ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/06 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 10/06 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 9

Orin 25

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù October sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ October 15 àti Jí! October-December (Lo àbá kẹta fún Jí! October-December.)

15 min: “Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”a Ní kí àwùjọ sọ bí àpẹẹrẹ àwọn ẹlòmíì àti àdúrà àtọkànwá ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n fi ṣèrìbọmi.

15 min: Ìrírí táwọn ará ní. Ní káwọn ará sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bá ẹnì kan pàdé. O lè jẹ́ kí wọ́n ṣe àṣefihàn ìrírí kan tàbí méjì tó tayọ.

Orin 221 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 16

Orin 84

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ látorí àkọlé kékeré tó wà lójú ìwé 70 sí àkọlé kékeré tó wà lójú ìwé 72.

15 min: “Kí Lo Kà sí Pàtàkì Jù?”b Ní kí àwọn akéde tó o ti sọ fún ṣáájú àkókò sọ bí wọ́n ṣe yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn padà kí àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run bàa lè gbawájú nígbèésí ayé wọn, kí wọ́n sì sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n rí látibẹ̀.

Orin 172 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 23

Orin 58

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ November 1 àti Jí! October-December. (Lo àbá kẹrin fún Ji! October-December.) Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn báwọn ará ṣe lè fún ẹni tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lésì, tó wá sọ pé “Èéṣe tí ẹ̀yin ènìyàn yii fi ń wá lemọ́lemọ́?”—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 12.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Tó Kún Rẹ́rẹ́ Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá.”c Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, fi àlàyé kún un látinú Àpótí Ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ 4 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2001, èyí tó dá lórí ohun tó yẹ ní ṣíṣe bí arákùnrin tó tóótun ò bá sí lárọ̀ọ́wọ́tó láti darí ìpàdé náà.

Orin 143 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 30

Orin 207

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù October sílẹ̀.

15 min: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Ọmọ Iléèwé Mi? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí Jí! April 8, 2002 ojú ìwé 28 sí 30. Ní kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí fáwọn ọmọ iléèwé bíi tiwọn.

20 min: Wíwà Láìdá sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú Ayé. Àsọyé tó dá lórí ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà, orí 18, ìpínrọ̀ 6 sí 15. Alàgbà tó tóótun ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí.

Orin 136 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 6

Orin 146

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lo àwọn àbá tó wà lójú ìwé 3 àti 4 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January ọdún 2005 tàbí àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Bí ààyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe ṣàṣeyọrí nígbà tí wọ́n lo ìtẹ̀jáde náà lóde ẹ̀rí tàbí nínú ìdílé wọn.

15 min: Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I. Alàgbà ni kó sọ ọ́ bí àsọyé tó dá lórí Ilé Ìṣọ́, October 15, 2006 ojú ìwé 28 sí 31.

20 min: Wíwàásù Ọ̀rọ̀ Náà Ń Mú Ìtura Wá. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí Ilé Ìṣọ́, January 15, 2002 ojú ìwé 8 àti 9. Ní kí àwùjọ sọ bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe máa ń tù wọ́n lára. O lè ti sọ fún ẹni kan tàbí méjì pé kí wọ́n múra sílẹ̀ ṣáájú.

Orin 8 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́