Àwọn Àbá Nípa Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
Lẹ́yìn tó o bá ti mẹ́nu ba ìròyìn nípa aburú kan tó ṣẹlẹ̀, o lè sọ pé:
“Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa ìdí tí Ọlọ́run fi ń wò wá níran tá à ń ráre báyìí bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ wa dénú? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìbéèrè náà, ó sì fi ohun tí Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ ọ̀la hàn kedere. [Fi àwòrán tó wà lójú ìwé 27 hàn án, kó o sì ka Sáàmù 145:16 bó ṣe wà ní ìpínrọ̀ 22.] Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run máa gbà mú gbogbo ìyà táráyé ti jẹ kúrò? Bí mo bá padà wá, ìyẹn ni ìbéèrè tá a máa gbé yẹ̀ wò.” Fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà kẹ́ ẹ sì jọ ṣètò ìgbà tó o máa padà bẹ̀ ẹ́ wò.
Nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò, o lè sọ pé:
“Lọ́jọ́ tí mo wá kẹ́yìn, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí la kà. [Ka Sáàmù 145:16 látinú Bíbélì tàbí kó o sọ ohun tó wà níbẹ̀.] Lọ́jọ́ yẹn mo béèrè pé: Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run máa gbà mú gbogbo ìyà táráyé ti jẹ kúrò?” Sọ fún un pé kóun náà mú ìwé tiẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ẹ ṣí i sí ojú ìwé 27 sí 28, kẹ́ ẹ sì jíròrò ìpínrọ̀ 23 sí 25. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́, tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣètò láti jíròrò ìpínrọ̀ 26 sí 27 nígbà tó o bá padà tọ̀ ọ́ lọ.
Akéde kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tiẹ̀ lọ́nà yìí:
“Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ ọ̀gbà ló fẹ́ mọ báyé ṣe máa rí lọ́dún mẹ́wàá tàbí lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún òní. Kí lèrò ẹ nípa báyé ṣe máa rí nígbà yẹn? [Jẹ́ kó fèsì.] Ṣe làwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wá lónìí ń fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà. [Ka 2 Tímótì 3:1-3.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀lé e yìí. [Ka àwọn ìbéèrè tó wà níwájú ìwé pẹlẹbẹ náà fún un, kó o wá fi ìwé náà lé e lọ́wọ́.] Bó o bá lè fi ìṣẹ́jú díẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí mo bá padà wá, màá fẹ́ ṣàlàyé ohun tó máa gbẹ̀yìn àìsàn àti ọjọ́ ogbó fún ọ.” Rí i pé o padà bẹ̀ ẹ́ wò.
Nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò, o lè sọ pé:
“Nígbà tá a sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, mo ní ó wù mí kí n sọ ohun tó máa gbẹ̀yìn àìsàn àti ọjọ́ ogbó fún ọ. Inú ìwé yìí làwọn nǹkan yẹn wà.” Ní kóun náà mú ìwé tiẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ 6 sí 7 lójú ìwé 23 sí 24 kẹ́ ẹ wá jọ jíròrò rẹ̀. Sọ fún un pé ìpínrọ̀ 8 sí 9 lẹ máa jíròrò nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò.
Bí àgbàlagbà bá ń bá ọmọdé kan ṣiṣẹ́, àgbàlagbà lè kí onílé kó sì sọ ohun tó gbé wọn dé iwájú rẹ̀, pé:
“Jọ̀wọ́, màá fẹ́ kí ________ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún ọ. [Kí ọmọ náà ka Sáàmù 37:29 kó sì ṣàlàyé ṣókí.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí jíròrò bí Ọlọ́run ṣe máa mú kí ìfẹ́ rẹ̀ fún aráyé àti nípa ilẹ́ ayé yìí ní ìmúṣẹ. [Fi àwòrán tó wà lójú ìwé 24 sí 27 hàn án.] Nígbà tá a bá padà wá, mo máa fẹ́ láti fi àgbàyanu ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa àjíǹde hàn ọ́.” Fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà kẹ́ ẹ sì jọ ṣètò ìgbà tẹ́ ẹ máa bẹ̀ ẹ́ wò.
Nígbà tẹ́ ẹ bá padà bẹ̀ ẹ́ wò, kí àgbàlagbà yẹn sọ pé:
“Nígbà tí mo wá kẹ́yìn, a ka Sáàmù 37:29, mo sì sọ pé mó máa fẹ́ láti fi ohun tí Bíbélì sọ nípa àjíǹde hàn ọ́. Kíyè sí bí ibí yìí ṣe kà.” Ní kóun náà mú ìwé tiẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò ìpínrọ̀ 12 sí 14 lójú ìwé 24 sí 25. Bá a sọ̀rọ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí kẹ́ ẹ ṣètò láti jíròrò ìpínrọ̀ 15 sí 16 nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò.