“Ẹ Máa Bá a Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”
“Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.”—MÁTÍÙ 24:42.
1. Ojú wo ni àwọn tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́ fi ń wo ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti fi sìn ín? Fúnni ni àpẹẹrẹ kan.
Ọ̀PỌ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, tí wọ́n ti ń sìn ín fún ìgbà pípẹ́ ló jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́mọkùnrin tàbí lọ́lọ́mọge ni wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bíi ti oníṣòwò tó rí péálì tó ṣeyebíye, tó ta gbogbo dúkìá rẹ̀, kó bàa lè rà á, bẹ́ẹ̀ ni àwọn onítara akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀nyẹn sẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. (Mátíù 13:45, 46; Máàkù 8:34) Báwo ló ṣe rí lára wọn láti dúró ju àkókò tí wọ́n ní lọ́kàn, kí wọn bàa lè rí i nígbà tí Ọlọ́run bá mú àwọn ète rẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ilẹ́ ayé ṣẹ? Wọn ò kábàámọ̀ rẹ̀ rárá o! Wọ́n gbà pẹ̀lú Arákùnrin A. H. Macmillan, ẹni tó jẹ́ pé lẹ́yìn tó ti fi nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sin Ọlọ́run, ó wí pé: “Ìpinnu mi túbọ̀ wá lágbára sí i pé, bó ti wù ó rí, n ò jẹ́ sẹ́ ìgbàgbọ́ mi láé. Ó ti jẹ́ kí ayé mi dùn. Ó ṣì ń jẹ́ kí n lè túbọ̀ máa retí ọjọ́ ọ̀la láìfòyà.”
2. (a) Ìmọ̀ràn tó bọ́ sákòókò wo ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Ìwọ ńkọ́ o? Yálà ọmọdé ni ọ́ tàbí àgbàlagbà, gbé ọ̀rọ̀ Jésù yìí yẹ̀ wò, ohun tó wí rèé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mátíù 24:42) Òdodo ọ̀rọ̀ ni gbólóhùn táa gbọ́ wẹ́rẹ́ yẹn. A ò mọ ọjọ́ tí Olúwa yóò wá mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ètò burúkú yìí, kò sì pọndandan pé ká mọ̀ ọ́n. Ṣùgbọ́n ó yẹ ká máa lo ayé wa lọ́nà tó jẹ́ pé, ìgbàkigbà tó bá dé, a ò ní fìka àbámọ̀ bọnu. Ní ti èyí, àwọn àpẹẹrẹ wo la rí nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà? Báwo ni Jésù ṣe lo àkàwé kan láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì? Ẹ̀rí wo ló sì wà lóde ìwòyí tó fi hàn pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí?
Àpẹẹrẹ Tí Ń Fúnni Ní Ìkìlọ̀
3. Báwo ni ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ṣe jọ àwọn ènìyàn ọjọ́ Nóà?
3 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà làwọn èèyàn òde òní fi dà bí àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó gbé ayé ní ọjọ́ Nóà. Nígbà yẹn, ìwà ipá kún inú ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ọkàn-àyà ènìyàn “búburú [ni] ní gbogbo ìgbà.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5) Àwọn tó pọ̀ jù sì rèé, wàhálà ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ló gbà wọ́n lọ́kàn. Àmọ́ ṣá o, kí Jèhófà tó mú Àkúnya Omi ńlá yẹn wá, ó fún àwọn ènìyàn láǹfààní láti ronú pìwà dà. Ó pàṣẹ fún Nóà láti wàásù, Nóà sì ṣe bó ti wí—ó jẹ́ “oníwàásù òdodo” fún nǹkan bí ogójì tàbí àádọ́ta ọdún tàbí kó tilẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. (2 Pétérù 2:5) Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn yẹn kọtí ikún sí ìkìlọ̀ Nóà. Wọn ò ṣọ́nà rárá. Níkẹyìn, Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan ló la ìdájọ́ Jèhófà já.—Mátíù 24:37-39.
4. Lọ́nà wo ni a fi lè sọ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Nóà kẹ́sẹ járí, báwo sì ni a ṣe lè sọ ohun kan náà nípa iṣẹ́ ìwàásù wa?
