ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/06 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 1/06 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 9

Orin 10

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ January 15 àti Jí! January-March. Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, jẹ́ kí akéde kan wàásù níbi táwọn èèyàn ti ń ṣòwò.

15 min: Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn-Àyà Jèhófà Yọ̀. (Òwe 27:11) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn méjì tàbí mẹ́ta tó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń sin Jèhófà. Ní kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sọ ohun kan tàbí méjì tó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà nìṣó. Lára àwọn nǹkan tí wọ́n lè mẹ́nu bà ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì taápọn taápọn, pípésẹ̀ sáwọn ìpàdé déédéé, bíbá àwọn ẹni ìdúróṣinṣin bíi tiwọn kẹ́gbẹ́, kíkópa tọkàntara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, gbígbàdúrà látọkànwá, àti sísá fáwọn eré ìnàjú tí ò bójú mu. Kí ló ti mú kó ṣòro fún wọn láti ṣègbọràn báwo ni wọ́n sì ṣe borí rẹ̀? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n ti rí látàrí jíjẹ́ onígbọràn?

20 min: “Ayé Tẹ́nikẹ́ni Ò Ti Ní Tòṣì Sún Mọ́lé.” Alàgbà kan ni kó sọ àsọyé yìí tá a gbé karí Ilé Ìṣọ́ May 15, 2005 ojú ìwé 4 sí 7. Jíròrò àsọyé náà bó bá ṣe bá ìjọ yín mu láàárín àkókò tá a yàn.

Orin 15 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 16

Orin 178

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù January sílẹ̀. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti wo fídíò náà, Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò tó máa wáyé lọ́sẹ̀ méjì tó ń bọ̀ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn.

15 min: A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ojú ìwé 4 sí 7 nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò gbọ́dọ̀ tó ìṣẹ́jú mẹ́ta tó dá lórí ojú ìwé 4, jíròrò ìpínrọ̀ 5 títí dé ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó wà lójú ìwé 7, pẹ̀lú àwùjọ. A óò jíròrò àwọn apá mìíràn nínú ìwé A Ṣètò Wa ní àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

20 min: “Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Tàn bí Ìmọ́lẹ̀.”a Ní káwọn ọ̀dọ́ sọ bí wọ́n ṣe máa ń wàásù nílé ẹ̀kọ́. O lè ṣètò pé kẹ́nì kan tàbí méjì múra sílẹ̀ ṣáájú.

Orin 107 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 23

Orin 60

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ọrẹ tá à ń ṣe. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìjọ yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ February 1. Jẹ́ kí ọ̀dọ́ kan wà lára àwọn tó máa ṣe àṣefihàn náà.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Bíbéèrè Ìbéèrè àti Fífetísílẹ̀.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, ní kí àwùjọ sọ àwọn ìbéèrè tí wọ́n rí i pè ó máa ń wúlò gan-an láti fi bẹ̀rẹ̀ ìfèròwérò. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè mú káwọn èèyàn sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn nípa fífọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè àti nípa fífetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀.

Orin 205 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 30

Orin 197

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù January sílẹ̀. Mẹ́nu ba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù February, kó o sì ṣe àṣefihàn ọ̀nà kan tá a lè gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀.

15 min: Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́ Tó Wà fún Àǹfààní Wa. Alàgbà ni kó sọ ọ́. Ka lẹ́tà January 3, 2006 tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ sí gbogbo ìjọ nípa àwọn ọ̀nà tá a lè gbà jàǹfààní akitiyan àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) àti Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò (PVG).

20 min: “Fídíò Tó Ṣàlàyé Ohun Pàtàkì Kan Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lọ́wọ́ Nínú Ọ̀ràn Ìṣègùn.” Ka Ìṣe 15:28, 29, kó o sì ṣàlàyé rẹ̀ ní ṣókí pé òfin tí Ọlọ́run fún wa lórí ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ ló jẹ́ ìdí pàtàkì táwa Kristẹni kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀ sára. Lẹ́yìn náà kó o wá lọ tààrà sórí ìjíròrò fídíò náà, Patient Needs and Rights. Àwọn ìbéèrè tá a tẹ̀ sínú àpilẹ̀kọ ni kó o lò. Ka ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn láti fi kádìí ìjíròrò náà. Gẹ́gẹ́ bí àfidípò, ẹ jíròrò “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004 àti October 15, 2000.

Orin 45 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 6

Orin 74

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: “A Fẹ́ Kó O Ṣèrànwọ́.”c Fọ̀rọ̀ wá alàgbà kan lẹ́nu wò ní ṣókí. Ní kó sọ ohun tó mú kó fẹ́ láti máa sìn nínú ìjọ àtohun tó ràn án lọ́wọ́ láti tóótun.

15 min: Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Ń Mú Ìbùkún Wá. (Òwe 10:22) Ní káwọn tó ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún tó kọjá sọ ètò tí wọ́n ṣe láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì sọ ayọ̀ àti ìbùkún tí wọ́n ti rí nínú rẹ̀. Gba àwùjọ níyànjú láti fi ọ̀rọ̀ ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March, April àti May sínú àdúrà.

Orin 16 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́