A Máa Mú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa ní Nàìjíríà Gbòòrò sí I
1. Ṣàlàyé ráńpẹ́ nípa bí iṣẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí Bẹ́tẹ́lì wa ní Igieduma.
1 Lọ́dún 1984 la bẹ̀rẹ̀ sí í mọ odi yíká Bẹ́tẹ́lì wa ní Igieduma. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, ní January 20, ọdún 1990, a ya Bẹ́tẹ́lì tuntun náà sí mímọ́. Ó dájú pé gbogbo wa ni inú wa dùn lọ́jọ́ mánigbàgbé yẹn. Bá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ètò Ọlọ́run ti gbé ṣe lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìṣẹ̀lẹ̀ tí ò lè pa rẹ́ láé ni ìyàsímímọ́ Bẹ́tẹ́lì yẹn! Irínwó [400] èèyàn ni ilé gbígbé tá a kọ́ síbẹ̀ lè gbà, èyí tó fi ohun tó lé ní ìlọ́po méjì ju ilẹ̀ tá a kọ́ Bẹ́tẹ́lì wa àtijọ́ sí ní Ṣómólú, nílùú Èkó.
2. Àwọn wo ló ti ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Igieduma látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ?
2 Látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Igieduma, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará ní wọ́n ti wá ṣèbẹ̀wò. Ọ̀pọ̀ lára yín lẹ ti wá fojú ara yín rí bí àwọn ilé tá a kọ́ náà ṣe dáa tó. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà títí kan àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan máa ń ṣèbẹ̀wò lóòrèkóòrè sí ọgbà ẹlẹ́wà yìí láti wá wo àwọn ilé tá a kọ́ síbẹ̀. Tayọ̀tayọ̀ la sì máa fi ń gbà wọ́n lálejò.
3. Ọ̀nà wo ni ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ti gbà gbòòrò sí i látọdún 1990 wá?
3 Ńṣe ni iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀ látọdún 1990 yẹn wá. Bá a ṣe ń bójú tó iṣẹ́ náà lọ́nà tó dáa jù kò ṣẹ̀yìn ilé àtàwọn ohun èlò tó pójú owó tá à ń lò ní Bẹ́tẹ́lì. Bí iṣẹ́ náà sì ṣe ń dáa sí i ló túbọ̀ ń pọn dandan pé kí ilé àtàwọn ohun èlò náà pọ̀ sí i. Nígbà tá a ya Bẹ́tẹ́lì sí mímọ́ lọ́dún 1990, àròpọ̀ akéde ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógóje ó lé àádọ́jọ [139,150] ló ròyìn. Mélòó wá ni wá lónìí? A ti di ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá, ẹgbàáta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dín márùnlélógójì [286,455] báyìí, iye yìí sì ju ìlọ́po méjì akéde tó ròyìn lọ́dún yẹn lọ! Ká bàa lè bójú tó àwọn akéde tó ń pọ̀ sí i làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ sí i. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwa tá à ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì fi ọgbọ̀n dín sí ẹgbẹ̀ta [570]. Lásìkò tí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò bá sì ń lọ lọ́wọ́, a máa ń lé ní ẹgbẹ̀ta [600]. Ẹ má ṣe gbàgbé pé irinwó [400] èèyàn péré la kọ́ Bẹ́tẹ́lì tuntun tá à ń lò báyìí fún. Pẹ̀lú bí nǹkan ṣe rí yìí, ẹ lè rí i pé Bẹ́tẹ́lì wa ti kún fọ́fọ́.
4, 5. Àwọn ibi ìjọsìn mìíràn wo la tún ti kọ́ látọdún 1990 wá?
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ kíkọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí parí lọ́dún 1990, a ò ṣíwọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Kò pẹ́ sígbà yẹn la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó rẹwà tó sì fẹ̀ sí onírúurú ibi lórílẹ̀-èdè yìí. Lára àwọn ibi tá a kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà sí ni Àkúrẹ́, Dálùwọ́n, Enugu, Ìbàdàn, Igurúta Àlì, Mgboko Umuoria, Ọ̀tà, Ùbogò àti Ùlì.
