Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù February 1-18: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! tàbí ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ìjọ. February 19–March 18: A ó ṣe àkànṣe ìpínkiri ìwé àṣàrò kúkúrú Kingdom News No. 37 tó ní àkọlé náà “Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!” March 19-31: Ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kẹ́ ẹ sì sapá gidigidi kẹ́ ẹ lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la óò lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn títí kan àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ wa mìíràn tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kẹ́ ẹ lè fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún èyíkéyìí lára wọn láti ní iye wákàtí tó yẹ kó ròyìn, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. Àwọn àmọ̀ràn tẹ́ ẹ lè fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà nínú lẹ́tà S-201-YR.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2007 ni, “O Lè Nífọ̀kànbalẹ̀ Nínú Ayé Tó Kún fún Ìdààmú Yìí!” Ẹ wo ìfilọ̀ tó jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2006.
◼ Ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tó máa wáyé lọ́dún 2007, a óò ya ibì kan sọ́tọ̀ fáwọn adití ní àwọn àpéjọ tá a tò sísàlẹ̀ yìí. Ibi tá a bá sì yà sọ́tọ̀ fún wọn yìí la ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà Ti Amẹ́ríkà.
Akábọ (EE-08) March 18 àti September 22 sí 23
Àkúrẹ́ (WE-12) February 17 àti August 11 sí 12
Bàdágìrì (WE-02) June 9 sí 10 àti September 2
Bàdágìrì (WE-04) June 16 àti July 28 sí 29
Bàdágìrì (WE-14) May 12 sí 13 àti July 22
Bàdágìrì (WE-23) June 17 àti September 8 sí 9
Benin City (ME-01) March 24 sí 25 àti July 8
Kàlàba (EE-21) June 10 àti September 15 sí 16
Dálùwọ́n (WE-01) February 10 sí 11 àti July 8
Dálùwọ́n (WE-03) February 24 sí 25 àti June 2
Dálùwọ́n (WE-13) March 17 sí 18 àti June 23
Dálùwọ́n (WE-22) June 30 àti October 6 sí 7
Ẹnúgu (EE-17) February 4 àti June 23 sí 24
Ẹnúgu (EE-19) January 20 sí 21 àti August 4
Ìbàdàn (WE-09) March 17 àti July 28 sí 29
Ìbàdàn (WE-10) August 5 àti September 29 sí 30
Igurúta Àlì (EE-22) February 18 àti May 5 sí 6
Iléṣà (WE-15) March 24 sí 25 àti July 7
Kàdúná (NE-01b) May 5 sí 6 àti August 11
Ọ̀tà (WE-05) March 31 sí April 1 àti August 18
Ọ̀tà (WE-06) January 6 sí 7 àti March 17
Ọ̀tà (WE-07) May 5 sí 6 àti August 19
Ọ̀tà (WE-25) March 18 àti June 23 sí 24
Ùbogò (ME-07) February 3 àti July 14 sí 15
Ùlì (EE-24) May 26 sí 27 àti August 12
Uyó (EE-20) March 4 àti July 7 sí 8