Ìwé Pẹlẹbẹ Tó Wà Fáwọn Tí Kì í Ṣe Kristẹni
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I
Bó bá jẹ́ ẹlẹ́sìn àbáláyé lò ń bá sọ̀rọ̀, o lè sọ pé:
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jọ́sìn àwọn baba ńlá wọn tó ti kú. Ìjọsìn àwọn baba ńlá ni ọ̀pọ̀ àṣà ìsìnkú dá lé lórí. Kí ló mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn àwọn baba ńlá tàbí kí wọ́n máa júbà wọn? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka ìpínrọ̀ 1 àti 2 lójú ewé 12 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà.] Ǹjẹ́ àwọn baba ńlá wa tó ti kú tiẹ̀ mọ̀ pé à ń ṣe nǹkan kan fún àwọn? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Oníwàásù 9:5, 10.] Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé wọn ò mọ nǹkan kan, kò ní bójú mu ká máa jọ́sìn wọn o. O lè kà sí i nípa kókó yìí lábẹ́ ẹ̀kọ́ 4 nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.”
Akoko fun Ijuwọsilẹ—tẹriba Tootọ fun Ọlọrun
Bó bá jẹ́ Mùsùlùmí lò ń bá sọ̀rọ̀, o lè sọ pé:
“Àwọn Mùsùlùmí ni mò ń wá ká lè jọ fèròwérò. Mo mọ̀ pé àwọn Mùsùlùmí gbà pé ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́run, wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú àwọn òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán. Àbí kí lo ní mo sọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Màá fẹ́ ká jọ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí ilẹ̀ ayé wa yìí máa gbà di Párádísè. Ṣé kí n ka ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Ìṣípayá 21:3, 4.] Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí mú mi rántí àlàyé kan nínú Àlùkùránì tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.” Ṣí ìwé náà sí ojú ìwé 15, kó o sì ka ìpínrọ̀ 4. Bó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìjíròrò náà, ẹ tún jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 4 lójú ìwé 46 sí 47.