ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/06 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 29
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 5
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 5/06 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 8

Orin 2

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ May 15 àti Jí! April-June. (Lo àbá kẹta fún Jí! April-June.) Nínú àṣefihàn kan, ní kí akéde náà fún ẹni tó máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé àmọ́ tí ò tíì fún ní ti May 1 ní ẹ̀dà kan Ilé Ìṣọ́ May 1 àti Ilé Ìṣọ́ May 15 pa pọ̀ mọ́ Jí! April-June. Nígbà tó bá ń fún un ní ìwé ìròyìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ẹyọ kan ni kó sọ̀rọ̀ lé lórí. Àwọn akéde lè bẹ ẹni tí wọ́n máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé wò lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì lóṣù.

12 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Gbígba Tiwọn Rò.”a

23 min: “Ẹ Má Fara Wé Àwọn Èèyàn Ayé.”b Alàgbà ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Ka gbogbo ìpínrọ̀.

Orin 91 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 15

Orin 9

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù May sílẹ̀. Gba àwọn ará níyànjú láti wo fídíò Nóà bá Ọlọ́run rìn, tá a ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Noah—He Walked With God láti lè múra sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ May 29 tá a ó ti gbé e yẹ̀ wò.

10 min: Bá A Ṣe Ń Ṣiṣẹ́ Pọ̀ Níṣọ̀kan Lábẹ́ Ìdarí Kristi. Àsọyé tó dá lórí àlàyé tó wà lábẹ́ àkòrí náà, “Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Mọ Ipa Tí Kristi Ń Kó” nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 13 sí 15.

25 min: “Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba—Ọ̀kan Pàtàkì Lára Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́.”c Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ti lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí tí wọ́n ti kópa nínú ṣíṣàtúnṣe àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Orin 133 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 22

Orin 86

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ June 1 àti Jí! April-June. (Lo àbá kẹrin fún Jí! April-June.) Ṣe àṣefihàn ìdílé kan tó ń fi bí wọ́n ṣe máa pín ìwé ìròyìn dánra wò.

15 min: “Ẹ ‘Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo.’”d Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde àwòfiṣàpẹẹrẹ kan tó ń sapá láti gbé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ tó sì ti dín àwọn ohun tó ń lépa kù torí àtilè tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run kó bàa lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́. Sọ̀rọ̀ lórí ìbùkún tó ti rí látinú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

18 min: Ìrísí Tó Dára. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 131 sí 133. Jíròrò àwọn kókó márùn-ún tó jẹ mọ́ irú aṣọ tó yẹ ká máa wọ̀ àti bó ṣe yẹ ká máa múra. Mẹ́nu bà á pé a lè fọgbọ́n lo kókó yìí láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bó ṣe yẹ ká máa múra wá sí àwọn ìpàdé ìjọ.

Orin 215 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 29

Orin 42

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù May sílẹ̀.

10 min: Ìwé Olùkọ́ la ó fi sóde lóṣù June. Nípa lílo àwọn àbá tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005, ojú ìwé 3 sí 4 tàbí ọ̀nà ìgbékalẹ̀ míì tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe bí wọ́n ṣe ń lo ìwé náà lóde ẹ̀rí tàbí pẹ̀lú ìdílé tiwọn fúnra wọn.

25 min: “Àwòkọ́ṣe fún Tèwe Tàgbà.” Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ò gbọ́dọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, lọ tààràtà sórí ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ lórí ìbéèrè tó wà nínú fídíò Nóà, gbogbo ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ni kó o lò.

Gẹ́gẹ́ bí àfidípò, o lè jíròrò “Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Oníwà Ipá Lo Fi Ń Wò Wọ́n?” èyí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2000, ojú ìwé 26 sí 29.

Orin 9 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 5

Orin 176

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: Bí A Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ November 15, 2003, ojú ìwé 16, àpótí. Jíròrò àbá méjèèje kó o wá ní kí àwùjọ sọ bá a ṣe lè lò wọ́n ládùúgbò yín. Gba àwọn akéde níyànjú láti fi ṣe àfojúsùn wọn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo ẹni tó bá gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ wọn tàbí tó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nípa lílo ọ̀kan lára àwọn àbá tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2006, ojú ìwé 6, ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n nígbà ìpadàbẹ̀wò.

25 min: “Ẹ Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Àwọn Àṣà Ayé Níbi Ìsìnkú.”e Alàgbà ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Ka gbogbo ìpínrọ̀.

Orin 57 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́