Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 11
Orin 53
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù October sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ October 15 àti Jí! November 8 lọni. (Àbá kẹta ni ká lò láti fi Jí! November 8 lọni.) Rọ àwọn ará pé kí wọ́n máa ka Ìwé Mímọ́ nígbà tí wọ́n bá ń fi ìwé lọni. A tún lè fi ìwé ìròyìn lọni láwọn ọ̀nà mìíràn.
20 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí Lọ́dún Tó Kọjá? Kí alàgbà kan sọ àsọyé lórí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ìjọ fún ọdún iṣẹ́ ìsìn 2004. Sọ àwọn ohun tó wúni lórí gan-an nínú ìròyìn náà, kó o sì yin àwọn ará fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe. Mẹ́nu kan iṣẹ́ aláápọn táwọn aṣáájú ọ̀nà ṣe. Sọ ohun kan tàbí méjì tí ìjọ lè ṣe láti tẹ̀ síwájú ní ọdún tó ń bọ̀.
15 min: Jẹ́ Kó Máa Wù Ọ́ Láti Ṣèrànwọ́ Fáwọn Èèyàn. (Jòh. 4:34) Ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò. Inú wa máa ń dùn tá a bá rí i tí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí ẹnì kan ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń mú inú rẹ̀ dùn. (w94-YR 3/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 6 àti 7) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde tàbí aṣáájú ọ̀nà méjì tàbí mẹ́ta, tí wọ́n máa ń lo Bíbélì lọ́nà tó múná dóko lóde ẹ̀rí, tí wọ́n sì mọ bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì máa darí rẹ̀. Kí ni wọ́n máa ń ṣe láti fi ran àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú? Báwo lèyí ṣe ń fún wọn láyọ̀? Sọ pé kí wọ́n sọ ìrírí tí wọ́n ní lóde ẹ̀rí tàbí kí wọ́n ṣe àṣefihàn àwọn ìrírí náà.
Orin 69 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 18
Orin 127
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
18 min: Àwọn Tó Ń Rí Iṣẹ́ Àtàtà Wa. (1 Pét. 2:12) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 1, 2002, ojú ìwé 12 sí 14, ìpínrọ̀ 14 sí 20. Sọ pé kí àwùjọ sọ bí àwọn iṣẹ́ àtàtà tá à ń ṣe ṣe ń nípa lórí àwọn ará àdúgbò tí wọ́n ń rí wa.
22 min: “Ní Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Tí Wàá Máa Lépa Láti Fi Yin Ẹlẹ́dàá Rẹ Lógo.”a Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ.
Orin 165 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 25
Orin 56
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù October sílẹ̀. Lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (bí wọ́n bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ November 1 àti Jí! November 8 lọni. (Àbá kẹrin ni ká lò láti fi Jí! November 8 lọni.) Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ káwọn ará mọ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a lè gbà fèsì ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn fi ń dènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yìí: “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 9.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
18 min: Máa Fi Ẹ̀rí Ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lẹ́yìn. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 256 àti 257. Báwo la ṣe lè lo ẹ̀rí tó wá láti ibòmíràn yàtọ̀ sí Bíbélì láti fi jẹ́ káwọn èèyàn rí bí ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ ti bọ́gbọ́n mu tó? Rọ àwùjọ pé kí wọ́n dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Àwọn àpẹẹrẹ wo la lè tọ́ka sí lórí ilẹ̀ ayé àti lójú ọ̀run láti fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà? (cl-YR orí karùn-ún) Báwo la ṣe lè lo àlàyé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àtàwọn ògbógi láti fi jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé lóòótọ́ ni Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (ba-YR ojú ìwé 14 sí 21) Àkàwé wo la lè lò láti fi jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi? (kl-YR ojú ìwé 75 àti 76) Àwọn ìrírí tàbí àpẹẹrẹ wo lo máa ń lò láti fi jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé fífi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò bọ́gbọ́n mu?
Orin 62 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 1
Orin 15
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lóṣù November, ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la ó fi lọni. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn àbá tá a dá nípa ọ̀nà tá a lè gbà fi ìwé yìí lọni nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2004, ojú ìwé 7, kó o sì ṣàṣefihàn ọ̀kan lára àwọn ìgbékalẹ̀ náà. Bó bá jẹ́ pé ọ̀nà mìíràn ló máa dára jù láti gbà fi ìwé yìí lọni ní ìpínlẹ̀ ìjọ, a lè sọ̀rọ̀ lórí èyí ká sì ṣàṣefihàn rẹ̀. Sọ pé kí àwùjọ sọ bí wọ́n ti ṣe lo ìwé yìí lóde ẹ̀rí, bí àkókò bá ṣe wà sí.
15 min: “Iṣẹ́ Tí Ọlọ́run Ń Tì Lẹ́yìn.”b Fi àlàyé kún un látinú ìwé Proclaimers, ojú ìwé 547 àti 548.
20 min: “Túbọ̀ Sún Mọ́ Àwọn Tí O Nífẹ̀ẹ́.”c Sọ pé kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ bí àkókò bá ṣe wà sí.
Orin 115 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.