5 Lẹ́yìn èyí niṣẹ́ kan kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ò kéré jù bẹ́ẹ̀ ni wọn ò tóbi ràgàjì. A kọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ilé ìjọsìn tó bójú mu tó sì jojú ní gbèsè. A pín àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí àwùjọ kéékèèké, gbogbo wọn sì jẹ́ ọgbọ̀n. Ọ̀kan lára àwọn àwùjọ kéékèèké náà máa ń ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwọn ará. Nígbà tí oṣù August ọdún 2006 ń parí lọ, a parí iṣẹ́ lórí Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó jẹ́ ẹgbẹ̀jọ dín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [1,574], a sì ya gbogbo wọn sí mímọ́! Àwọn ìjọ tó jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi ṣe ìpàdé nínú àwọn ilé ẹgẹrẹmìtì, àwọn ilé tí wọ́n yá lò fúngbà díẹ̀ tàbí nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọn ò tíì kọ́ parí ti wá dẹni tó ń ṣèpàdé nínú àwọn ilé rèǹtèrente tó dùn-ún wò gẹ́gẹ́ bí ibi ìjọsìn tòótọ́ ládùúgbò èyíkéyìí tí wọ́n bá kọ́ ọ sí báyìí. Àwọn ìjọ tó ń lo àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí láyọ̀ gidigidi, ẹnu wọn ò sì gbọpẹ́ nítorí ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn! Ó máa ń lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń kọ́ lọ́dọọdún, síbẹ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó kù ká kọ́ lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900].
6. Kí ló jẹ́ tuntun nínú ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí?
6 Láàárín ọdún mẹ́ta tó kọjá, bá a ṣe ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tuntun káàkiri orílẹ̀-èdè yìí. A ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tuntun tó dín ìnáwó kù. Lára àwọn ìlú tá a ti kọ́ irú Gbọ̀ngàn Àpéjọ bẹ́ẹ̀ sí ni Agbor, Awi (nítòsí Kàlàba) àti ní Benin City. Bí àwọn kan lára àwọn àwùjọ kéékèèké yìí ṣe ń parí iṣẹ́ lára Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tá a ti pa tì látọjọ́ tó pẹ́ làwọn míì nínú wọn ń dáwọ́ lé kíkọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tuntun. Lọ́dún tó kọjá, wọ́n parí àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tá a ti pa tì bẹ́ẹ̀, bí irú èyí tó wà nílùú Àkúrẹ́, Igurúta Àlì àti Iléṣà.
7. (a) Báwo ni àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tó Ṣeé Lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ ṣe máa ń rí? (b) Látìgbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ti bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, irú àwọn gbọ̀ngàn bẹ́ẹ̀ mélòó la ti kọ́, ibo la sì kọ́ wọn sí?
7 A tún ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tó Ṣeé Lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ. A ti kọ́ irú àwọn gbọ̀ngàn bẹ́ẹ̀ sáwọn ìlú Akaeze Ukwu, Amassoma, Bori, Ikot Akan, Ìlọrin, Jos, Kàbà, Kàdúná, Katsina Ala, Makurdi, Numan, Obehie Asa àti Zaria. Dípò kí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń sọ yìí ní ògiri lẹ́yìn, ìlẹ̀kùn kan tó fẹ́ gan-an la fi dá a sí méjì láàárín. Ìlẹ̀kùn yìí máa ń ṣeé ṣí, apá ibi tá à ń lò bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba á sì já pọ̀ mọ́ àyè tó wà lẹ́yìn tó lè gba ẹgbẹ̀ta tàbí ẹgbàafà èèyàn nígbà àpéjọ àyíká, àkànṣe àti nígbà àpéjọ àgbègbè. A kọ́ irú àwọn gbọ̀ngàn yìí káàkiri àwọn ìlú táwọn akéde ò ti pọ̀ tó láti ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Àwọn ìjọ máa ń ṣèpàdé nínú apá tó ṣeé lò bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba jálẹ̀ ọdún. Bí àpéjọ àyíká, àpéjọ àkànṣe tàbí àpéjọ àgbègbè bá sì tó, ẹnu kí wọ́n ṣí ilẹ̀kùn tó wà láàárín kí gbogbo gbọ̀ngàn náà lè já pọ̀ mọ́ra ni.
8. Báwo ni kálukú wa ṣe lè ti iṣẹ́ ìkọ́lé ńlá tó ń lọ ní orílẹ̀-èdè yìí lẹ́yìn?
8 Ẹ lè wá rí i pé owó ribiribi là ń ná lórí iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè yìí. A mọrírì ọrẹ tẹ́yin ará máa ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ìtìlẹ́yìn yín fún iṣẹ́ kárí ayé, èyí tó ń jẹ́ ká lè máa rí owó látọ̀dọ̀ yín fún àbójútó iṣẹ́ ńlá yìí. Gbogbo ìgbà làwọn ará wa látòkè òkun máa ń ràn wá lọ́wọ́, ṣùgbọ́n níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará wa kárí ayé ni wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ báyìí, ìwọ̀nba ni owó tá a lè retí láti òkè òkun o. Nítorí náà, ẹ jẹ́ káwa náà ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lórílẹ̀-èdè yìí láti ti iṣẹ́ yìí lẹ́yìn?
9. (a) Ìròyìn amọ́kànyọ̀ wo la rí nínú ìpínrọ̀ yìí? (b) Ibo la ti kọ́kọ́ múṣẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé ibẹ̀ la ti bẹ̀rẹ̀? (d) Ibo ni ọ́fíìsì tuntun náà wà nílùú Èkó, irú àwọn ilé wo la sì máa kọ́ síbẹ̀?
9 Ní báyìí, ìdùnnú ti ṣubú lu ayọ̀ fún wa o! Inú yín á dùn láti gbọ́ pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti fọwọ́ sí i pé ká kọ́ àwọn ilé mìíràn kún èyí tá à ń lò ní Bẹ́tẹ́lì nítorí bá a ṣe nílò ilé púpọ̀ sí i lójú méjèèjì ní Bẹ́tẹ́lì wa lórílẹ̀-èdè yìí. Iṣẹ́ ìkọ́lé náà sì ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún tó kọjá. Ọ́fíìsì tí Èkó la ti kọ́kọ́ múṣẹ́ ṣe níbẹ̀rẹ̀ ọdún tó kọjá. Èyí yẹ bẹ́ẹ̀ nítorí pé ọ́fíìsì ti Èkó kéré púpọ̀ jù fún iṣẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tá à ń ṣe níbẹ̀. A rí àtìlẹ́yìn Jèhófà nínú bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ tá a fi rí ilẹ̀ tó dáa rà, ilẹ̀ náà sì tóbi dáadáa láti gba àwọn ilé tá a máa kọ́ sórí ẹ̀. Ilẹ̀ náà wà lẹ́bàá ọ̀nà tó lọ sí Àdúgbò Mobọ́lájí Johnson nítòsí Ọ́fíìsì Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó, èyí tó dojú kọ títì márosẹ̀ Ìbàdàn, kò sì fi bẹ́ẹ̀ jìnnà síbi tí wọ́n ti ń gbowó ojú ọ̀nà látijọ́ níbi àbáwọlé sílùú Èkó. Ilé náà máa ní ibi ìkẹ́rùsí tí wọ́n kọ́ pa pọ̀ mọ́ ọ́fíìsì tá a ó ti máa bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì àti ilé gbígbé tó máa gbà tó òṣìṣẹ́ méjìdínláàádọ́ta. Àjà mẹ́ta ni ilé gbígbé náà máa ní. Iléeṣẹ́ agbalékọ́ kan lórílẹ̀-èdè yìí la gbé iṣẹ́ náà fún. Iṣẹ́ ti ń lọ ní pẹrẹu, ó sì yẹ kí ilé iṣẹ́ agbalékọ́ náà parí ẹ̀ ní August 1, 2007. Àwòrán ibi tí wọ́n bá àwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ náà dé wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àwòrán àfọwọ́yà nípa bí ilé náà ṣe máa rí bí wọ́n bá kọ́ ọ tán tún wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ńṣe lẹ ò ní bínú pé a ò jẹ́ kẹ́ ẹ wá máa wo bí iṣẹ́ ṣe ń lọ sí, ìdí sì ni pé ilé iṣẹ́ agbalékọ́ la gbé e fún.
10. (a) Báwo ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ti Igieduma ṣe máa rí bí wọ́n bá kọ́ ọ tán? (b) Ta ló máa bójú tó iṣẹ́ náà, kí sì nìdí tá a fi lè sọ pé iṣẹ́ ńlá gbáà ni?
10 Kó tó di pé ilé ti Èkó yìí parí pátápátá, à ń fojú sọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé ti ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Igieduma. Báwo wá ni ti Igieduma ṣe máa rí o? Àwọn ilé gbígbé àtàwọn ọ́fíìsì tá a máa kọ́ sí Igieduma á ju ìlọ́po méjì ilé gbígbé àtàwọn ọ́fíìsì tá à ń lò lọ́wọ́ báyìí lọ! Iṣẹ́ ti ń lọ ní pẹrẹu lórí àwọn ohun tó gbọ́dọ̀ wà ní sẹpẹ́ tí iṣẹ́ náà bá máa ṣeé ṣe. Àwọn Òṣìṣẹ́ Káyé ti dé, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ àbójútó tó yẹ lórí iṣẹ́ méjèèjì náà, síbẹ̀ àwọn míì máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í dé. Ilé gbígbé tá a kọ́kọ́ máa kọ́ síbẹ̀ pa pọ̀ mọ́ àwọn ilé gbígbé tá à ń lò lọ́wọ́ á gba àádọ́ta lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [750] èèyàn, nígbà tá a bá sì kọ́ ti ìpele kejì tán, àròpọ̀ gbogbo òṣìṣẹ́ táá máa gbébẹ̀ pa pọ̀ mọ́ àwọn táá máa gbé inú ti tẹ́lẹ̀ á jẹ́ ẹgbẹ̀rún [1,000] kan. Iṣẹ́ ńlá gbáà lèyí á mà jẹ́ o!
11. (a) Nǹkan mìíràn wo la tún máa ṣe tó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́lé náà? (b) Ta ló máa ṣe iṣẹ́ náà?
11 Ilé tá a máa gbé ẹ̀rọ amúnáwá tuntun sí la máa kọ́kọ́ kọ́, ẹ̀rọ amúnáwá tuntun ràgàjì náà á máa pèsè iná tí agbára rẹ̀ jẹ́ ìlọ́po méjì èyí tá à ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́. Iṣẹ́ ìkọ́lé náà máa ní nínú kíkọ́ àwọn ilé ńláńlá tuntun mẹ́rin àtàwọn ilé tá a ó ti máa bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì títí kan ilé ìfọṣọ kan, ilé ìgbọ́únjẹ kan àti ilé ìjẹun kan tó máa gba èèyàn ẹgbẹ̀rún [1,000] kan. A máa kọ́ ilé mìíràn mọ́ ara ọ́fíìsì tá a ti ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù wa ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, èyí tó máa mú kó tóbi sí i ní ìlọ́po méjì. Lẹ́yìn náà, a ó wàá sọ ilé tá a ti ń bójú tó àwọn ohun tó jẹ́ ti ìdílé Bẹ́tẹ́lì báyìí di ilé tá a ó ti máa ṣe àtúnṣe gbogbo ohun tá à ń lò. Àwọn ilé mìíràn tí àtúnṣe máa bá ni ilé tá a ti ń bójú tó ìwé títẹ̀, ọ́fíìsì tá a ti ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè yìí, ibi tá a ti ń bójú tó Iṣẹ́ Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, yàrá tá à ń lò fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ àti ibi tá a ti ń tọ́jú àwọn tó bá ń ṣòjòjò. A máa la àwọn ọ̀nà tuntun. A sì máa tún bi ilẹ̀ ibẹ̀ ṣe rí ṣe kó bàa lè dami nù dáadáa. Ẹ ò rí i pé tẹ̀gàn ni ẹ̀, iṣẹ́ ńlá ló wà níwájú wa! Ní báyìí ná, a ò tíì lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ bóyá àwa la máa bójú tó iṣẹ́ náà tá a kàn máa ní kí ilé iṣẹ́ agbalékọ́ ṣe èyí tó pọ̀ nínú ẹ̀ tàbí ńṣe la kúkú máa gbé iṣẹ́ náà fún ilé iṣẹ́ agbalékọ́ bá a ṣe ṣe ti ọ́fíìsì Èkó. Èyíwù ó jẹ́, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó ni iṣẹ́ náà máa ná wa. Ó máa pọn dandan pé ká nílò ìrànwọ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tó mọ̀ nípa ilé kíkọ́ lórílẹ̀-èdè yìí, bí àkókò bá sì ti tó, a óò jẹ́ kẹ́ ẹ gbọ́.