4 Ǹjẹ́ Nóà kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? Máà fojú ti pé iye àwọn tó tẹ̀ lé ìkìlọ̀ rẹ̀ kéré wò ó. Ká sòótọ́, láìka ẹ̀mí tí àwọn èèyàn fi gba iṣẹ́ ìwàásù Nóà sí, iṣẹ́ náà mú ète táa ní fún un ṣẹ. Èé ṣe táa fi sọ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ó fún àwọn ènìyàn ní àǹfààní tí ó tó láti yàn bóyá wọn yóò sin Jèhófà tàbí wọn ò ní sìn ín. Báwo ni ìpínlẹ̀ tóo ti ń wàásù ti rí? Ká tiẹ̀ ní àwọn kéréje ló ń fetí sílẹ̀, àṣeyọrí tó ní pọ̀ jọjọ. Èé ṣe? Nítorí nípa wíwàásù, o ń sọ ìkìlọ̀ Ọlọ́run fáráyé, o sì ń tipa báyìí ṣe iṣẹ́ tí Jésù yàn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.
Fífi Àwọn Wòlíì Ọlọ́run Gún Lágídi
5. (a) Àwọn ipò wo ló gbòde kan ní Júdà ní ọjọ́ Hábákúkù, ẹ̀mí wo sì ni àwọn èèyàn náà fi gba iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀? (b) Báwo ni àwọn ará Júdà ṣe fi ẹ̀tanú hàn sí àwọn wòlíì Jèhófà?
5 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí Ìkún Omi ti jà, ni ìjọba Júdà wá dojú kọ wàhálà ńlá. Ìbọ̀rìṣà, ìrẹ́jẹ, ìninilára, àti ìpànìyàn pàápàá wà níbi gbogbo. Ni Jèhófà bá gbé Hábákúkù dìde láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé, bí wọn ò bá tètè lọ ronú pìwà dà, àjálù yóò bá wọn látọwọ́ àwọn ará Kálídíà, tàbí Bábílónì. (Hábákúkù 1:5-7) Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀, wọn ò gbọ́. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa ronú pé, ‘Ẹẹ, ṣebí ní nǹkan tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, wòlíì Aísáyà kìlọ̀ bẹ́ẹ̀, nǹkan kan ò sì ṣẹlẹ̀ títí dòní olónìí!’ (Aísáyà 39:6, 7) Yàtọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ àwọn ìjòyè Júdà ò ka ìkìlọ̀ yìí sí, wọ́n tún kórìíra àwọn tó wá jíṣẹ́ náà fún wọn. Àní nígbà kan, wọ́n fẹ́ pa wòlíì Jeremáyà pátápátá, ọpẹ́lọpẹ́ Áhíkámù tó dá sí ọ̀ràn ọ̀hún, wọn ì bá kúkú pa á. Nítorí tí iṣẹ́ tí wòlíì Ùríjà jẹ́ bí Jèhóákímù Ọba nínú, ló bá ṣá a ní àṣápa.—Jeremáyà 26:21-24.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe fún Hábákúkù lókun?
6 Irú iṣẹ́ táa rán Hábákúkù tó ń béèrè ìgboyà tí àwọn èèyàn ò sì kà sí náà ni iṣẹ́ táa rán Jeremáyà tí Ọlọ́run mí sí láti sàsọtẹ́lẹ̀ pé Júdà yóò dahoro fún àádọ́rin ọdún. (Jeremáyà 25:8-11) Nítorí náà, a lè lóye ìdí tí Hábákúkù fi ń dààmú, tó sì fi tẹ̀dùntẹ̀dùn sọ pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́? Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là?” (Hábákúkù 1:2) Jèhófà lo inú rere láti dáhùn ìbéèrè Hábákúkù nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ afúngbàgbọ́-lókun wọ̀nyí pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3) Nítorí náà, Jèhófà ní “àkókò tí [ó] yàn kalẹ̀” láti fòpin sí ìrẹ́jẹ àti ìninilára. Bó bá tiẹ̀ jọ pé ó ń falẹ̀, Hábákúkù ò ní rẹ̀wẹ̀sì, tàbí kó dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìkìlọ̀ tó ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò máa “bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà,” tí yóò máa fi ìjẹ́kánjúkánjú lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ọjọ́ Jèhófà kò ní pẹ́ o!
7. Èé ṣe tí a fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun mìíràn nípa Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa?
7 Lẹ́yìn ogún ọdún tí Jèhófà ti bá Hábákúkù sọ̀rọ̀, ìparun dé sórí olú ìlú Júdà gan-an, ìyẹn ni Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ṣàtúnṣe gbogbo ìwà àìtọ́ tó kó ìdààmú bá Hábákúkù. Ṣùgbọ́n, ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, a tún sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò tún pa ìlú náà run nítorí ìwà àìṣòótọ́ àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Nítorí àánú Jèhófà tó pọ̀, ó ṣètò pé àwọn olóòótọ́-ọkàn tó wà níbẹ̀ yóò là á já. Lọ́tẹ̀ yìí ṣá o, wòlíì tó tóbi jù lọ nì, Jésù Kristi, ló lò láti jíṣẹ́ náà. Lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.”—Lúùkù 21:20, 21.
8. (a) Kí ló lè ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni kan bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ lẹ́yìn ikú Jésù? (b) Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa Jerúsálẹ́mù ṣe nímùúṣẹ?
8 Bọ́dún ti ń gorí ọdún, ó ṣeé ṣe kí àwọn Kristẹni kan ní Jerúsálẹ́mù ti máa ṣe kàyéfì pé ìgbà wo gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ Jésù máa nímùúṣẹ. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ nǹkan ni àwọn kan lára wọn ti yááfì. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi iṣẹ́ tó lè tètè mówó wọlé sílẹ̀ nítorí ìpinnu wọn láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà. Bí ọjọ́ sì ti ń gorí ọjọ́, ṣé àárẹ̀ mú wọn? Ǹjẹ́ wọ́n parí èrò sí pé, ńṣe làwọn ń fi àkókò àwọn ṣòfò, tí wọ́n ń rò pé ìran tí ń bọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la ni ọ̀rọ̀ Jésù bá wí, pé kì í ṣe ìran tiwọn? Nígbà tó di ọdún 66 Sànmánì Tiwa, àsọtẹ́lẹ̀ Jésù bẹ̀rẹ̀ sí nímùúṣẹ nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù yí Jerúsálẹ́mù ká. Àmì náà yé àwọn tí wọ́n ń bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kíá ni wọ́n sá kúrò nínú ìlú náà, wọn ò sì fara gbá nínú ìsọdahoro Jerúsálẹ́mù.
Ṣíṣàkàwé Ìjẹ́pàtàkì Bíbá A Nìṣó Láti Máa Ṣọ́nà
9, 10. (a) Báwo ni wàá ṣe ṣàkópọ̀ àkàwé Jésù nípa àwọn ẹrú tó ń retí kí ọ̀gá wọn padà dé láti ibi ìgbéyàwó rẹ̀? (b) Èé ṣe tí ríretí ọ̀gá wọn ṣe lè jẹ́ ohun ìnira fún àwọn ẹrú náà? (d) Èé ṣe tó fi ṣàǹfààní fún àwọn ẹrú náà láti mú sùúrù?
9 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ lórí ìjẹ́pàtàkì bíbá a nìṣó láti máa ṣọ́nà, ó fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé àwọn ẹrú tó ń retí dídé ọ̀gá wọn láti ibi ìgbéyàwó rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé òru ọjọ́ kan ló máa dé—ṣùgbọ́n aago mélòó ló máa dé? Ṣé nígbà ìṣọ́ kìíní ló máa dé ni? Àbí nígbà ìṣọ́ kejì? Àbí nígbà ìṣọ́ kẹta? Wọn ò mọ̀. Jésù wí pé: “Bí [ọ̀gá náà] bá sì dé ní ìṣọ́ kejì, kódà bí ó jẹ́ ní ẹ̀kẹta, tí ó sì bá wọn [tí wọ́n ń ṣọ́nà], aláyọ̀ ni wọ́n!” (Lúùkù 12:35-38) Ìwọ náà wo bí ara àwọn ẹrú wọ̀nyí yóò ti wà lọ́nà tó. Gbogbo ìró tí wọ́n bá ń gbọ́, gbogbo òjìji tí wọ́n bá rí fìrí, ni yóò mú kí wọ́n máa hára gàgà pé: ‘Àbí ọ̀gá wa ti dé ni?’
