Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 10
Orin 4
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù July sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ July 15 àti Jí! July-September. Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn báwọn ará ṣe lè dá ẹni tí ò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lóhùn tó wá sọ pé ‘Kristẹni ni àwa náà níbí.’—Wo Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 11.
15 min: Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ àti Bá A Ṣe Ń Darí Rẹ̀. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 4.
20 min: “Mú Káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Mọrírì Àwọn Ànímọ́ Jèhófà Tí Ò Láfiwé.”a Fi àṣefihàn kan kún un èyí tó máa fi hàn bá a ṣe lè fi ìbéèrè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn kókó tó wà nínú àpótí àtúnyẹ̀wò níparí orí àkọ́kọ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.
Orin 88 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 17
Orin 99
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ní ṣókí, jíròrò Ilé Ìṣọ́ August 15, 2000, ojú ìwé 32. Tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní tó wà nínú kíka Bíbélì lójoojúmọ́, kódà láwọn àkókò ìsinmi tá a rìnrìn-àjò kúrò nílé tàbí láwọn àkókò míì tọ́wọ́ wa bá dilẹ̀.
15 min: Ìfẹ́ àti Ìrẹ̀lẹ̀—Àwọn Ànímọ́ Tó Ṣe Kókó Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Àsọyé tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ August 15, 2002, ojú ìwé 18 sí 20, ìpínrọ̀ 13 sí 20.
20 min: “Ẹ Máa Fara Wé Jèhófà Ọlọ́run Wa, ‘Ọlọ́run Aláyọ̀.’ ”b Ní káwọn ará sọ ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa túra ká kí inú wọn sì máa dùn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ́rìí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
Orin 189 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 24
Orin 218
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ August 1 àti Jí! July-September. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, tún ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí akéde lò láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú onílé sọ.
10 min: “Wọ́n Ti Fi Àpẹẹrẹ Ìṣòtítọ́ Lélẹ̀.” Àsọyé tó ní díẹ̀ lára ìrírí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tá a ti tẹ̀ jáde nínú tàbí kó o fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó bá wà nínú ìjọ yín.—Wo ìwé Watch Tower Publications Index lábẹ́ “Special Pioneers.”
20 min: Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin, Ẹ Di Aláìṣeéṣínípò. (1 Kọ́r. 15:58) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu méjì tàbí mẹ́ta lára àwọn akéde tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé tí wọ́n ti sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Báwo ni wọ́n ṣe wá sínú òtítọ́? Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe rí lákòókò tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú ẹ̀? Ìṣòro wo ni wọ́n ti dojú kọ? Ìbùkún wo ni wọ́n ti rí látìgbà tí wọ́n ti ń sin Jèhófà bọ̀?
Orin 12 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 31
Orin 28
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù July sílẹ̀. Mẹ́nu ba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù August.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: “Fi Ohun Tó Dáa Kọ́ra Kó O Lè Rí Ìbùkún Rẹpẹtẹ Gbà.”c Ní káwọn ará sọ bí wọ́n ṣe sapá láti lè ní ìṣètò kan tí wọ́n ń tẹ̀ lé, èyí tó máa mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì sọ ìbùkún tí wọ́n ti rí.
Orin 130 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 7
Orin 209
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní ṣókí, jíròrò bá a ṣe lè mú àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa bá àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mu.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005, ojú ìwé 8.
15 min: Àwọn Ìpàdé Tí Ń Runi Sókè sí Ìfẹ́ àti sí Iṣẹ́ Àtàtà. Àsọyé tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ March 15, 2002, ojú ìwé 24 sí 25. Fi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ṣókí kan kún un nínú èyí tí akéde náà ti máa sọ ìsapá tó ti ṣe láti lè máa lọ sí ìpàdé déédéé kó sì sọ àǹfààní tó ti jẹ látinú ṣíṣe bẹ́ẹ̀.
20 min: Máa Kọ́ni Ní Ṣísẹ̀-Ń-Tẹ̀lé, Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Bá Onírúurú Èèyàn Mu. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ December 1, 2005, ojú ìwé 28 sí 30. Jíròrò ìpínrọ̀ 6 sí 11 bí àsọyé, kó o tẹnu mọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ẹni tó lákìíyèsí, tó mọ bó ṣe yẹ ká bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀, tó sì já fáfá gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Kó o wá ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ 12 sí 14, kí wọ́n sì mú un bá ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn mu. Fi àṣefihàn kan kún un láti fi bí àwọn akéde ṣe lè mú ọ̀rọ̀ wọn bá ẹni tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mu, bí wọ́n ṣe lè kíyè sí ohun táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn nílò, ipò tó yí wọn ká àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́.
Orin 83 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.