ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/05 ojú ìwé 2-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 6/05 ojú ìwé 2-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù June: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà ni kẹ́ ẹ lò, báwọn kan bá sì sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Ẹ gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. July àti August: Èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé 32 yìí ni kẹ́ ẹ lò: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọ́run Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la ó lò. Ẹ sì lè lo ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà bí àfirọ́pò.

◼ Ẹ fi ẹ̀dà kan ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà sínú ibi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àlàyé síwájú sí i nípa ibi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2003 ojú ìwé 5 àti Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 1997.

◼ Kí akọ̀wé ìjọ máa rí i dájú pé òun jẹ́ kí ẹ̀ka ọ́fíìsì máa mọ ipò akéde tó ti ṣèrìbọmi, tó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Volunteer Worker Questionnaire (S-82). Bí ipò akéde náà bá ti yí padà, bíi kó ti lọ sí ìjọ mìíràn tàbí kó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni kí wọ́n fún un ni fọ́ọ̀mù mìíràn tàbí kó béèrè fún un, kó wá dáhùn ìbéèrè tó wà nínú ẹ̀ kó sì fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ. Bí àdírẹ́sì tàbí nọ́ńbà fóònù ẹni náà bá ti yí padà tàbí tó bá ṣi ẹsẹ̀ gbé, kí ẹ̀yin alàgbà tètè kọ lẹ́tà láti fi tó ẹ̀ka ọ́fíìsì létí.

◼ Àwọn Ike Pẹlẹbẹ Àtẹ́tísí Tuntun Tó Wà:

Ṣiṣe Ifẹ-inu Ọlọrun Pẹlu Itara—Gẹ̀ẹ́sì

Ẹ̀yin Ìdílé—Ẹ Jẹ́ Kí Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́ Jẹ́ Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Yín—Gẹ̀ẹ́sì

Ẹ Jẹ́ Kí Ojú Yín Mú Ọ̀nà Kan—Gẹ̀ẹ́sì

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà (ike pẹlẹbẹ méje ló wà nínú rẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì

Èé Ṣe Tí A Fi Ní Láti Bọ̀wọ̀ fún Ìṣètò Ìṣàkóso Ọlọ́run?—Gẹ̀ẹ́sì

◼ Àwọn Ike Pẹlẹbẹ DVD Tuntun Tó Wà:

Noah Walked With God—David Trusted in God—Gẹ̀ẹ́sì

Young People Ask—What Will I Do With My Life?—Gẹ̀ẹ́sì

ÀKÍYÈSÍ: Ẹni tó bá ní ẹ̀rọ tá a fi ń wo DVD nìkan ni kó béèrè fún àwọn ike pẹlẹbẹ méjì yìí. Ẹ̀rọ tá a fi ń wo DVD yàtọ̀ sí ẹ̀rọ tá a fi ń gbọ́ ike pẹlẹbẹ àtẹ́tísí CD tàbí èyí tá a fi ń wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ tá a ṣe sórí ike pẹlẹbẹ o.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́