Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 14
Orin 174
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìdajì oṣù February sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ February 15 lọni. Ní ṣókí, sọ bí a ṣe lè lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dámọ̀ràn lọ́nà tó máa bá ipò àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ mu.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005, ojú ìwé 8.
35 min: “Àkókò Ìṣe Ìrántí—Àkókò Tí Ìgbòkègbodò Tẹ̀mí Wa Máa Ń Pọ̀ Sí I.”a Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó ìjíròrò yìí. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń gbé ìpínrọ̀ 6 yẹ̀ wò, mẹ́nu kan ohun tó wà nínú Jí! September 8, 2004, ojú ìwé 30 àti 31. Ka orúkọ àwọn tó ti forúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Sọ àwọn ètò mìíràn tí ìjọ tún ṣe nípa ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n jẹ́ kí ìgbòkègbodò tẹ̀mí wọn pọ̀ sí i lákòókò Ìṣe Ìrántí yìí.
Orin 14 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 21
Orin 31
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́: “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Ìṣe Ìrántí.”
20 min: “Ẹ Fi Ọpẹ́ fún Jèhófà Nítorí Inú Rere Rẹ̀ Onífẹ̀ẹ́.”b Sọ ibi tá a ti máa ṣe Ìṣe Ìrántí àti àkókò tá a máa ṣe é, kó o sì tún sọ orúkọ ẹni tó máa sọ àsọyé Ìṣe Ìrántí àtàwọn nǹkan mìíràn tó jẹ mọ́ ayẹyẹ yìí. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń gbé ìpínrọ̀ 4 yẹ̀ wò, kí a ṣe àṣefihàn ṣókí kan, èyí tí akéde kan ti ń sọ fún ẹnì kan tó máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé pé kó wá síbi Ìṣe Ìrántí. Bí a ò bá tíì pín ìwé pélébé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá síbi Ìṣe Ìrántí, kí a pín in fún àwọn ará lẹ́yìn ìpàdé.
15 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kẹfà.”c Kí a ṣe àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́rin, nínú èyí tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan yóò ti béèrè ìdí tó fi jẹ́ pé àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìṣe Ìrántí. Ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yìn ín fún ìbéèrè rẹ̀, ó kọ ọ́ sílẹ̀, ó sì sọ fún un pé kó jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn. Nígbà tí wọ́n parí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ tọ́ka sí ohun tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà, “Àwọn Wo Ló Yẹ Kó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Náà?” tó wà lójú ìwé 5 àti 6 nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2004 àti nínú ìwé Reasoning, ojú ìwé 266 sí 269. Àwọn méjèèjì jọ kà á, akẹ́kọ̀ọ́ náà sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nítorí bó ṣe dáhùn ìbéèrè rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere.
Orin 21 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 28
Orin 42
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù February sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ March 1 àti Jí! March 8 lọni. A tún lè fi ìwé ìròyìn lọni láwọn ọ̀nà mìíràn tó bá ipò ìpínlẹ̀ ìjọ mu. Kí ọ̀kan lára àwọn akéde tá a máa lò fún àṣefihàn yìí tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kó lo àlàyé tó wà lẹ́yìn Jí! March 8 láti fi pe onílé wá síbi Ìṣe Ìrántí.
10 min: Àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: “Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù.”d Nígbà tẹ́ ẹ bá ń gbé ìpínrọ̀ 3 àti 4 yẹ̀ wò, sọ bí a ṣe lè lo kókó ibẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìjọ. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n máa ń fi ìwé ìròyìn sóde dáadáa níbi táwọn èèyàn tí ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ní òpópónà, níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí tàbí nígbà tí wọ́n ń wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Sọ pé kí wọ́n ṣàlàyé bí wọ́n ṣe máa ń fi ìwé ìròyìn sóde láwọn àkókò wọ̀nyí. Kí a ṣe àṣefihàn kúkúrú kan tó dá lórí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí ká ṣe àṣefihàn ọ̀kan nínú ìrírí àwọn akéde náà.
Orin 192 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 7
Orin 12
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
40 min: “Àpéjọ Àgbègbè Tó Kọjá Ta Wá Jí Láti Bá Ọlọ́run Rìn.” Alàgbà ni kó bójú tó o. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìṣẹ́jú kan tàbí ó dín díẹ̀ ní ìṣẹ́jú kan, lo àwọn ìbéèrè inú àpilẹ̀kọ náà láti fi bá àwùjọ jíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè. Pín àkókò tó o máa lò sórí ìbéèrè kọ̀ọ̀kan kẹ́ ẹ lè gbé wọn yẹ̀ wò bó ṣe yẹ, bóyá kó o kàn gba ìdáhùn kan ṣoṣo láwọn ìbéèrè kan. Kì í ṣe gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lẹ máa lè kà láàárín àkókò tí a yàn fún iṣẹ́ yìí; ńṣe la fi wọ́n síbẹ̀ kó fi lè rọrùn láti rí àwọn ìdáhùn ibẹ̀. Kí ìdáhùn àwọn ará dá lórí àǹfààní tó wà nínú fífi àwọn ohun tá a kọ́ sílò.
Orin 165 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.