ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Bí Ìjọba Ọlọ́run!
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 12. (a) Níbi tí Jèhófà ti sàsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù nínú ìwé Sáàmù, ìlérí wo ló ṣe nípa Jésù? (b) Kí ni bíbí tí obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan “tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè” dúró fún?

      12 Ǹjẹ́ o ti gbọ́ gbólóhùn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí rí? Bẹ́ẹ̀ ni, nínú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù, Jèhófà ṣèlérí pé: “Ìwọ yóò fi ọ̀pá aládé irin ṣẹ́ wọn, bí ohun èlò amọ̀kòkò ni ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú.” (Sáàmù 2:9) Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ọ̀pá okun rẹ ni Jèhófà yóò rán jáde láti Síónì, pé: ‘Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.’” (Sáàmù 110:2) Nítorí náà, ìbímọ tí Jòhánù rí yìí kan Jésù Kristi gbọ̀ngbọ̀n. Àmọ́ o, kì í ṣe bíbí tí wúńdíá kan bí Jésù ṣáájú ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ni èyí o; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀rọ̀ jíjí tí Ọlọ́run jí Jésù dìde sí ìwàláàyè tẹ̀mí lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. Bákan náà sì ni kì í ṣe ọ̀ràn àtúnwáyé nínú ara mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìbí Ìjọba Ọlọ́run tó wáyé lọ́dún 1914, nígbà tí Ọlọ́run gbé Jésù tó ti tó ẹgbàá [2,000] ọdún báyìí tó ti wà lọ́run gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba.—Ìṣípayá 12:10.

      13. Kí ni gbígbà tí a “gba” ọmọ náà tó jẹ́ akọ “lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀” fi hàn?

      13 Láéláé, Jèhófà ò ní fàyè gba Sátánì láti pa aya Rẹ̀ tàbí ọmọkùnrin tí aya Rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí! Lẹ́yìn tí aya Ọlọ́run bí ọmọkùnrin yìí, a ‘gbà á lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀.’ Nípa bẹ́ẹ̀, ó bọ́ sábẹ́ ààbò Jèhófà, ẹni tí yóò tọ́jú Ìjọba tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí yìí dáadáa. Ìjọba náà ni Jèhófà máa lò láti sọ orúkọ mímọ́ Rẹ̀ di mímọ́. Obìnrin tó bímọ náà sá lọ síbi tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún un nínú aginjù. A ṣì máa rí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ìyẹn! Sátánì ńkọ́? Ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì kan máa wáyé tí kò ní í mú kó ṣeé ṣe fún un láé láti gbógun ti Ìjọba náà ní ọ̀run. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo nìyẹn?

      Ogun Jà Lọ́run!

      14. (a) Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe sọ, ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Sátánì mọ́ láti gbógun ti Ìjọba náà? (b) Sàkáání ibo ni wọ́n há Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ mọ́?

      14 Jòhánù sọ fún wa pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (Ìṣípayá 12:7-9) Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì tó mú àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run wá sí ìparí ṣẹlẹ̀. Máíkẹ́lì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ lé Sátánì kúrò lọ́run, wọ́n sì fi òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Sátánì tó ti ṣi gbogbo ayé lọ́nà tó sì tún di ọlọ́run rẹ̀ wá dẹni tí wọ́n ká lọ́wọ́ kò, tí wọn ò jẹ́ kó lè kúrò ní sàkáání ilẹ̀ ayé, ilẹ̀ ayé ọ̀hún ló sì kúkú ti bẹ̀rẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:3, 4.

      15, 16. (a) Ta ni Máíkẹ́lì, báwo la sì ṣe mọ̀? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu rẹ́gí pé Máíkẹ́lì lẹni tó fi Sátánì sọ̀kò sísàlẹ̀ látọ̀run?

