ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/07 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 1/07 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tó bá ti wà ṣáájú ọdún 1991. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! February 1-18: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! tàbí ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ìjọ. February 19–March 18: Àkànṣe Ìpínkiri ìwé àṣàrò kúkúrú Kingdom News No. 37 tó ní àkọlé náà “Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!” March 19-31: Ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kẹ́ ẹ sì sapá gidigidi kẹ́ ẹ lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la óò lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn títí kan àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ wa mìíràn tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kẹ́ ẹ lè fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February tàbí ó pẹ́ tán ní March 4, àsọyé tuntun fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Ta Ló Máa Wọnú Ayé Tuntun Ọlọ́run?”

◼ Ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan lóṣù April, a óò jíròrò fídíò tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Young People Ask—What Will I Do With My Life? tó sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn ọ̀dọ́ lè fayé wọn ṣe. Bẹ́ ẹ bá fẹ́ fídíò yìí, kẹ́ ẹ béèrè nípasẹ̀ ìjọ yín bó bá ṣe lè yà tó.

◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí ní ọjọ́ Monday, April 2, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Kí ìjọ kọ̀ọ̀kan gbìyànjú láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi tiwọn. Àmọ́, ó lè má ṣeé ṣe bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ni wọ́n ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára wọn lè lọ gba ibòmíràn tí wọn máa lò lálẹ́ ọjọ́ yẹn. A dábàá pé níbi tó bá ti ṣeé ṣe, kó tó ogójì ìṣẹ́jú ó kéré tán lẹ́yìn tí ìjọ kan bá ṣe tán kí ìjọ tó kàn tó bẹ̀rẹ̀, kí gbogbo àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lè ráyè kíra wọn. Ó yẹ ká ronú nípa bí àwọn ọkọ̀ tá a óò gbé wá ò ṣe ní ṣèdíwọ́, ká sì tún ronú nípa ibi tí a óò gbé wọn sí, títí kan jíjá èrò sílẹ̀ àti gbígbé èrò. Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ fún ìjọ wọn.

◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé lẹ́tà tá a fi yan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn (S-202), wà lọ́wọ́. Bí ti aṣáájú-ọ̀nà èyíkéyìí ò bá sí nínú fáìlì ìjọ, kí akọ̀wé kọ lẹ́tà láti béèrè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì.

◼ Àwọn Àwo CD Tuntun Tó Wà:

Mímọrírì Ogún Tẹ̀mí Tá A Ní (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, àwo kan ṣoṣo ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Families—Make Daily Bible Reading Your Way of Life! (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, àwo kan ṣoṣo ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Marked for Survival (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, àwo kan ṣoṣo ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Iwe Itan Bibeli Mi (àwo méjìlá ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí (àwo méjìlá ló wà nínú ẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí (àwo méjìlá ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Warning Examples for Our Day (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, àwo kan ṣoṣo ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

Why Respect Theocratic Arrangements? (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, àwo kan ṣoṣo ló wà nínú ẹ̀)—Faransé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́