Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tí a ó fi lọni ní November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la ó fi lọni. Bí ẹni tó ò ń wàásù fún bá sọ pé òun ò lọ́mọ, fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Gbìyànjú láti fi ìwé pẹlẹbẹ yìí bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní, Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì, Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí, a lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, àti Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ní àkáǹtì mìíràn tẹ́ ẹ̀ ń lò fún títọ́jú owó àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí owó kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, ẹ rí i pé ẹ ṣàyẹ̀wò èyí náà pẹ̀lú. Bí ẹ bá ti ṣàyẹ̀wò àkáǹtì tán, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ nígbà tí ẹ bá tún fẹ́ ka ìròyìn ìnáwó.
◼ Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí ní àkọsílẹ̀ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù gbogbo alábòójútó olùṣalága àti akọ̀wé tó bágbà mu. Bí ìyípadà bá wà nígbàkigbà, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tó bágbà mu sínú fọ́ọ̀mù Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29) [Ìyípadà Àdírẹ́sì Alábòójútó Olùṣalága àti Akọ̀wé], kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́gán. Èyí kan ìyípadà tó bá wà nínú area code [nọ́ńbà tẹlifóònù àgbègbè kọ̀ọ̀kan].