá wo gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lóòótọ́ ká sì fún un ní ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gédégbé. (Róòmù 5:8) Níwọ̀n bí Kristi Jésù ti jẹ́ Olùràpadà, Àlùfáà Àgbà àti Ọba wa, a nífẹ̀ẹ́ òun náà gidigidi. (1 Pét. 1:8) Ọkọ àti aya ní láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Éfé. 5:25, 33) Àwọn òbí ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì tọ́ wọn dàgbà ní ọ̀nà Jèhófà. (Títù 2:4) Bákan náà, gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ní láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn.—1 Pét. 1:22.

2 Èṣù ń sapá láti mú ká yẹra fún àwọn tó yẹ ká nífẹ̀ẹ́. Kí Èṣù lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn yìí, ó máa ń lo onírúurú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àti ọgbọ́n àrékérekè. Bí àpẹẹrẹ, ó lè lo kíkópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbòkègbodò ayé láti fi pín ọkàn wa níyà débi pé a ò ní fi bẹ́ẹ̀ máa rí àyè lọ sí ìpàdé tàbí òde ẹ̀rí. Tàbí kẹ̀, ó lè mú ká dẹni tó ń lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí wíwo tẹlifíṣọ̀n, wíwo fídíò, kíka lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tàbí fífi í ránṣẹ́, tàbí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí ló wá yẹ ká ṣe nígbà tí àwọn èèyàn ayé bá fẹ́ tì wá ṣe ohun tí ò tọ́ tàbí tí ìdẹwò bá dé bá wa?

3 Ó yẹ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì kọjú ìjà sí Èṣù. (Ják. 4:7, 8) Bí a ṣe túbọ̀ ń kà nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tí a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, ìmọrírì wa fún àwòkọ́ṣe tó fi lélẹ̀ fún wa yóò jẹ́ ká túbọ̀ tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (1 Pét. 2:21; Jòh. 4:34) Nínú ìdílé, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ìwà kan táwọn èèyàn ayé ń hù, ìyẹn ni pé kí kálukú máa dá nǹkan tiẹ̀ ṣe. Ńṣe ló yẹ kí ìdílé gbìyànjú láti máa wà pa pọ̀ kí wọ́n sì jọ máa ṣe nǹkan pọ̀.—Diu. 6:7.

4 Gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ ni Ọlọ́run ń kọ́ pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa ká sì máa jẹ́ kí ìfẹ́ yìí jinlẹ̀ sí i, ìyẹn ni pé a ní láti túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Gál. 6:9, 10; 1 Tẹs. 4:9, 10) Láti fi ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí sílò, ó yẹ ká máa lọ sí ìpàdé ká sì máa jáde òde ẹ̀rí déédéé, ká sì tún máa lọ kí àwọn ará wa nílé láti gbé wọn ró. Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa túbọ̀ rọrùn fún wa láti ṣe ohun tó tọ́ nígbà tí ìṣòro èyíkéyìí bá yọjú.

5 Ìdánwò yòówù kó bá wa tàbí ipò yòówù ká bá ara wa, bí a bá dúró ti Jèhófà, kì yóò fi wá sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní kọ̀ wá sílẹ̀. (Héb. 13:5) Kristi Jésù ṣèlérí pé òun yóò wà pẹ̀lú wa títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan yìí. (Mát. 28:20) Ìfẹ́ tó wà láàárín tọkọtaya á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i bí wọ́n bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tí wọ́n sì fìmọ̀ ṣọ̀kan, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro inú ayé.

6 Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò túbọ̀ sún mọ́ àwọn tá a nífẹ̀ẹ́. Ó yẹ ká máa ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà nínú ìjọ. Bákan náà, ó yẹ ká máa fi ìfẹ́ àtọkànwá bá ara wa lò bí òpin ètò ògbólógbòó yìí ṣe ń yára sún mọ́lé.—Héb. 10:23, 24;1 Pét. 4:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́