Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 11
Orin 153
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù June sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ June 15 àti Jí! April-June. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 4 fún Jí! April-June)
15 min: A Ti Mú Wa Gbára Dì fún Iṣẹ́ Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ February 15, 2002, ojú ìwé 24 sí 28. Àwọn Kristẹni kan kì í fẹ́ kọ́ àwọn tó fìfẹ́ hàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí ó ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò dáńgájíá tó. Síbẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń mú wa tóótun nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ àti ètò rẹ̀. Kì í ṣe torí àtifún wọn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ nìkan la ṣe ń lọ sọ́dọ̀ wọn. A gbọ́dọ̀ sapá láti kọ́ wọn. (Mát. 28:19, 20) Gba àwọn akéde níyànjú láti máa fi sọ́kàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
20 min: Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 13.
Orin 144 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 18
Orin 217
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: Ǹjẹ́ O Rántí? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2007, ojú ìwé 19.
20 min: “À Ń Láyọ̀ Bá A Ṣe Ń Lo Ara Wa Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà!”a Ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ bí àkókò bá ṣe wà sí.
Orin 82 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 25
Orin 15
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! April-June. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 4 fún Jí! April-June)
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: “Ṣé Wàá Gba Ẹnu Ọ̀nà ‘Ńlá Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Ìgbòkègbodò’ Wọlé?”b Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan tàbí méjì. Àwọn àyípadà wo ni wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè di aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n sì ti rí?
Orin 138 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 2
Orin 208
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù June sílẹ̀. Mẹ́nu ba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá ó lò lóṣù July, kó o sì ṣe àṣefihàn rẹ̀.
15 min: Ìjẹ́rìí Àìjẹ́-bí-Àṣà—Ọ̀nà Kan Pàtàkì Tá A Gbà Ń Wàásù Ìhìn Rere. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 101 àti 102. Dámọ̀ràn àwọn ọ̀nà mélòó kan tá a lè gbà wàásù láìjẹ́-bí-àṣà. Ní kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà.
20 min: “Ẹ Máa Bá A Lọ ní ‘Síso Èso Púpọ̀.’”c Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2003, àpótí tó wà lójú ìwé 21 tó ní àkòrí náà “Bá A Ṣe Lè ‘So Èso Pẹ̀lú Ìfaradà.’”
Orin 69 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.