Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 29, 2007. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ September 3 sí October 29, 2007.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí nìdí tí sísọ àsọtúnsọ fi jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 206 ìpínrọ̀ 1 àti 2, àpótí]
2. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ nígbà tá a bá ń sọ àsọyé? [be-YR ojú ìwé 210, àpótí]
3. Kí làwọn kókó ọ̀rọ̀ inú àsọyé kan, kí ló sì máa ran asọ̀rọ̀ lọ́wọ́ láti yan àwọn kókó náà? [be-YR ojú ìwé 212 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
4. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí kókó ọ̀rọ̀ pọ̀ jù nínú àsọyé? [be-YR ojú ìwé 213 àti 214 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa ru àwọn èèyàn lọ́kàn sókè, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe é? [be-YR ojú ìwé 215 ìpínrọ̀ 1; ojú ìwé 216 ìpínrọ̀ 1 sí 3, àpótí]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Báwo ni Sáàmù 119:89, 90 ṣe fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeé gbára lé? [w05-YR 4/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 3]
7. Kí ni omi tó ń sun láti ibi tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ń ṣàpẹẹrẹ? (Ìsík. 47:2-11) [w99-YR 3/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 2]
8. Báwo ni “àsọjáde Jèhófà” ṣe lè dáàbò bo ọkàn-àyà wa? (Sm. 18:30) [w05-YR 9/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2]
9. Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí tí wọ́n ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lóde òní lè rí kọ́ nínú ọ̀nà táwọn òbí Dáníẹ́lì, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò gbà tọ́ wọn? [w88-YR 12/1 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 10]
10. Kí ni ohun tó lè mú kí Jèhófà fi àánú hàn? [w89-YR 3/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 6]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Kí ni wíwọ̀n tí wọ́n wọn tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran túmọ̀ sí, kí ni ìyẹn sì mú kó dá wa lójú lónìí? (Ìsík. 40:2-5) [w99-YR 3/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 6; ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 7]
12. Ta ni “àwọn ìjòyè” tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìmúṣẹ tó kẹ́yìn ìran rẹ̀? (Ìsík. 48:21) [w99-YR 3/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 13 sí 15; ojú ìwé 22 sí 23 ìpínrọ̀ 19 àti 20]
13. Kí ni ìtúmọ̀ Dáníẹ́lì 2:21? [w98-YR 9/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 9]
14. Kí ló mú kí Dáníẹ́lì jẹ́ “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra” lójú Jèhófà? (Dán. 9:23) [dp-YR ojú ìwé 185 àti 186 ìpínrọ̀ 12; w04-YR 8/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 17]
15. Lọ́nà wo ni kò fi sí ‘ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ní ilẹ̀’ Ísírẹ́lì, báwo nìyẹn sì ṣe kàn wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? (Hós. 4:1, 2, 6) [w05-YR 11/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 21; jd-YR ojú ìwé 57 àti 58 ìpínrọ̀ 5; ojú ìwé 61 ìpínrọ̀ 10]