Tọ́jú Rẹ̀
Àwọn Àbá Nípa Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Lóde Ẹ̀rí
Ọ̀kan-ò-jọ̀kan àbá ló wà nínú àkìbọnú yìí tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá ń múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó o máa lò láti fún àwọn èèyàn ní ìwé pẹlẹbẹ lóde ẹ̀rí. O lè yí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà padà kó lè bá bí nǹkan ti rí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Tàbí kó o lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn. Bó bá sì jẹ́ àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí a ò dábàá bá a ṣe máa lò wọ́n sínú àkìbọnú yìí lo fẹ́ lò, lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí bí àpẹẹrẹ.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005, ojú ìwé 8.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àbá tó wà lójú ìwé yìí ló ní (1) ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ láti fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, (2) ibi tá a ti lè rí kókó tá à ń sọ̀rọ̀ lé lórí nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, àti (3) ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mú tá a lè kà nígbà ìjíròrò. O lè sọ̀rọ̀ tó kù fúnra ẹ bó bá ṣe bá èsì ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ mu.
Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ojútùú sáwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wá lónìí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o rò pé ìjọba kan á wà tó máa lè yanjú àwọn ìṣòro yìí?”—ojú ìwé 3, ìpínrọ̀ 1; Mát. 6:9, 10.
Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ọ̀run làwọn ti máa lọ jẹ̀gbádún ìyè àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n kí lèrò tìẹ nípa gbígbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé?”—Àwòrán tó wà níwájú ìwé; Ìṣí. 21:4.
Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
“Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì wúlò lásìkò tá a wà yìí?”—ojú ìwé 22, ọ̀rọ̀ wínníwínní tó wà lábẹ́ àkòrí tó wà níbẹ̀; ojú ìwé 23, ìpínrọ̀ 3 nínú àpótí; Òwe 25:11.
Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?
“Èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ní nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Ṣó o rò pé èrò yòówù ká ní ṣe pàtàkì?”—ojú ìwé 3, ìpínrọ̀ 3, 7, àti 8; Jòh. 17:3.
Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
“Bí ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ ẹni bá kú, ó máa ń ṣeni bíi pé kéèyàn mọ ibi tó wà àti bóyá ojú á tiẹ̀ túnra rí lọ́jọ́ kan. Ǹjẹ́ irú ìbéèrè yìí ò ti wá sí ọ lọ́kàn rí?”—Ìbéèrè tó wà lẹ́yìn èèpo ìwé; Jóòbù 14:14, 15.
Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú
“Ìwé pẹlẹbẹ tá à ń pín lónìí yìí ti tu ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan wọn ti kú nínú, wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tó nírètí. Ǹjẹ́ o rò pé ìrètí kankan wà fẹ́ni tó ti kú?”—ojú ìwé 27, ìpínrọ̀ 3; Jòh. 5:28, 29.
“Ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí ronú nípa béèyàn ṣe lè tu ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú?”—ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 1; Òwe 17:17.
Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
“Èyí tó pọ̀ nínú wa ló mọ àdúrà kan tá a máa ń bẹ̀rẹ̀ báyìí pé ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ká bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ.’ (Mát. 6:9, Bibeli Mimọ) Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ̀ pé bá a bá fẹ́ rí ìgbàlà àfi ká mọ orúkọ yẹn?”—ojú ìwé 28, ìpínrọ̀ 1; Róòmù 10:13.
“Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
“Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti máa ṣàníyàn bíi tèmi nípa àwọn àṣàkaṣà tó kún ìgboro fọ́fọ́ báyìí àti bó ṣe ń sọ àwọn ọmọ dìdàkudà. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ́ nípa bí nǹkan ṣe máa rí lásìkò yìí wà nínú ìwé kan tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíkọ rẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, nígbà tí kò tíì sí ẹ̀sìn Ìsìláàmù, ẹ̀sìn Kristẹni àtẹ̀sìn Híńdù pàápàá?”—ojú ìwé 25, ìpínrọ̀ 47; 2 Tím. 3:1-3.