Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 10
Orin 223
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìdajì oṣù January sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ January 15 àti Jí! February 8 lọni. (Àbá kẹta ni ká lò láti fi Jí! February 8 lọni.) A tún lè fi ìwé ìròyìn lọni láwọn ọ̀nà mìíràn tó bá ipò ìpínlẹ̀ ìjọ mu. Kí ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà dá lórí bá a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọ mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.
15 min: “Jèhófà ‘Ń Fi Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìgbàgbọ́ Bọ́ Wa.’”a Kí a ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ, kí a sì ṣàlàyé wọn bí àkókò bá ṣe wà sí.
20 min: “Gbọ́rọ̀ Kalẹ̀ Lọ́nà Tó Máa Bá Onírúurú Ipò Mu.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. A gbé e ka àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 5 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Ṣe àṣefihàn méjì lórí bá a ṣe lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó máa bá onírúurú ipò mu tá a bá ń fi ìwé tá a dámọ̀ràn lóṣù yìí lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, ní kí akéde ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tí onílé mẹ́nu kàn.
Orin 143 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 17
Orin 34
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ǹjẹ́ Ẹ̀ Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí? Alàgbà ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. A gbé e ka Ilé Ìṣọ́ April 1, 2003, ojú ìwé 8 sí 10. Mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn nǹkan tẹ̀mí tọ́wọ́ lè tẹ̀ tá a lè máa lépa, kí o sì rọ àwọn ọ̀dọ́ láti ní àwọn nǹkan tẹ̀mí kan tí wọ́n á máa lépa.
20 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Karùn-ún.”b Jẹ́ kí akéde kan tó mọ bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa àti akéde tuntun kan ṣe àṣefihàn kan. Nínú àṣefihàn náà, kí akéde tó mọ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe dáadáa náà ṣàlàyé fún akéde tuntun náà nípa bá a ṣe lè yẹra fún àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn nínú ìpínrọ̀ 4 àti 5.
Orin 78 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 24
Orin 163
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Sọ ọ́ bí àsọyé.
25 min: “Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Lo Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tí A Dámọ̀ràn.”c Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Sọ fún àwọn ará pé àwọn ìgbékalẹ̀ tá a lè lò nígbà tá a bá fẹ́ fi ìwé lọni wà lójú ìwé 3 àti 4 àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù yìí. Ẹ tọ́jú àkìbọnú náà kẹ́ ẹ lè lò ó jálẹ̀ ọdún yìí. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti gbé àpilẹ̀kọ yìí yẹ̀ wò, ṣàlàyé nípa bá a ṣe lè fi ìwé Sún Mọ́ Jèhófà lọni lóṣù February. Ṣe àṣefihàn méjì. Nínú àṣefihàn náà, ẹ lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dámọ̀ràn lójú ìwé 3 tàbí èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé yóò wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ní ìpínlẹ̀ yín.
Orin 200 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 31
Orin 157
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù January sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ February 1 àti Jí! February 8 lọni. (Àbá kẹrin ni ká lò láti fi Jí! February 8 lọni.) A tún lè fi ìwé ìròyìn lọni láwọn ọ̀nà mìíràn tó bá ipò ìpínlẹ̀ ìjọ mu.
15 min: “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí láìkọ ọ̀rọ̀ wọn síbẹ̀, kí o sì ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lé e lórí, bí àkókò bá ṣe wà sí.
20 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. A gbé e ka ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2005. Ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa máa fi ìṣẹ́jú díẹ̀ ó kéré tán, ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àlàyé ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ṣètò pé kí ẹnì kan tàbí méjì sọ ètò tí wọ́n ṣe tó fi ṣeé ṣe fún wọn láti máa ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ déédéé àti bí èyí ṣe ṣe wọ́n láǹfààní. Fi ọ̀rọ̀ ṣókí lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ ọdún 2005 kádìí ìjíròrò yìí.
Orin 184 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 7
Orin 97
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Aládùúgbò Wọn. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 1, 2004, ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 7 sí 9. Ṣàlàyé bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn Kristi.
20 min: Jèhófà Kì Í Fawọ́ Ohunkóhun Tó Dára Sẹ́yìn. (Sm. 84:11) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn arákùnrin àti arábìnrin díẹ̀ tí wọ́n dúró ṣinṣin nígbà ìṣòro. Irú ìṣòro wo ni wọ́n ní? Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n ti rí, kí sì làwọn ohun tó ti fún wọn láyọ̀?
Orin 104 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.