10 Tó bá lọ jẹ́ pé ìṣọ́ kejì lóru ni ọ̀gá náà lọ dé ńkọ́, èyí tó máa ń jẹ́ láti nǹkan bí aago mẹ́sàn-án alẹ́ títí di ọ̀gànjọ́ òru? Ṣé gbogbo àwọn ẹrú náà, títí kan àwọn tó ti ṣiṣẹ́ àṣekára láti àárọ̀ kùtùkùtù, yóò lè wà lójúfò láti kí i káàbọ̀, tàbí àwọn kan lára wọn yóò ti sùn? Tó bá lọ jẹ́ pé ìṣọ́ kẹta ni ọ̀gá náà dé ńkọ́—ìyẹn ni láti ọ̀gànjọ́ òru títí di nǹkan bí aago mẹ́ta ìdájí? Ǹjẹ́ ìrẹ̀wẹ̀sì ò ti ní bá àwọn kan lára àwọn ẹrú náà, tí wọn yóò sì máa fapá jánú nítorí tó jọ pé ọ̀gá wọn ti pẹ́ jù?a Kìkì àwọn tí wọ́n bá ń ṣọ́nà nígbà tí ọ̀gá náà bá dé ni a ó pè ní aláyọ̀. Àwọn ni ọ̀rọ̀ ìwé Òwe 13:12 yóò nímùúṣẹ sí lára pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn, ṣùgbọ́n igi ìyè ni ohun tí a fọkàn fẹ́ nígbà tí ó bá dé ní ti tòótọ́.”
11. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
11 Ní àkókò tó jọ pé dídé Jésù ń falẹ̀, kí ló lè ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà? Nígbà ti Jésù wà nínú ọgbà Gẹtisémánì ní kété ṣáájú kí wọ́n tó fàṣẹ ọba mú un, ó sọ fún mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.” (Mátíù 26:41) Ọ̀pọ̀ ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Pétérù, ẹni tí ọ̀rọ̀ yẹn ṣojú rẹ̀, gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní irú ìmọ̀ràn kan náà. Ó kọ̀wé pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Nítorí náà, ẹ yè kooro ní èrò inú, kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn.” (1 Pétérù 4:7) Kò sí àní-àní pé, àdúrà onítara yẹ kó jẹ́ apá kan ohun tí àwa Kristẹni yóò máa ṣe nígbà gbogbo. Ká sòótọ́, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bẹ Jèhófà pé kó dákun ràn wá lọ́wọ́, ká lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.—Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:17.
12. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín míméfò àti ṣíṣọ́nà?
12 Ṣàkíyèsí pé Pétérù náà sọ pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” Báwo ló ti sún mọ́lé tó? Kò ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí láti sọ pé ọjọ́ báyìí àti wákàtí báyìí ni. (Mátíù 24:36) Àmọ́ ṣá o, ìyàtọ̀ wà láàárín míméfò, èyí tí Bíbélì ò fẹ́, àti fífojú sọ́nà fún òpin, èyí tó fẹ́. (Fi wé 2 Tímótì 4:3, 4; Títù 3:9.) Kí ni ọ̀nà kan táa lè máa gbà fojú sọ́nà fún òpin? Òun ni nípa fífiyè gidigidi sí ẹ̀rí náà pé òpin ti sún mọ́lé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀rí mẹ́fà tí kò ṣeé já ní koro, tó fi hàn pé à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí.
Ẹ̀rí Mẹ́fà Tí Kò Ṣeé Já Ní Koro Rárá
13. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Pọ́ọ̀lù táa kọ sínú 2 Tímótì orí 3 ṣe mú un dá ọ lójú pé à ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?
