Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù October: Ilé Ìṣọ́ àti Jí!. Bí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o bá a sọ, fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?, jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀, kó o sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la máa lò. Bó o bá kíyè sí i pé ẹni tó o fẹ́ wàásù fún kì í ṣe òbí, fún un ní ìwé Ẹ Máa Ṣọ́nà! December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Àwọn ìwé tá a lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Sún Mọ́ Jèhófà tàbí ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tó bá ti wà ṣáájú ọdún 1991 tàbí ìwé tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tó bá wà lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà!
◼ Níwọ̀n bí oṣù December ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan lóṣù January, a óò jíròrò fídíò tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights, èyí tó dá lórí àwọn ìtọ́jú ìṣègùn míì tá a lè lò dípò ẹ̀jẹ̀. Bẹ́ ẹ bá fẹ́ fídíò yìí, kẹ́ ẹ béèrè nípasẹ̀ ìjọ yín bó bá ṣe lè yá tó.
◼ Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí ni “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2008.” Ẹ tọ́jú rẹ̀ kẹ́ ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún.
◼ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé arákùnrin tó bá bójú tó apá tó gbẹ̀yìn ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ló máa pe orin ìparí. Lẹ́yìn náà, òun tàbí arákùnrin mìíràn tó bá tóótun tó ti sọ fún ṣáájú ni kó fi àdúrà kádìí ìpàdé náà.
◼ Àkíyèsí fún ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà: Inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù October lédè Gẹ̀ẹ́sì nìkan la tẹ ìsọfúnni sí lórí bá a ṣe fẹ́ pín àkànṣe Jí! ti oṣù November lédè Gẹ̀ẹ́sì.