ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/07 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 29
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 5
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 1/07 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 8

Orin 12

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Gba gbogbo gbòò níyànjú pé kí wọ́n wo fídíò No Blood—Medicine Meets the Challenge ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò tó máa wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ January 22. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ January 15 àti Jí! January–March. (Lo àbá kẹta fún Jí! January–March.) Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn báwọn ará ṣe lè fún ẹni tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lésì, tó wá sọ pé, “Ọwọ́ mi dí.”—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ewé 11.

35 min: “A Máa Mú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Nàìjíríà Gbòòrò sí I.”a

Orin 53 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 15

Orin 93

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù January sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: Wàásù Ìhìn Rere fún Gbogbo Èèyàn. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 92 sí àkọlé kékeré tó wà lójú ìwé 102.

20 min: “‘Èmi Kò Nífẹ̀ẹ́ sí I.’”b Bó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí àwùjọ sọ ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ lọ́kàn. Ṣe àṣefihàn méjì ṣókí nípa ohun tá a lè sọ fún àwọn tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa tí wọ́n wá sọ pé, “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí i.”—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 8.

Orin 135 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 22

Orin 224

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ February 1 àti Jí! January–March. (Lo àbá kẹrin fún Jí! January–March.) Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, fi hàn bá a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tó máa ń gba ìwé ìròyìn lọ́wọ́ wa déédéé.

10 min: Ṣé Nǹkan Kan Ń Dí Ẹ Lọ́wọ́ Ni? Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Kó gbé e karí Ilé Ìṣọ́ April 1, 2002, ojú ìwé 13 sí 15.

25 min: “Irú Ìtọ́jú Ìṣègùn Wo Ló Dára Jù?” Alàgbà ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Ní tààràtà ni kó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó dá lórí fídíò No Blood, àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà ni kó o lò. Mú ìjíròrò náà wá síparí nípa kíka ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn kó o sì gba àwùjọ níyànjú láti fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ tá a fà yọ.

Orin 188 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 29

Orin 55

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù January sílẹ̀. Mẹ́nu ba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò ní oṣù February, kó o sì ṣe àṣefihàn kan nípa bá a ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀.

10 min: Bó O Bá Ṣàdéhùn Pé Wàá Padà Lọ, Má Ṣaláì Lọ. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ September 15, 1999, ojú ìwé 11. Ní kí àwùjọ sọ ìrírí wọn nípa àǹfààní tí wọ́n ti rí nígbà tí wọ́n ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tí wọ́n bá ṣàdéhùn.

25 min: “Àkànṣe Ìgbòkègbodò Tá A Ó Ṣe Láàárín February 19 sí March 18!” Kí alàgbà kan fi ìtara jíròrò àpilẹ̀kọ yìí. Lẹ́yìn tó o bá ti ka ìfilọ̀ tó wà nínú lẹ́tà tá a kọ sí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ní June 6, 2006, fún àwọn tó wà ní ìpàdé ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé àṣàrò kúkúrú Kingdom News No. 37. Kó o wá jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ètò tí ìjọ ti ṣe tẹ́ ó fi lè kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Gba gbogbo akéde níyànjú kí wọ́n bàa lè lọ́wọ́ sí ìpínkiri yìí. Ṣe àṣefihàn ṣókí.

Orin 50 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 5

Orin 3

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: Àǹfààní Tá A Lè Rí Jẹ́ Látinú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ti ọdún 2007. Ṣàlàyé ìdí tó fi pọn dandan pé kí gbogbo wa máa ya ìṣẹ́jú mélòó kan sọ́tọ̀ lóòjọ́ láti fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́. Sọ pé kí ẹnì kan tàbí méjì ti múra àlàyé sílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́, kí wọ́n sì sọ àǹfààní tí wọ́n ti jẹ látibẹ̀. Fi àlàyé ráńpẹ́ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2007 parí ẹ̀.

20 min: “Ìfẹ́ Ṣe Kókó Bí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Bá Máa Yọrí sí Rere.”c Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2003, ojú ìwé 23, ìpínrọ̀ 16 àti 17.

Orin 83 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́