Irú Ìtọ́jú Ìṣègùn Wo Ló Dára Jù?
Dókítà Michael Rose, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà nínú ìmọ̀ ìṣègùn tó sì tún jẹ́ onímọ̀ nípa ohun tí kì í jẹ́ kí aláìsàn mọ ìrora sọ pé: “Bá a bá máa sọ pé aláìsàn kan rí ìtọ́jú ìṣègùn tó dara jù gbà, a jẹ́ pé wọ́n ti ní láti tọ́jú aláìsàn náà láìlo ẹ̀jẹ̀.” Kí làwọn ìlànà táwọn oníṣègùn ń tẹ̀ lé nígbà tí wọ́n bá ń ṣe “iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀,” àwọn nǹkan wo ni wọ́n sì máa ń lò dípò ẹ̀jẹ̀? Ó pọn dandan pé kó o mọ àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kó o bàa lè ṣèpinnu tó dá ẹ lójú nípa ìtọ́jú ìṣègùn tó o fẹ́ gbà tàbí nípa iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fẹ́ ṣe fún ẹ. Wo fídíò náà No Blood—Medicine Meets the Challenge. Bó o bá ti wò ó tán, kó o fi àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí dánra wò.—Àkíyèsí: Nítorí pé fídíò náà láwọn ibì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti fi iṣẹ́ abẹ hàn ní ṣókí, káwọn òbí lo ìfòyemọ̀ láti pinnu bóyá káwọn ọmọ wọn kéékèèké wò ó.
(1) Kí ni olórí ìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀? (2) Bó bá dọ̀rọ̀ ìtọ́jú ìlera, kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́? (3) Ẹ̀tọ́ wo ni aláìsàn ní? (4) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé dípò kéèyàn gba ẹ̀jẹ̀, kó gba ohun tí wọ́n ń lò dípò ẹ̀jẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe fi hàn pé èèyàn ò fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ọ̀ràn ìlera ẹ̀? (5) Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀jẹ̀ ń dà lára aláìsàn láìdáwọ́ dúró, nǹkan méjì wo ní àwọn dókítà gbọ́dọ̀ ṣe ní kíákíá? (6) Ìlànà mẹ́rin wo ni wọ́n ní láti tẹ̀ lé bó bá di pé wọ́n fẹ́ fún aláìsàn ní ohun téèyàn lè lò dípò ẹ̀jẹ̀? (7) Ọ̀nà wo làwọn dókítà lè gbà ṣe é (a) tí ẹ̀jẹ̀ tó máa dà lára aláìsàn ò fi ní pọ̀ jù, (b) tí wọ́n á fi lè rí i pé sẹ́ẹ̀lì pupa ò ṣòfò, (d) tí ẹ̀jẹ̀ tára ń mú jáde á fi pọ̀ sí i, (e) tí ẹ̀jẹ̀ ara aláìsàn a fi tó padà? (8) Ṣàlàyé ọ̀nà táwọn dókítà lè gbà fi ẹ̀jẹ̀ rẹ tọ́jú rẹ, bíi (a) dída oògùn pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ àti (b) fífi ẹ̀rọ gbe ẹ̀jẹ̀. (9) Kí lo yẹ kó o mọ̀ nípa ohunkóhun tó bá ṣeé lò dípò ẹ̀jẹ̀? (10) Ṣé iṣẹ́ abẹ tó gbẹgẹ́ tó sì díjú ṣeé ṣe láìjẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ síni lára? (11) Ohun tó dáa wo ló ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn oníṣègùn báyìí?
Bí ẹnì kan bá máa yan èyíkéyìí lára àwọn ọ̀nà ìtọ́jú tá a fi hàn nínú fídíò yìí, ìyẹn á jẹ́ ìpinnu ara rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́. Ṣó o ti pinnu èyí tí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ máa yàn lára àwọn nǹkan tí wọ́n lè lò dípò fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára? Rí i pé o jẹ́ káwọn ẹbí rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí mọ̀ sí ìpinnu tó o bá ṣe kó o sì sọ ohun tó sún ọ ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ fún wọn.—Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004 àti October 15, 2000.