13 Èkíní, a rí i dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti ń nímùúṣẹ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀; yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tímótì 3:1-5, 13) Ǹjẹ́ àwa pẹ̀lú kò fojú ara wa rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń nímùúṣẹ lónìí? Àfàwọn tí kò ka òótọ́ kún ló lè sọ pé kò rí bẹ́ẹ̀!b
14. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìṣípayá 12:9 nípa Èṣù ṣe ní ìmúṣẹ lónìí, kí sì ni yóò ṣẹlẹ̀ sí i láìpẹ́?
14 Èkejì, a fojú wa rí ipá tí lílé táa le Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run ní, kí Ìṣípayá 12:9 lè ní ìmúṣẹ. Níbẹ̀, a kà pé: “A fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Èyí ti yọrí sí ègbé ńlá fún ilẹ̀ ayé. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ègbé ló ti dé sórí aráyé, pàápàá jù lọ láti ọdún 1914. Ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìṣípayá fi kún un pé nígbà tí a lé Èṣù wá sí ilẹ̀ ayé, ó mọ̀ pé “sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Láàárín àkókò yìí, Sátánì ń bá àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi jagun. (Ìṣípayá 12:17) Kò sí àní-àní pé ní àkókò wa yìí, a ti rí ipa tí ìgbéjàkò rẹ̀ yìí ní.c Ṣùgbọ́n, láìpẹ́, a ó ti Sátánì mọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, kí ó má bàa lè “ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́.”—Ìṣípayá 20:1-3.
15. Báwo ni Ìṣípayá 17:9-11 ṣe fi ẹ̀rí hàn pé à ń gbé ní àkókò òpin?
15 Ìkẹta, à ń gbé ní àkókò “ọba” kẹjọ, èyí tí yóò jẹ kẹ́yìn, táa mẹ́nu kàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 17:9-11. Níhìn-ín, àpọ́sítélì Jòhánù mẹ́nu kan ọba méje, tí wọ́n ń ṣojú fún agbára ayé méje—ti Íjíbítì, Asíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, Róòmù, àti ti Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà, tó jẹ́ agbára ayé aláwẹ́ méjì. Ó tún rí “ọba kẹjọ” tó “jáde wá láti inú àwọn méje náà.” Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọba kẹjọ yìí—èyí tí Jòhánù rí kẹ́yìn nínú ìran rẹ̀—ń dúró fún ètò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Jòhánù sọ pé ọba kẹjọ yìí “kọjá lọ sínú ìparun,” lẹ́yìn èyí, kò sì sọ̀rọ̀ nípa ọba èyíkéyìí mọ́ tó jẹ lórí ilẹ̀ ayé.d
16. Báwo ni àwọn òtítọ́ tó wà nínú ìmúṣẹ àlá ère Nebukadinésárì ṣe fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé?
16 Ìkẹrin, a ń gbé ní àkókò tí ẹsẹ̀ ère tí Nebukadinésárì rí nínú àlá rẹ̀ ń ṣàpẹẹrẹ. Wòlíì Dáníẹ́lì túmọ̀ àlá tó díjú yìí, èyí tó dá lórí ère gàgàrà kan tó dà bí ènìyàn. (Dáníẹ́lì 2:36-43) Ìsọ̀rí mẹ́rin tó jẹ́ mẹ́táàlì tí ère náà pín sí ń dúró fún àwọn agbára ayé tó yàtọ̀ síra wọn, láti orí rẹ̀ (ìyẹn ni Ilẹ̀ Ọba Bábílónì) títí tó fi dé ẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ (ìyẹn ni àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso lónìí). Gbogbo àwọn agbára ayé tí a ṣàpèjúwe lára ère yẹn ló ti fara hàn. Àkókò tí ẹsẹ̀ ère náà dúró fún là ń gbé yìí. Àsọtẹ́lẹ̀ náà kò sọ pé agbára ayé mìíràn á tún yọjú.e
17. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba tí à ń ṣe ṣe túbọ̀ fi ẹ̀rí hàn pé àkókò ìkẹyìn là ń gbé?
