ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/97 ojú ìwé 1
  • Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Hùwà Pa Dà sí Ẹ̀mí Ìdágunlá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Hùwà Pa Dà sí Ẹ̀mí Ìdágunlá?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Èmi Kò Nífẹ̀ẹ́ sí I”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Bí A Ṣe Lè Máa Bá a Lọ Ní Jíjẹ́ Aláyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Pa Dà Ṣiṣẹ́ Lórí Ọkàn Ìfẹ́ Nínú Ìròyìn Ìjọba
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 10/97 ojú ìwé 1

Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Hùwà Pa Dà sí Ẹ̀mí Ìdágunlá?

1 Ẹ̀mí ìdágunlá jẹ́ ṣíṣàìní ìmọ̀lára tàbí èrò ìmọ̀lára, àìní ọkàn ìfẹ́ tàbí àníyàn. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìṣarasíhùwà tí ó wọ́pọ̀ jù tí ó sì ṣòro jù tí a ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Báwo ni ìwọ ṣe ń hùwà pa dà sí i? Ó ha ti mú kí o dẹwọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ bí? Báwo ni o ṣe lè ṣẹ́pá rẹ̀ kí o baà lè mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn?

2 Lákọ̀ọ́kọ́, mọ ìdí tí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ fi jẹ́ ẹlẹ́mìí ìdágunlá. Ó ha jẹ́ nítorí pé àwọn aṣáájú òṣèlú àti ti ìsìn wọn ti já wọn kulẹ̀ bí? Wọ́n ha nímọ̀lára pé kò sí ọ̀nà àbájáde kankan kúrò nínú àwọn ìṣòro tí ń dojú kọ wọ́n bí? Wọ́n ha ń ṣiyè méjì nípa àwọn ìlérí ohun tí ó sàn jù bí? Wọ́n ha ń lọ́ tìkọ̀ láti ronú nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí àyàfi bí wọ́n bá lè rí àwọn àǹfààní ojú ẹsẹ̀ tí a lè fojú rí bí?

3 Tẹnu Mọ́ Ìrètí Ìjọba Náà: Kò sí ìṣòro kankan tí Ìjọba náà kì yóò yanjú. Nítorí náà, nígbà tí a bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí Ìjọba, ní títọ́ka sí àwọn gbólóhùn ṣíṣe kókó inú Ìwé Mímọ́, àní bí kò bá tilẹ̀ ṣeé ṣe tàbí gbéṣẹ́ láti fi ẹsẹ Bíbélì kan hàn. (Héb. 4:12) Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè mú ìjíròrò náà dé orí kókó yẹn?

4 Ó yẹ kí àwọn ènìyàn lóye ète ìkésíni wa. Ó yẹ kí wọ́n mọ̀ pé wíwá tí a wá jẹ́ nítorí ìfẹ́ aládùúgbò àti àníyàn fún àwọn aládùúgbò. A lè béèrè ìbéèrè kan tí a ti ronú jinlẹ̀ nípa rẹ̀ dáadáa irú bíi, “Kí ni o rò pé ó jẹ́ ojútùú sí [ìṣòro kan tí ń ṣẹlẹ̀ ní àdúgbò náà]?” Bí ọ̀nà ìyọsíni kan kò bá ṣiṣẹ́, gbìyànjú òmíràn.

5 Ní ìpínlẹ̀ kan tí ó láásìkí gan-an tí àwọn onílé tí jẹ́ aláìbìkítà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba, àwọn akéde sakun láti wá ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí yóò ru ọkàn ìfẹ́ sókè. Nígbà tí wọ́n ń gbé ìwé Ìmọ̀ jáde lákànṣe, tọkọtaya kan gbìyànjú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ yí: “Ìwọ ha rò pé ẹ̀kọ́ gbígbámúṣé ṣe pàtàkì fún àṣeyọrí nínú ayé lónìí bí? Ìwọ ha gbà pé ẹ̀kọ́ tí ó múná dóko yẹ kí ó ní ìmọ̀ Bíbélì nínú bí?” Ní ọ̀sán ọjọ́ kan wọ́n fi ìwé mẹ́ta sóde, ọ̀kan nínú rẹ̀ ni wọ́n fún obìnrin kan tí ó sọ lẹ́yìn náà pé òun ti ka ìwé Ìmọ̀ látòkè délẹ̀, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

6 Nígbà tí o bá bá ẹ̀mí ìdágunlá pàdé, gbìyànjú onírúurú ọ̀nà ìyọsíni, béèrè àwọn ìbéèrè tí ń runi lọ́kàn sókè, kí o sì lo agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nípa báyìí, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba àgbàyanu ìrètí Ìjọba wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́