ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/04 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 29
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 11/04 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 8

Orin 180

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lóṣù November, ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè la ó fi lọni. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn àbá tá a dá nípa bá a ṣe lè fi ìwé yìí lọni, nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2004, ojú ìwé 7.

15 min: Jàǹfààní Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 71 àti 72. Ọ̀nà márùn-ún wo ni Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lè gbà ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́nà tó túbọ̀ dáa sí i? Sọ àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ oṣù yìí. Kí làwọn àǹfààní tó wà nínú mímúrasílẹ̀? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wà ní ìpàdé yìí déédéé? Àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa àwọn tó ṣe irú ìpàdé yìí?

20 min: “Má Ṣe Fi Iṣẹ́ Ìwàásù Falẹ̀!”a Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ January 15, 2000, ojú ìwé 12 àti 13.

Orin 19 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 15

Orin 170

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù November sílẹ̀. Bí àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, lò wọ́n láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ November 15 àti Jí! December 8 lọni. (Àbá kẹta ni ká lò láti fi Jí! December 8 lọni.) A tún lè ṣe àwọn àṣefihàn mìíràn tó ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ.

15 min: Ǹjẹ́ O Mọ̀ Pé Ayọ̀ Wà Nínú Ṣíṣètọrẹ? Àsọyé tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 1, 2004, ojú ìwé 19 sí 23.

20 min: Múra Sílẹ̀ Láti Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, tí a gbé ka Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2003, ojú ìwé 3. Ṣètò pé kí àwọn díẹ̀ sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Ní ṣókí, ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìléwọ́ Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? àti ìwé pélébé náà Good News for All Nations nígbà tá a bá ń wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà.

Orin 211 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 22

Orin 199

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Béèyàn Ṣe Lè Ní Ojúlówó Ìfẹ́.” Àsọyé tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 1, 2003, ojú ìwé 4 sí 7.

Orin 115 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 29

Orin 23

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù November sílẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ December 1 àti Jí! December 8 lọni. (Àbá kẹrin ni ká lò láti fi Jí! December 8 lọni.)

10 min: Àpótí Ìbéèrè. Kí alàgbà sọ ọ́ bí àsọyé.

25 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kẹta.”b Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti sọ̀rọ̀ lórí ìpínrọ̀ 3, jẹ́ kí á fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, ẹ̀kọ́ 5, ìpínrọ̀ 1 ṣe àṣefihàn kúkúrú kan nípa bí a ṣe lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nínú àṣefihàn náà, wọ́n ti ka ìpínrọ̀, wọ́n sì ti dáhùn ìbéèrè ibẹ̀. Ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ jọ ka Aísáyà 45:18 àti Oníwàásù 1:4, wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ wá béèrè àwọn ìbéèrè tó rọrùn lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́, kí ó lè ṣàlàyé bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe bá kókó pàtàkì tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ mu.

Orin 178 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 6

Orin 96

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ àwọn ìwé tá a fẹ́ fi lọni lóṣù December. Ṣe àṣefihàn ìfilọni kan tàbí méjì tá a lè lò nígbà tá a bá ń fi ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí lọni.

20 min: “Ǹjẹ́ O Lè Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́?”c Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n mọrírì ìrànlọ́wọ́ táwọn ẹlòmíràn ń ṣe fún wọn.

15 min: Ìrírí táwọn akéde ní. Sọ pé kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní lẹ́yìn tí wọ́n lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fún ní ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lóṣù November. Ṣètò pé kí a ṣàṣefihàn àwọn ìrírí tó wúni lórí gan-an. Gbóríyìn fún gbogbo àwọn ará fún ìsapá wọn.

Orin 101 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́