Ọjọ́ Jèhófà Ti Sún Mọ́lé
1 Lójú méjèèjì làwa Kristẹni ń retí pé kí ọjọ́ Jèhófà dé, ìyẹn àkókò tó máa pa ètò nǹkan ìsinsìnyí run tó sì máa fi ayé tuntun òdodo rọ́pò rẹ̀. (2 Pét. 3:12, 13) Níwọ̀n bá ò ti mọ ọjọ́ tó máa jẹ́ gan-an, a ní láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà ká sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. (Ìsík. 33:7-9; Mát. 24:42-44) Bá a bá ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, ó máa mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà [ti] sún mọ́lé.”—Sef. 1:14.
2 Bí Àwọn Agbára Ayé Ṣe Ń Rọ́pò Ara Wọn: Bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìṣípayá 17:9-11, àpọ́sítélì Jòhánù dárúkọ “ọba méje” tó ń ṣojú fún agbára ayé méje. Jòhánù tún tọ́ka sí “ọba kẹjọ,” èyí tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń ṣojú fún. Ṣé ká tún máa retí agbára ayé mìíràn ni? Rárá o, ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ ni pé ṣe ni ọba kẹjọ “kọjá lọ sínú ìparun,” lẹ́yìn rẹ̀, kò sọ̀rọ̀ nípa ọba èyíkéyìí mọ́ tó jẹ lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí i pé ọjọ́ ti lọ jìnnà?
3 Dáníẹ́lì 2:31-45, ràn wá lọ́wọ́ láti lóye dídé ọjọ́ Jèhófà. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, ṣe ni ère gàgàrà tí Nebukadinésárì rí nínú àlá rẹ̀ ṣàpẹẹrẹ bí àwọn agbára ayé yóò ṣe máa rọ́pò ara wọn. Gbogbo àwọn agbára ayé yìí ló ti yọjú tán. Èwo lára àwọn agbára ayé ló ń ṣàkóso lónìí? Àkókò tí ẹsẹ̀ ère náà dúró fún là ń gbé yìí. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e kedere. Ìjọba èèyàn máa pa run títí láé láti lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjọba kan “èyí tí a kì yóò run láé.” Ṣé o ti wá rí i bí èyí ṣe fi hàn pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé?
4 Ẹ̀rí Síwájú Sí I: À ń fojú ara wa rí àwọn ẹ̀rí síwájú sí i pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé. À ń rí bí ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìwà táwọn èèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí hù “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí ṣe ń nímùúṣẹ. (2 Tím. 3:1-5) Àti pé à ń lọ́wọ́ sí ìjẹ́rìí kárí ayé tó gbọ́dọ̀ di ṣíṣe kí òpin tó ó dé. (Mát. 24:14) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ọ̀nà tá à ń gba ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú bí áńgẹ́lì yẹn ṣe polongo pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.”—Ìṣí. 14:6, 7.