Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 26, 2007. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ January 1 sí February 26, 2007. [Àkíyèsí: Níbi tá ò bá ti sọ ibi tá a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, kó o ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Ìgbà wo ló yẹ́ ká jẹ́ kí àwùjọ rí bí wọ́n ṣe lè fi ọ̀rọ̀ wa sílò, báwo la sì ṣe lè ṣe é? [be-YR ojú ìwé 158 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí bí wọ́n ṣe lè fi ọ̀rọ̀ wa sílò, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? [be-YR ojú ìwé 159 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo èdè tó dára? [be-YR ojú ìwé 160]
4. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa lo oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ lọ́nà tó bá a mu rẹ́gí? [be-YR ojú ìwé 161 ìpínrọ̀ 5 àti 6; ojú ìwé 162 ìpínrọ̀ 1 àti 4]
5. Kí làwọn àǹfààní mélòó kan tó wà nínú sísọ̀rọ̀ látinú ìlapa èrò téèyàn mọ̀ sórí tàbí èyí téèyàn kọ síwèé? [be-YR ojú ìwé 166 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Béèyàn bá fẹ́ múra ìwé kíkà sílẹ̀, kí làwọn nǹkan tó yẹ kó ṣe? [be-YR ojú ìwé 43 ìpínrọ̀ 2 àti 4]
7. Kí ló ṣe pàtàkì ká mọ̀ bá a bá máa nífẹ̀ẹ́ ohun tó tọ́, tá a sì máa kórìíra ohun tí kò tọ́ bíi ti Jèhófà? (Héb. 5:14) [w05-YR 1/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 11]
8. Bá a bá ka nǹkan nínú Bíbélì tó mú ká máa ṣiyè méjì bóyá ohun tí Ọlọ́run ṣe tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà, kí ló yẹ ká rántí? [w05-YR 2/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 7]
9. Kí la ó ṣe táwọn èèyàn bá ní ká ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́? [w05-YR 4/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 9]
10. Ibo ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ‘àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún’ lóde òní, àǹfààní wo la sì lè rí látinú àwọn yàrá náà? (Aísá. 26:20) [w01-YR 3/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 17]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Kí ni “ojú ìràgàbò” kí sì ni “ohun híhun” tí Aísáyà 25:7 mẹ́nu bà?
12. Báwo lèèyàn ṣe lè “rí” Jèhófà kó sì “gbọ́” ọ̀rọ̀ rẹ̀? (Aís. 30:20, 21)
13. Bẹ́ẹ̀ ni àbí Bẹ́ẹ̀ kọ́: Nítorí pé Hesekáyà fẹ́ pẹ́ láyé ní gbogbo ọ̀nà ló ṣe gbàdúrà tó wà nínú Aísáyà 38:3.
14. Ọ̀nà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, báwo la sì ṣe lè fara wé wọn? (Ais. 43:10)
15. Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 52:11, 12, kí léèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè “gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà”?