ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/05 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 5/05 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 9

Orin 217

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ẹ lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ May 15 àti Jí! June 8. Ẹ tún lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà. Nínú ọ̀kan lára ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìròyìn láìjẹ́ bí àṣà nínú ọkọ̀ èrò.

15 min: Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láti Dénú Ọkàn. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ February 1, 2005, ojú ìwé 28 sí 31. Ṣàlàyé kúnnákúnná nípa bí Jésù ṣe lo Ìwé Mímọ́ láti ran Pétérù lọ́wọ́. Jíròrò bá a ṣe lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù nígbà tó bá yẹ ká tún ìrònú àti ìṣesí àwọn ọmọ wa, tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, tàbí ti àwa fúnra wa pàápàá ṣe.

20 min: “Ṣe Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé Tá Á Ṣeé Tẹ̀ Lé.” Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ tí kò gbọ́dọ̀ tó ìṣẹ́jú méjì, sọ ìdí tó fi yẹ kí ìdílé ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lákọọ́lẹ̀, kó o sì jíròrò bá a ṣe lè kọ ohun tá a ó máa ṣe sínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a fi ṣàpẹẹrẹ lójú ìwé 6. Kó o wá jíròrò àpilẹ̀kọ náà, “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Àwọn Ìpàdé Ìjọ” lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é táwọn ìgbòkègbodò míì kì í fi í dí wọn lọ́wọ́ láti pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé ìjọ. A ó máa jíròrò àwọn apá tó kù lára ìṣètò ìdílé láwọn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀.

Orin 176 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 16

Orin 201

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù May sílẹ̀. Ní ṣókí, ṣàgbéyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọnà!,” tó wà lójú ìwé 7. Sọ fáwọn ará pé inú àpilẹ̀kọ yìí ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá a ṣe máa ka ìwé pẹlẹbẹ náà wà. Fún àwọn ará ní ìṣírí pé kí wọ́n múra sílẹ̀ dáadáa kí wọ́n lè máa lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tó máa bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ May 23.

15 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Ìdílé.”a Sọ pé káwọn ará sọ àǹfààní tí wọ́n ti rí nínú jíjùmọ̀ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé lóde ẹ̀rí.

20 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kẹsàn-án.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, ṣàlàyé kókó kan tàbí méjì látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù December ọdún 2004, ojú ìwé 8. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kan nípa bá a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí wọ́n bá ti parí ẹ̀kọ́ 2 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, kí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bi akẹ́kọ̀ọ́ pé: “Báwo ni wàá ṣe ṣàlàyé orúkọ Ọlọ́run fún ọ̀rẹ́ rẹ?” Akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò wá ṣàlàyé bó ṣe máa lo Sáàmù 83:18, lẹ́yìn náà kí olùkọ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Orin 134 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 23

Orin 194

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lẹ́yìn ìròyìn ìnáwó, ka lẹ́tà tí ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́ nítorí ọrẹ tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ June 1. Ẹ tún lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà.

18 min: “Ọjọ́ Jèhófà Ti Sún Mọ́lé.”c Nígbà tó o bá ń múra ibí yìí sílẹ̀, wo ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 59, ìpínrọ̀ 28.

15 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé.”d Sọ fún akéde kan tàbí méjì ṣáájú àkókò pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti sọ bí wọ́n ṣe ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn àti ìsapá tí wọ́n ṣe láti lè rí i pé kì í yẹ̀.

Orin 152 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 30

Orin 190

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù May sílẹ̀. Mẹ́nu ba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù June. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe máa lò ó nípa lílo àbá kan tàbí méjì lára àwọn àbá tá a dámọ̀ràn nínú àfikún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu). Ẹ tún lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tó dára.

20 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Ẹ̀kọ́ Ojoojúmọ́.”e Ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ nípa bí ìdílé wọn ti ṣe jàǹfààní látinú kíka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé àti pé àsìkò wo ni wọ́n fi sí tó mú kó rọrùn fún wọn.

15 min: Ẹ sọ àwọn ìrírí tẹ́ ẹ ní nínú iṣẹ́ ìsìn pápá láàárín oṣù March, April àti May tàbí kẹ́ ẹ ṣe àṣefihàn wọn. Sọ fún ẹnì kan tàbí méjì ṣáájú pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti sọ ìsapá tí wọ́n ṣe láti lè fi kún iṣẹ́ ìsìn wọn láàárín àkókò Ìṣe Ìrántí àti àkókò tá a pín ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà!, kí wọ́n sì sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n rí nínú rẹ̀.

Orin 115 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 6

Orin 155

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Mú Kí Ìfẹ́ Àwọn Tó Ò Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé Jinlẹ̀ Sí I.”f Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, fa àwọn kókó tó wà nínú ìwé Reasoning lójú ìwé 227 sí 232 yọ. Àwọn àlàyé tó wà níbẹ̀ lè wúlò láti múra onírúurú ìjíròrò tá a lè fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣe sílẹ̀ nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa gbé ṣe. Ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe lè lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣoṣo láti fi bá ẹni tó máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé sọ̀rọ̀. Kí akéde ṣàlàyé rẹ̀ ní ṣókí, kó sì jẹ́ kí ẹni yẹn mọ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe kàn án, kó lè yé e dáadáa, kó sì mọ bó ṣe máa wúlò fóun tó nígbèésí ayé.

Orin 107 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́