      15 Ta ló ja àjàṣẹ́gun ńlá yìí ní orúkọ Jèhófà? Bíbélì sọ pé Máíkẹ́lì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ta ni Máíkẹ́lì? Orúkọ náà “Máíkẹ́lì” túmọ̀ sí “Ta Ni Ó Dà Bí Ọlọ́run?” Nítorí náà, Máíkẹ́lì ní láti nífẹ̀ẹ́ sí fífihàn pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run nípa fífi ẹ̀rí hàn pé kò sẹ́nì kankan tá a lè fi wé E. Nínú Júúdà ẹsẹ 9, a pè é ní “Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, Bíbélì lo orúkọ oyè náà “olú-áńgẹ́lì” níbòmíràn tó sì jẹ́ pé Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ló tọ́ka sí.b Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ pé: “Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 4:16) Orúkọ oyè náà “olú-áńgẹ́lì” túmọ̀ sí “olórí àwọn áńgẹ́lì.” Nítorí náà kò yani lẹ́nu pé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa “Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” Láwọn ibòmíràn tí Bíbélì ti fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì wà ní ìtẹríba fún ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó jẹ́ olódodo, Jésù ló tọ́ka sí. Ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù fi sọ̀rọ̀ nípa “ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára.”—2 Tẹsalóníkà 1:7; tún wo Mátíù 24:30, 31; 25:31.

      16 Ìwọ̀nyí àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn jẹ́ ká mọ̀ láìsí iyèméjì kankan pé Máíkẹ́lì kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Jésù Kristi Olúwa nínú ipò rẹ̀ ní ọ̀run. Nísinsìnyí tá a ti wà ní ọjọ́ Olúwa, kò wulẹ̀ sọ fún Sátánì mọ́ pé: “Kí Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná.” Níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ àkókò ìdájọ́, Jésù tí í ṣe Máíkẹ́lì, fi Sátánì ẹni ibi náà àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ látọ̀run. (Júúdà 9; Ìṣípayá 1:10) Òun gan-an ló yẹ kó ṣe èyí, nítorí pé Òun ni Ọba tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé gorí ìtẹ́. Jésù tún ni Irú-Ọmọ náà tí Ọlọ́run ṣèlérí ní Édẹ́nì, tí yóò tẹ orí Ejò náà fọ́, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ pa á run títí gbére. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Bí Jésù sì ṣe lé Sátánì kúrò lọ́run fi hàn pé ó ti sún mọ́ ìgbà tó máa tẹ orí ejò náà fọ́ pátápátá.

      “Ẹ Máa Yọ̀ Ṣẹ̀ṣẹ̀, Ẹ̀yin Ọ̀run”

      17, 18. (a) Kí ni Jòhánù sọ pé àwọn tó wà lọ́rùn ṣe nígbà tí Máíkẹ́lì lé Sátánì kúrò níbẹ̀? (b) Ibo ló ṣeé ṣe kí ohùn rara tí Jòhánù gbọ́ ti wá?

      17 Jòhánù ròyìn bí inú àwọn tó wà lọ́run ṣe dùn tó pé Sátánì ṣubú yakata, ó ní: “Mo sì gbọ́ tí ohùn rara kan ní ọ̀run wí pé: ‘Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé àti agbára àti ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀, nítorí pé olùfisùn àwọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa! Wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn, wọn kò sì nífẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lójú ikú pàápàá. Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!’”—Ìṣípayá 12:10-12a.

      18 Ohùn rara ta ni Jòhánù gbọ́? Bíbélì kò sọ. Ṣùgbọ́n igbe tó jọ ọ́ tí Ìṣípayá 11:17 sọ nípa rẹ̀ wá látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún tá a jí dìde tí wọ́n wà ní ipò wọn lọ́run, níbi tí wọ́n ti lè ṣojú fún àwọn ẹni mímọ́ tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. (Ìṣípayá 11:18) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń fojú winá inúnibíni, tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ni ohùn náà pè ní “àwọn arákùnrin wa,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún yẹn kan náà ló sọ̀rọ̀ yìí. Kò sí iyè méjì kankan pé àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí lè pa ohùn wọn pọ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kété lẹ́yìn tí Máíkẹ́lì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá fi Sátánì àti ògìdìgbó àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò kúrò lọ́run ni wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í jíǹde.

      19. (a) Kí ni dídé tí àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run dé ìparí rẹ̀ mú kí Jésù ṣe? (b) Kí ni pípè tá a pe Sátánì ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa” fi hàn?

      19 Dídé tí àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run dé ìparí rẹ̀ mú kó di dandan pé kí Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Bó ṣe di Ọba yìí ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti ṣe ohun ńlá tó ní lọ́kàn láti ṣe, ìyẹn ni láti dá àwọn olóòótọ́ èèyàn nídè. Kì í ṣe kìkì àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí nìkan ni Jésù máa gbà là, á tún gba ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òkú tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run là. (Lúùkù 21:27, 28) Pípè tá a pe Sátánì ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa” fi hàn pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀sùn tó fi kan Jóòbù jẹ́ èké, kò yéé pe ìwà títọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé níjà. Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti tún ẹ̀sùn rẹ̀ sọ pé èèyàn á fi gbogbo ohun tó ní ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀. Asán ni gbogbo ìsapá Sátánì!—Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5.

      20. Báwo làwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ṣe ṣẹ́gun Sátánì?

      20 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tá a kà sí olódodo “nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ń bá a lọ láti máa jẹ́rìí Ọlọ́run àti Jésù Kristi láìka inúnibíni sí. Ó ti lé ní ọgọ́fà ọdún tí ẹgbẹ́ Jòhánù, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró, ti ń sọ nípa àwọn àríyànjiyàn ńlá tó jẹ mọ́ mímú Àwọn Àkókò Kèfèrí wá sópin lọ́dún 1914. (Lúùkù 21:24) Ogunlọ́gọ̀ ńlá sì ń fi ìdúróṣinṣin sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú wọn nísinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbésí ayé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi hàn léraléra lákòókò tiwa yìí, kò sí ìkankan nínú wọn tó “bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn.” Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti ìwà wọn tó bá ìlànà Kristẹni mu, wọ́n ti ṣẹ́gun Sátánì, wọ́n sì ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Mátíù 10:28; Òwe 27:11; Ìṣípayá 7:9) Nígbà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá sì jíǹde sí ọ̀run, ó dájú pé ayọ̀ wọn á pọ̀ gan-an nítorí pé Sátánì ò sí lọ́run mọ́ láti fẹ̀sùn kan àwọn arákùnrin wọn! Ní tòótọ́, ó jẹ́ àkókò fún ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì láti fi tayọ̀tayọ̀ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ náà, pé: “Ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!”

      Ègbé Tí Sátánì Fà Jẹ́ Àfarawé Lásánlàsàn!

      21. Báwo ni Sátánì ṣe mú ègbé bá ilẹ̀ ayé àti òkun?

      21 Inú tó bí Sátánì nítorí ègbé kẹta mú kó pète láti fi ègbé tirẹ̀ alára pọ́n aráyé lójú. Ìṣípayá sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12b) Lílé tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run mú ègbé bá ilẹ̀ ayé, ìyẹn ayé táwọn èèyàn onímọtara-ẹni-nìkan tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso Sátánì ń pa run. (Diutarónómì 32:5) Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìlànà ‘ìṣàkóso tìpá-tìkúùkù’ tí Sátánì ń lò ń mú ègbé bá ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ètò àwọn ẹ̀dá èèyàn, ó tún ń mú ègbé ba òkun ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ọmọ aráyé onírúkèrúdò. Nígbà ogun àgbáyé méjèèjì, ìbínú àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Sátánì fi hàn pé inú ń bí Sátánì, irú ìbínú ran-n-to bẹ́ẹ̀ sì ń bá a lọ títí di òní olónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní í pẹ́ dópin! (Máàkù 13:7, 8) Ṣùgbọ́n, bó ti wù kí ọ̀nà tí Èṣù gbà ń bínú burú tó, ègbé tó máa fà kò ní í tó ègbé kẹta tí Ìjọba Ọlọ́run yóò fi ṣe apá tó ṣeé fójú rí nínú ètò Sátánì bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú!

      22, 23. (a) Kí ni Jòhánù sọ pé ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fi dírágónì náà sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé? (b) Báwo ni dírágónì náà ṣe ṣenúnibíni sí “obìnrin tí ó bí ọmọ náà tí ó jẹ́ akọ”?

      22 Látìgbà tí wọ́n ti lé Sátánì síta làwọn arákùnrin Kristi tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ti ń fojú winá ìbínú rẹ̀. Jòhánù sọ pé: “Wàyí o, nígbà tí dírágónì náà rí i pé a ti fi òun sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sí obìnrin tí ó bí ọmọ náà tí ó jẹ́ akọ. Ṣùgbọ́n a fún obìnrin náà ní ìyẹ́ apá méjì ti idì ńlá, kí ó lè fò lọ sínú aginjù sí àyè rẹ̀; níbẹ̀ ni a ti bọ́ ọ fún àkókò kan àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò kúrò ní ojú ejò náà.”—Ìṣípayá 12:13, 14.

      23 Ìṣípayá 12:13, 14 tá a kà tán yìí tún ń bá ọ̀rọ̀ tá a kà ní ẹsẹ kẹfà nìṣó, èyí tó sọ fún wa pé lẹ́yìn tí obìnrin náà bí ọmọ rẹ̀, ó sá lọ sínú aginjù, kúrò lọ́dọ̀ dírágónì náà. A lè máa ṣe kàyéfì nípa bí dírágónì náà ṣe lè ṣenúnibíni sí obìnrin náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀run ni obìnrin náà wà tí wọ́n sì ti lé dírágónì náà jù sí ilẹ̀ ayé báyìí. Ó dáa, ṣó o rántí pé obìnrin náà ní àwọn ọmọ lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn irú-ọmọ rẹ̀? Nígbà tó yá nínú ìran yìí, wọ́n sọ fún wa pé Sátánì fi ìrunú rẹ̀ hàn sí obìnrin náà nípa ṣíṣe inúnibíni sí irú-ọmọ rẹ̀. (Ìṣípayá 12:17) Ohunkóhun tó bá ń ṣẹlẹ̀ sí irú-ọmọ obìnrin náà lórí ilẹ̀ ayé, a lè sọ pé obìnrin náà fúnra rẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ sí. (Fi wé Mátíù 25:40.) Àti pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ irú-ọmọ náà tí iye wọn ń pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé yóò fojú winá inúnibíni wọ̀nyí.

      Orílẹ̀-Èdè Tuntun Kan

      24. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó fara jọ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí ìdáǹdè kúrò ní Íjíbítì?

      24 Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń lọ lọ́wọ́, àwọn arákùnrin Jésù ń fi ìṣòtítọ́ bá iṣẹ́ ìjẹ́rìí wọn nìṣó débí tí wọ́n lè ṣeé dé. Wọ́n ń ṣe èyí bí Sátánì àtàwọn òǹrorò ẹmẹ̀wà rẹ̀ tiẹ̀ ń ṣàtakò tó gbóná janjan sí wọn. Níkẹyìn, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ dá iṣẹ́ ìwàásù táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ṣe dúró. (Ìṣípayá 11:7-10) Nígbà yẹn, ojú wọn rí màbo bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pọ́n lójú nílẹ̀ Íjíbítì. Nígbà tí wọ́n pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú, Jèhófà mú wọn wá síbi ààbò ní aṣálẹ̀ Sínáì pẹ̀lú ìyára, bí ẹni pé lórí ìyẹ́ apá idì. (Ẹ́kísódù 19:1-4) Bákan náà, lẹ́yìn inúnibíni gbígbóná janjan tó wáyé lọ́dún 1918 sí ọdún 1919, Jèhófà dá àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀, tí ń ṣojú fún obìnrin rẹ̀, nídè sínú ipò tẹ̀mí tó jẹ́ ibi ààbò fún wọn gẹ́gẹ́ bí aṣálẹ̀ náà ti jẹ́ ibi ààbò fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èyí jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dáhùn àdúrà wọn.—Fi wé Sáàmù 55:6-9.

      25. (a) Kí ni Jèhófà sọ di orílẹ̀-èdè lọ́dún 1919, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè nínú aginjù? (b) Àwọn wo ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè yìí, inú kí ni Ọlọ́run sì ti mú wọn wọ̀?

      25 Jèhófà sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè nínú aginjù, ó sì tún pèsè fún wọn nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Bákan náà, bẹ̀rẹ̀ látọdún 1919, Jèhófà sọ irú-ọmọ obìnrin náà di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí. Èyí kì í ṣe Ìjọba Mèsáyà tó ti ń ṣàkóso láti ọ̀run látọdún 1914 o. Kàkà bẹ́ẹ̀, orílẹ̀-èdè tuntun yìí ni àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ẹlẹ́rìí lórí ilẹ̀ ayé, tí Ọlọ́run mú wọnú ipò ológo nípa tẹ̀mí lọ́dún 1919. Níwọ̀n bí wọ́n ti ń rí “ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” nísinsìnyí, èyí fún wọn lókun láti lè ṣe iṣẹ́ tó wà níwájú wọn.—Lúùkù 12:42; Aísáyà 66:8.

      26. (a) Báwo ni sáà àkókò tí Ìṣípayá 12:6, 14 mẹ́nu kan ṣe gùn tó? (b) Kí ni àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ náà wà fún, ìgbà wo ló bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ló sì parí?

      26 Báwo ni àkókò tí irú-ọmọ obìnrin Ọlọ́run yìí fi wà láginjù ṣe gùn tó? Ìṣípayá 12:6 sọ pé ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́ ni. Ìṣípayá 12:14 sọ pé ó jẹ́ àkókò kan, àwọn àkókò, àti ààbọ̀ àkókò, tó túmọ̀ sí àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀. Ní tòótọ́, gbólóhùn méjèèjì dúró fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀, èyí tó jẹ́ pé ní Àríwá Ìlàjì Ayé, ó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìrúwé ọdún 1919 títí dé ìgbà ìkórè ọdún 1922. Àkókò yẹn ni ẹgbẹ́ Jòhánù jèrè okun padà tí wọ́n sì ṣe àtúntò.

      27. (a) Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe sọ, kí ni dírágónì náà ṣe lẹ́yìn ọdún 1922? (b) Kí nìdí tí Sátánì fi ń ṣe inúnibíni tó pọ̀ gan-an sáwọn Ẹlẹ́rìí?

      27 Dírágónì náà ò yéé ṣenúnibíni! Jòhánù sọ pé: “Ejò náà sì pọ omi jáde bí odò láti ẹnu rẹ̀ tẹ̀ lé obìnrin náà, láti mú kí odò náà gbé e lọ.” (Ìṣípayá 12:15) Kí ni “omi . . . bí odò,” tàbí “àkúnya omi” (Bíbélì The New English Bible) yìí túmọ̀ sí? Dáfídì Ọba ìgbàanì sọ pé àwọn èèyàn burúkú tí wọ́n ń ṣàtakò sóun dà bí “ìkún omi ayaluni lójijì ti àwọn èèyàn tí kò dára fún ohunkóhun” [tàbí “ìṣàn omi ti àwọn aláìníláárí,” Bíbélì Young]. (Sáàmù 18:4, 5, 16, 17) Bó sì ṣe rí náà nìyẹn, àwọn aláìníláárí tàbí “àwọn èèyàn tí kò dára fún ohunkóhun” ni Sátánì ń lò láti fi ṣenúnibíni. Lẹ́yìn ọdún 1922, inúnibíni tí Sátánì ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí pọ̀ gan-an ni, ńṣe ló dà bí ìkún omi. (Mátíù 24:9-13) Lára inúnibíni ọ̀hún ni pé wọ́n lù wọ́n nílùkulù, wọ́n “fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n,” wọ́n fi wọn sẹ́wọ̀n, wọ́n yẹgi fún àwọn kan lára wọn, wọ́n yìnbọn pa àwọn míì, wọ́n sì bẹ́ àwọn míì lórí. (Sáàmù 94:20) Nítorí pé kò ṣeé ṣe fún Sátánì tí wọ́n ti rẹ̀ nípò wálẹ̀ láti dé ọ̀dọ̀ obìnrin Ọlọ́run ti ọ̀run ní tààràtà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìbínú gbógun ti irú-ọmọ obìnrin náà tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé ó sì fẹ́ pa wọ́n run, ní tààràtà tàbí nípa bíba ìwà títọ́ wọn jẹ́ kí wọ́n má bàa rí ojú rere Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ńṣe ni ìpinnu wọn dà bíi ti Jóòbù tó sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—Jóòbù 27:5.

      28. Báwo ni inúnibíni tó dà bí ikùn omi yìí ṣe wá le gan-an nígbà Ogun Àgbáyé Kejì?

      28 Inúnibíni rírorò yìí dé góńgó nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nílẹ̀ Yúróòpù, nǹkan bí ẹgbàafà [12,000] Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n há mọ́ ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ọgbà ẹ̀wọ̀n Násì, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ló sì kú. Àwọn ọ̀gágun tó ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ítálì, Japan, Kòríà, àti Taiwan náà fojú àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ rí màbo. Kódà láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ oníjọba tiwa-n-tiwa pàápàá, àwọn Ajagun Kátólíìkì gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n fi ọ̀dà tí wọ́n fi ń ṣe títì kùn wọ́n, wọ́n wá lẹ ìyẹ́ mọ́ wọn lára, wọ́n sì lé wọn kúrò nílùú. Àwọn kan da àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí rú, àwọn aláṣẹ sì tún lé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí kúrò nílé ìwé.

      29. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ìtura tó dé láti orísun tí a kò retí? (b) Báwo ló ṣe jẹ́ pé “ilẹ̀ ayé wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún obìnrin náà”? (d) Kí ni dírágónì náà ò yéé ṣe?

      29 Ìtura dé láti orísun kan tí a kò retí. Ìṣípayá sọ pé: “Ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún obìnrin náà, ilẹ̀ ayé sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé odò náà mì, èyí tí dírágónì náà pọ̀ jáde láti ẹnu rẹ̀. Dírágónì náà sì kún fún ìrunú sí obìnrin náà, ó sì lọ láti bá àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ rẹ̀ ja ogun, àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:16, 17) “Ilẹ̀ ayé,” ìyẹn àwọn ètò ẹ̀dá èèyàn tí ń bẹ nínú ètò àwọn nǹkan Sátánì, bẹ̀rẹ̀ sí í gbé “odò,” tàbí “ìkún omi” náà mì. Láàárín ọdún 1940 sí 1949, àwọn Ẹlẹ́rìí rí ojú rere Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti tàwọn alágbára tí ń ṣàkóso láwọn ilẹ̀ mìíràn, tí wọ́n mọrírì òmìnira ìsìn. Níkẹyìn, àwọn orílẹ̀-èdè Alájùmọ̀ṣepọ̀ gbé ìjọba Násì òun ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ tó jẹ́ òǹrorò mì pátápátá, èyí sì jẹ́ kára tu àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti jìyà lábẹ́ àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ oníkà. Àmọ́ inúnibíni ò dáwọ́ dúró pátápátá o, nítorí pé ìbínú dírágónì náà ṣì ń bá a lọ títí dòní, kò sì yéé gbógun ti àwọn tí wọ́n “ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin ṣì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, síbẹ̀ àwọn kan ṣì ń kú nítorí ìwà títọ́ wọn. Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn aláṣẹ sábà máa ń dẹwọ́ inúnibíni tí wọ́n ń ṣe, èyí sì ń jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí ní òmìnira ìsìn.c Nípa báyìí, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe wí, ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti gbé omilẹgbẹ inúnibíni mì.

      30. (a) Kí ni ilẹ̀ ayé ti pèsè ìtura tó pọ̀ tó fún láti ṣẹlẹ̀? (b) Kí ni ìwà títọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run ti yọrí sí?

      30 Lọ́nà yìí, ilẹ̀ ayé ti pèsè ìtura tó pọ̀ tó láti jẹ́ kí iṣẹ́ Ọlọ́run gbòòrò dé òjìlénígba ó dín márùn-ún [235] ilẹ̀ àti láti mú ohun tó ju mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn olùṣòtítọ́ oníwàásù ìhìn rere jáde. Yàtọ̀ sáwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá èèyàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ jákèjádò ayé ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ní ti pé wọ́n yà sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, wọ́n ń hu ìwà rere, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wọn, wọ́n sì ń jẹ́rìí nípa Ìjọba Mèsáyà. Ìwà títọ́ wọn ń fi hàn pé irọ́ funfun báláú ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi pẹ̀gàn Ọlọ́run, ó sì tún fi hàn pé ìparun ò ní pẹ́ dé bá Sátánì àti ètò àwọn nǹkan rẹ̀.—Òwe 27:11.

  • Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • Orí 28

      Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà

      Ìran 8—Ìṣípayá 13:1-18

      Ohun tó dá lé: Ẹranko ẹhànnà olórí méje náà, ẹranko ẹhànnà oníwo méjì, àti ère ẹranko ẹhànnà náà

      Ìgbà tó nímùúṣẹ: Láti ọjọ́ Nímírọ́dù títí di ìgbà ìpọ́njú ńlá

      1, 2. (a) Kí ni Jòhánù wí nípa dírágónì náà? (b) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ètò tó ṣeé fojú rí tí dírágónì náà ń lò?

      ÁÀ, MÁÍKẸ́LÌ ti fi dírágónì náà sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé! Ohun tá a ti rí kọ́ nínú Ìṣípayá ti mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ò ní gba Ejò náà tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láàyè láé láti padà sọ́run. Àmọ́, a ṣì wà lórí ọ̀rọ̀ “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Ohun tí Sátánì ń lò láti fi bá ‘obìnrin náà àti irú-ọmọ rẹ̀ jà’ ni àkọsílẹ̀ tó tẹ̀ lé e sọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. (Ìṣípayá 12:9, 17) Jòhánù sọ nípa dírágónì tó rí tó dà bí ejò pé: “Ó sì dúró jẹ́ẹ́ lórí iyanrìn òkun.” (Ìṣípayá 13:1a) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí dírágónì náà ń lò.

      2 Ọ̀rọ̀ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń dá wàhálà sílẹ̀ lọ́run tó jẹ́ ibi mímọ́ ti dìtàn báyìí. Àfẹ́kù ti bá wọn lókè ọ̀run, wọn ò sì lè kọjá sàkáání ilẹ̀ ayé tí wọ́n wà báyìí mọ́. Ìdí rèé tí ìwà bí-èṣù-bí-èṣù fi ń pọ̀ sí i lọ́nà tó pabanbarì lóde òní. Ejò alárèékérekè yìí ṣì ní ètò ẹ̀mí tá ò lè fojú rí tó ti díbàjẹ́. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó ń lo ètò tá a lè fojú rí láti ṣi aráyé lọ́nà? Jòhánù sọ fún wa pé: “Mo sì rí ẹranko ẹhànnà kan tí ń gòkè bọ̀ láti inú òkun, ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje, adé dáyádémà mẹ́wàá sì wà lórí àwọn ìwo rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn orúkọ tí ó kún fún ọ̀rọ̀ òdì wà ní àwọn orí rẹ̀. Wàyí o, ẹranko ẹhànnà náà tí mo rí dà bí àmọ̀tẹ́kùn, ṣùgbọ́n ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ti béárì, ẹnu rẹ̀ sì dà bí ẹnu kìnnìún. Dírágónì náà sì fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.”—Ìṣípayá 13:1b, 2.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́