Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn August
Av. Av. Av. Av.
Iye: Hrs. Mags. R.V. Bi.St.
Aṣá. Àkàn. 478 125.8 37.9 60.8 13.9
Aṣá. Déédéé 26,858 53.9 16.1 21.3 5.9
Aṣá. Olù. 8,187 48.2 13.1 16.3 4.2
Akéde 250,932 10.7 4.1 4.1 1.3
ÀRÒPỌ̀ 286,455 Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 232
Ìròyìn amóríyá gbáà ni ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn 2006. Iye àwa akéde ti pọ̀ sí i. A ti di ẹgbàá mẹ́tàlélógóje, irínwó ó lé márùnlélógójì [286,455] báyìí! Iye wákàtí tá a fi wàásù pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a lo ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n-lé-nígba àti ẹgbẹ̀rún méjìlá ó dín márùn-ún [4,591,995] wákàtí. A ṣe ìpadàbẹ̀wò tó tíì pọ̀ jù lọ, tí àròpọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìdínláàádọ́rùn-ún àti ẹgbàafà dín ọ̀rìnlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [1,771,420], ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì báwọn èèyàn ṣe jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó dín ẹgbẹ̀rún kan àti márùnlélọ́gọ́fà [518, 875]. Ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ẹni tuntun ló ṣì máa dara pọ̀ mọ́ wa. A dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ń bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.