17 Ìkarùn-ún, a fojú ara wa rí i pé iṣẹ́ ìwàásù ti kárí ayé, Jésù sì sọ pé èyí yóò ṣẹlẹ̀ kí òpin ètò àwọn nǹkan yìí tó dé. Jésù wí pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Lónìí, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣì ń bá a lọ láti máa ní ìmúṣẹ lọ́nà tí kò láfiwé. Òótọ́ ni pé àwọn àgbègbè kan wà tí a kò tíì fọwọ́ kàn, ó sì lè jẹ́ pé nígbà tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, ilẹ̀kùn ńlá kan tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i yóò ṣí sílẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 16:9) Síbẹ̀síbẹ̀, Bíbélì ò sọ pé Jèhófà yóò dúró títí di ìgbà tí olúkúlùkù ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé bá tó fetí ara wọn gbọ́ iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni a ó wàásù ìhìn rere náà débi tó bá tẹ́ Jèhófà lọ́rùn. Nígbà náà ni òpin yóò dé.—Fi wé Mátíù 10:23.
18. Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, báwo la sì ṣe lè pinnu èyí?
18 Ìkẹfà, iye àwọn ojúlówó ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi ń dín kù sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ṣì máa wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn àṣẹ́kù náà ló ti dàgbàlagbà, bí ọdún sì ti ń gorí ọdún ni iye àwọn ojúlówó ẹni àmì òróró túbọ̀ ń dín kù sí i. Síbẹ̀, nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìpọ́njú ńlá náà, ó wí pé: “Láìjẹ́ pé a ké ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là; ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́, a óò ké ọjọ́ wọnnì kúrú.” (Mátíù 24:21, 22) Nítorí náà, ó hàn gbangba pé àwọn kan lára àwọn “àyànfẹ́” Kristi ṣì máa wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀.f
Kí Ló Wà Níwájú?
19, 20. Èé ṣe tó fi jẹ́ kánjúkánjú fún wa nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ láti wà lójúfò, kí a sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
19 Kí ni ọjọ́ iwájú ní nípamọ́ fún wa? Àwọn àkókò amóríyá-gágá ṣì wà níwájú. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé “ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru.” Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n lọ́nà ti ayé, ó wí pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń sọ pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn òǹkàwé rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:2, 3, 6) Ní tòótọ́, àwọn tó bá ń wojú ètò àjọ ènìyàn láti mú àlàáfíà àti ààbò wá ń fi òtítọ́ ṣeré ni o. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti sùn lọ fọnfọn!
20 Ìparun ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí yóò dé lójijì lọ́nà tó máa bani lẹ́rù. Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún ọjọ́ Jèhófà. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ fún Hábákúkù pé: “Kì yóò pẹ́”! Ká sòótọ́, bíbá a nìṣó láti máa ṣọ́nà jẹ́ kánjúkánjú fún wa nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀gá náà ò bá àwọn ẹrú rẹ̀ dá àkókò kankan. Nítorí náà, ìgbàkigbà tó bá dé, kò sẹ́ni tó lè bi í pé kí ló dé, bẹ́ẹ̀ sì ni kò pọndandan fún un láti ṣàlàyé fún àwọn ẹrú rẹ̀ nípa ohun tó fà á tó fi jọ pé òun pẹ́.
b Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo orí kọkànlá ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
c Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo ojú ìwé 180 sí 186 nínú ìwé náà, Ìṣípayá—Òtéńté Atóbilọ́lá Rẹ̀ Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
e Wo orí kẹrin ìwé náà, Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
f Nínú òwe àgùntàn àti ewúrẹ́, Ọmọ ènìyàn dé nínú ògo rẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá, ó sì jókòó láti máa ṣèdájọ́. Ó ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lórí bóyá wọ́n kọ́wọ́ ti àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi lẹ́yìn tàbí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Bó bá lọ jẹ́ pé gbogbo àwọn arákùnrin Kristi yóò ti kúró lórí ilẹ̀ ayé tipẹ́tipẹ́ kó tó wá ṣèdájọ́, ìlànà tó fẹ́ fi ṣèdájọ́ yìí kò ní nítumọ̀ mọ́.—Mátíù 25:31-46.
Ṣé O Rántí?
• Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
• Báwo ni Jésù ṣe ṣàkàwé ìjẹ́pàtàkì bíbá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
• Àwọn ẹ̀rí mẹ́fà tí kò ṣeé já ní koro wo ló fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
A. H. Macmillan fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta ọdún
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jésù fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé àwọn ẹrú tó ń bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà