Ìfẹ́ Ṣe Kókó Bí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Bá Máa Yọrí sí Rere
1 “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì tù yín lára.” (Mát. 11:28) Ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn ṣe jinlẹ̀ tó. Ó máa ń wu àwa tá a jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run láti máa ṣe bíi ti Jésù nípa nínífẹ̀ẹ́ àwọn tí ọ̀rọ̀ ilé ayé ti sú nítorí pé kò sí ìfẹ́. Àmọ́, báwo la ṣe lè máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí?
2 Nínú Ọ̀rọ̀: Ìfẹ́ tí Jésù ní sáwọn èèyàn ló mú kó máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn ní gbogbo ìgbà tí àyè bá ti ṣí sílẹ̀. (Jòh. 4:7-14) Táwa náà bá ní ìfẹ́, a ò ní máa lọ́ra láti wàásù níbikíbi tá a bá ti bá àwọn èèyàn pàdé. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́fà kan wàásù lọ́nà tó múná dóko fún obìnrin kan tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń dúró dé dókítà nílé ìwòsàn. Kí ló mú kí ọmọdé yìí wàásù fóbìnrin yẹn? Ó sọ pé, “Bí mo ṣe rí obìnrin náà, mo wò ó pé ó yẹ kó gbọ́ nípa Jèhófà.”
3 Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ká bá wọn sọ̀rọ̀ tọkàntọkàn, pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́, ká sì bá wọn sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́. Ọ̀nà míì ni pé ká fetí sóhun tí wọ́n fẹ́ sọ, ká mọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn jẹ wá lógún. (Òwe 15:23) Bíi ti Jésù, àwọn ohun tó ń fúnni níṣìírí nípa Ìjọba Ọlọ́run àti nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ oníyọ̀ọ́nú sáwọn èèyàn ni ká máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ.—Mát. 24:14; Lúùkù 4:18.
4 Nínú Ìṣe: Tí Jésù bá rí i pé àwọn kan nílò ìrànlọ́wọ́, ó máa ń tètè ṣe é fún wọn. (Mát. 15:32) Nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, àwa pẹ̀lú lè bá ipò tá a ti lè ṣoore fáwọn èèyàn pàdé. Lọ́jọ́ kan, arábìnrin wa kan kíyè sí obìnrin kan pé ọ̀rọ̀ pàtàkì tí wọ́n ń bá a sọ lórí tẹlifóònù kò fi bẹ́ẹ̀ yé e. Ní arábìnrin wa yìí bá yọ̀ọ̀da ara ẹ̀ láti ṣe ògbufọ̀ fún obìnrin náà. Oore tí arábìnrin yìí ṣe lọ́jọ́ náà mú kí obìnrin náà gbọ́ ìwàásù, ó sì tún gbà pé kí wọ́n máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti arákùnrin wa kan tó lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọkùnrin kan. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i tí ọkùnrin náà ń bínú síra ẹ̀ nítorí pé àga ìrọ̀gbọ̀kú tó fẹ́ gbé wọlé há mọ́ ẹnu ọ̀nà. Ni arákùnrin yìí bá ràn án lọ́wọ́ láti gbé àga náà wọlé, ọkùnrin náà sì mọrírì oore yẹn gan-an. Kódà, orí àga yẹn gan-an ni arákùnrin yìí jókòó lé nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọkùnrin náà.
5 Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa. (Mát. 22:36-40) Ìfẹ́ tá a sì ń fi hàn lọ́rọ̀ àti níṣe yìí ń mú káwọn tó fẹ́ láti mọ òtítọ́ rí i pé àwa là ń ṣe ìsìn tòótọ́.