12, 13. (a) Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé bàǹtàbanta tá a ti dáwọ́ lé yìí, kí là ń retí lọ́dọ̀ kálukú wa? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ṣiyè méjì nígbà tá a bá fẹ́ fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé?
12 Ta ló máa san gbogbo owó tá a máa fi ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé yìí, títí kan kíkọ́ ọ́fíìsì tuntun sí Èkó, kíkọ́ kún ilé tá à ń lò ní Bẹ́tẹ́lì ti Igieduma, kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tó Ṣée Lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ? À ń fi àsìkò yìí rọ gbogbo ẹ̀yin ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà ní Nàìjíríà láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́lé yìí nípasẹ̀ ọrẹ àtinúwá fún iṣẹ́ kárí ayé.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ ẹ ṣe mọ̀, lọ́dọọdún ni èlò ìkọ́lé ń wọ́nwó sí i. Ká tó lè parí iṣẹ́ ìkọ́lé bàǹtàbanta yìí, ó máa pọn dandan pé kẹ́ ẹ fi owó ṣètìlẹ́yìn o. Nítorí náà, a ó mọrírì ìtìlẹ́yìn yín gidigidi.
13 Àwọn ará wa ṣe bẹbẹ lásìkò tá à ń kọ́ ilé Igieduma yìí nígbà náà lọ́hùn-ún. Kí la wá lè ṣe báyìí? Ọrẹ àfínnúfíndọ̀ ṣe tí kálukú wa bá fi ṣètìlẹ́yìn nìkan la máa fi ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Fún ìdí yìí, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa ká lè rówó tó tówó ṣe àtìlẹ́yìn. Kì í ṣohun tuntun láti máa fi ohun èlò àti owó ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn mímọ́. Ohun tó sì máa ń fúnni láyọ̀ ni. (1 Kíró. 29:9; 2 Kọ́r. 9:7-11) Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé a ó lo iyekíye yòówù tẹ́ ẹ bá fi ránṣẹ́ lọ́nà tó tọ́. Irú owó bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, a ó sì mọrírì rẹ̀.—Máàkù 12:41-44; 14:3-8.
14. Ìdánilójú wo la ní?
14 Ǹjẹ́ apá àwa ará Nàìjíríà máa ká iṣẹ́ bàǹtàbanta tó wà níwájú wa yìí? Iṣẹ́ Jèhófà lèyí. Kì í ṣe ti ẹnikẹ́ni. Òun fúnra rẹ̀ sì ti mú un dá wa lójú nínú Sáàmù 127:1 pé: “Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.” Pẹ̀lú ìlérí tí Jèhófà ṣe láti tì wá lẹ́yìn yìí, ó dá wa lójú pé àwọn ilé tuntun tá a fẹ́ kọ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa yìí á kẹ́sẹ járí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwòrán àfọwọ́yà nípa bí ọ́fíìsì tuntun tá à ń kọ́ sí Èkó ṣe máa rí bí wọ́n bá kọ́ ọ tán
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ilé gbígbé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ilé ìkẹ́rùsí àtàwọn ọ́fíìsì