Àwọn Àbá Nípa Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
Lẹ́yìn tó o bá ti kí onílé tán, o lè sọ pé:
“Lóde òní, kò sí bá a ṣe lè ṣe é tí a ó fi bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro tàbí kí ohunkóhun máà já wa kulẹ̀. Ṣé o rò pé bó ṣe yẹ kí ìgbésí ayé rí nìyẹn? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìfẹ́ rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé àtàwọn èèyàn inú rẹ̀ ṣẹ. [Jíròrò àwòrán tó wà lójú ìwé 20 àti 21. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ 9, kó o sì fa kókó tó wà nínú Aísáyà 14:24 àti 46:11 yọ.] Nígbà tí mo bá padà wá, màá fẹ́ fi ẹsẹ Bíbélì tó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa sọ ilẹ̀ ayé yìí di Párádísè, bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ hàn ọ́.” Fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà, kẹ́ ẹ sì jọ ṣètò ìgbà tó o máa padà bẹ̀ ẹ́ wò.
Nígbà tó o bá padà lọ, o lè sọ pé:
“Lọ́jọ́ tí mo wá kẹ́yìn, mo sọ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé káwọn èèyàn máa gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. [Fi àwòrán tó wà lójú ìwé 20 àti 21 hàn án lẹ́ẹ̀kan sí i.] Kíyè sí i pé Jésù, Pétérù àti Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa Párádísè.” Ní kó mú ìwé tiẹ̀ náà lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ṣí i sí ojú ìwé 21 sí 22, kẹ́ ẹ sì jíròrò ìpínrọ̀ 10 sí 13. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́, tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣètò láti jíròrò ọ̀kan lára àwọn ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 29 sí 30 nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò.
Akéde kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tiẹ̀ lọ́nà yìí:
“Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ ọ̀gbà ló ń ṣiyèméjì nípa ọjọ́ ọ̀la. Ṣó o rò pé nǹkan á ṣẹnuure fáwọn ìran tó ń bọ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la tó mìrìngìndìn fún gbogbo èèyàn. [Ṣí ìwé náà sí àwòrán tó wà lójú ìwé 31 kó o sì ka ọ̀rọ̀ tó wà láàárín àwòrán náà. Lẹ́yìn náà, ka 2 Pétérù 3:13.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣàlàyé ìbùkún tí Ọlọ́run ti ṣètò sílẹ̀ fún aráyé. [Fa kókó tó wà lábẹ́ àwọn ìsọ̀rí tó dúdú yàtọ̀ lójú ìwé 29 sí 30 yọ, kó o sì fún onílé ní ìwé pẹlẹbẹ náà.] Màá fẹ́ padà wá kí n lè sọ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe láti fòpin sí ogun fún ọ.” Rí i pé o padà bẹ onílé náà wò.
Nígbà tó o bá padà lọ, o lè sọ pé:
“Lọ́jọ́ tí mo wá kẹ́yìn, mo sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run láti sọ ilẹ̀ ayé yìí di Párádísè bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. [Rán an létí àwòrán tó wà lójú ìwé 31.] Ngbọ́, báwo ni nǹkan á ṣe rí bí Ọlọ́run bá fòpin sí ogun?” Ní kó mú ìwé tiẹ̀ náà lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ 3 sí 6 lójú ìwé 29, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Ẹ jọ ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa jíròrò ìpínrọ̀ 7 sí 8 nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò.
Bí àgbàlagbà bá ń bá ọmọdé kan ṣiṣẹ́, àgbàlagbà lè kí onílé kó sì sọ ohun tó gbé wọn dé iwájú rẹ̀, pé:
“Jọ̀wọ́, màá fẹ́ kí, ________ fi àwòrán kan hàn ọ́ kó sì ka ẹsẹ Bíbélì kan. [Kí ọmọ náà fi àwòrán hàn án, kó sì ka ọ̀rọ̀ tó wà lójú ìwé 31, lẹ́yìn ìyẹn kó wá ka Ìṣípayá 21:4.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run máa ṣe nípa àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wá lónìí. [Ní ṣókí, fa kókó tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí tó dúdú yàtọ̀ lójú ìwé 29 sí 30 yọ, kó o sì fún un ní ìwé pẹlẹbẹ náà.] Nígbà tá a bá padà wá, màá fi ohun tí Bíbélì sọ nípa bí òpin ṣe máa dé bá gbogbo àìlera tó ń dojú kọ wá hàn ẹ́.”
Nígbà tẹ́ ẹ bá padà lọ, àgbàlagbà yẹn lè sọ pé:
“Nígbà tá a sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, mo sọ pé mó fẹ́ fi ohun tí Bíbélì sọ nípa bí òpin ṣe máa dé bá gbogbo àìlera tó ń dojú kọ wá hàn ẹ́. Kíyè sí bí ibí yìí ṣe kà.” Ní kó mú ìwé tiẹ̀ náà lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò ìpínrọ̀ 9 sí 14 lójú ìwé 29. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́ tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣètò láti jíròrò ìpínrọ̀ 15 sí 17 nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò.