ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/07 ojú ìwé 1
  • “Èmi Kò Nífẹ̀ẹ́ sí I”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Èmi Kò Nífẹ̀ẹ́ sí I”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Hùwà Pa Dà sí Ẹ̀mí Ìdágunlá?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Mímú Ọ̀rọ̀ Rẹ Bá Ipò Wọn Mu
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Bí A Ṣe Lè Máa Bá a Lọ Ní Jíjẹ́ Aláyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Bá A Ṣe Lè Borí Ìṣòro Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwáàsù Ilé-dé-Ilé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 1/07 ojú ìwé 1

“Èmi Kò Nífẹ̀ẹ́ sí I”

1 Láwọn ibì kan, ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn sábà máa ń fi pàdé wa nígbà tá a bá fẹ́ wàásù fún wọn nìyẹn. Kí ni ò ní jẹ́ ká bọkàn jẹ́ nígbà táwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù? Kí la lè ṣe tí wọ́n á fi fẹ́ láti gbọ́?

2 Ayọ̀ Ṣe Pàtàkì: Tá a bá ń rántí ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi fẹ́ máa gbọ́ ìwàásù, a ò ní jẹ́ kíyẹn bayọ̀ wa jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan wa tó jẹ́ pé wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sọ pé ara ẹranko làwa èèyàn ti wá kọ́ wọn, nígbà táwọn míì dàgbà lágbègbè táwọn èèyàn ò ti gbà pé Ọlọ́run wà. Irú àwọn èèyàn báwọ̀nyí lè má mọ bí Bíbélì ṣe wúlò tó. Ìwà àgàbàgebè tó kúnnú ẹ̀sìn sì ti lè mú kí gbogbo nǹkan tojú sú àwọn míì. Ohun tó fà á táwọn kan ò fi fẹ́ máa gbọ́ ìwàásù ni bí gbogbo nǹkan ṣe tojú sú wọn àti rírò tí wọ́n ń rò pé kò sọ́nà àbáyọ. (Éfé. 2:12) Àwọn míì ò sì “fiyè sí” ìhìn rere nítorí pé àníyàn ìgbésí ayé ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn.—Mát. 24:37-39.

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ò fẹ́ máa gbọ́rọ̀ wa, a ṣì lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tá à ń ṣe ń gbé Jèhófà ga. (1 Pét. 4:11) Yàtọ̀ síyẹn, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i tá a bá ń sọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, títí kan àwọn tí ò tiẹ̀ mọyì rẹ̀ nísinsìnyí. Ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn ni káwa náà máa fi wo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Jèhófà káàánú àwọn ará Nínéfè “tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn.” (Jónà 4:11) Ó di dandan pé káwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run! Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kó sú wa, dípò ìyẹn ẹ jẹ́ ká wá ọ̀nà tá a lè gbà mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì.

4 Bá Wọn Jíròrò Ohun Tó Ń Jẹ Wọ́n Lọ́kàn: Tó o bá wà lóde ẹ̀rí, o lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ nípa sísọ ohun kan tó ń jẹ àwọn tó ń gbé lágbègbè yẹn lọ́kàn, kó o sì ní kẹ́ni tó o fẹ́ wàásù fún sọ èrò tirẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. Fetí sóhun tó bá ń sọ, lẹ́yìn náà, fi ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Bíbélì sọ nípa ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn hàn án. Arákùnrin kan tó jáde òde ẹ̀rí lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan wáyé lágbègbè rẹ̀ sọ pé ní gbogbo ilé tóun ti wàásù, òun jẹ́ káwọn èèyàn ibẹ̀ mọ̀ pé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ náà dun òun gan-an. Ó ní: “Àfìgbà táwọn èèyàn tí kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù tẹ́lẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í dá sí ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni mo wàásù fún lọ́jọ́ náà nítorí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn jẹ mí lógún.”

5 Gbogbo ìṣòro tó ń pọ́n aráyé lójú ni Ìjọba Ọlọ́run máa mú kúrò láìku ẹyọ kan. Gbìyànjú láti fòye mọ ìṣòro tẹ́ni tó ò ń wàásù fún ń bá yí. Ó ṣeé ṣe kó gbà ọ́ láyè láti sọ ọ̀rọ̀ ìrètí tó wà nínú Bíbélì fóun. Tí ò bá sì gbà ọ́ láyè, ó ṣeé ṣe kó ṣe bẹ́ẹ̀ “àní ní ìgbà mìíràn.”—Ìṣe 17:32.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́