Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2008
Ìtọ́ni
Bí a ó ṣe máa darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 2008 la ṣàlàyé sísàlẹ̀ yìí.
IBI TÁ A TI MÚṢẸ́ JÁDE: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run [be-YR] àti “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò,” tó wà lẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (td-YR)
Kí ilé ẹ̀kọ́ yìí máa bẹ̀rẹ̀ LÁKÒÓKÒ. Lẹ́yìn orin, àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀, kẹ́ ẹ máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nísàlẹ̀ yìí. Lẹ́yìn iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa pe ẹni tí iṣẹ́ kàn sórí pèpéle.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: 5 min: Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, olùrànlọ́wọ́ agbaninímọ̀ràn tàbí alàgbà mìíràn tó tóótun ni kó máa sọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, èyí tá a mú látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Láwọn ìjọ tí alàgbà ò bá ti pọ̀ tó, a lè lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá tóótun.)
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ 1: 10 min: Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá tóótun ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí, kó sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú Ilé Ìṣọ́ tàbí ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìṣẹ́jú mẹ́wàá ni kó fi sọ ọ̀rọ̀ ìtọ́ni yìí. Kì í ṣe pé kí asọ̀rọ̀ náà kàn sọ̀rọ̀ lórí ibi tá a yàn fún un nìkan ni, ṣùgbọ́n ní pàtàkì, ó yẹ kó sọ ìwúlò kókó tó ń sọ̀rọ̀ lé lórí, kó sì tẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ni kó lò. A retí pé káwọn arákùnrin tó bá máa ṣe iṣẹ́ yìí rí i dájú pé àwọn ò kọjá àkókò tó yẹ kí wọ́n lò. A lè fún wọn nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́ bó bá yẹ.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTINÚ BÍBÉLÌ: 10 min: Fún ìṣẹ́jú márùn-ún àkọ́kọ́, kí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bá tóótun, tó máa ṣiṣẹ́ náà, ṣàlàyé bí Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ náà ṣe wúlò tó fún ìjọ. Ó lè sọ̀rọ̀ lórí apá èyíkéyìí lára Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ náà. Kì í wulẹ̀ ṣe pé kó kàn ṣe àkópọ̀ ibi tá a ní kó kà o. Ohun tí iṣẹ́ yìí wà fún ni láti jẹ́ kí àwùjọ rí ìdí tí wọ́n fi lè jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ tó ń sọ àti bí àǹfààní náà ṣe lè jẹ́ tiwọn. Kí asọ̀rọ̀ náà rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tó máa sọ kò kọjá ìṣẹ́jú márùn-ún. Kó wá jẹ́ kí àwùjọ lo ìṣẹ́jú márùn-ún tó kù láti fi sọ ohun tí wọ́n rí kọ́ látinú Bíbélì kíkà náà. Kó sọ pé kí àwùjọ sọ̀rọ̀ ṣókí (ní ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀) lórí ohun tí wọ́n rí kọ́ nínú Bíbélì kíkà náà àti bó ṣe lè ṣe wọ́n láǹfààní. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ pé káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a yàn sí kíláàsì mìíràn máa lọ síbẹ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ 2: 4 min: (Ó sì lè dín sí ìṣẹ́jú mẹ́rin nígbà míì.) Arákùnrin ni ká máa jẹ́ kó ka ìwé náà. Kí akẹ́kọ̀ọ́ ka ibi tá a yàn fún un láìsí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ àsọparí. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lógún jù lọ ni bó ṣe máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kàwé dáadáa nípa ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí: kíkàwé lọ́nà tó yéni yékéyéké, jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ni lẹ́nu, títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dídánudúró bó ṣe yẹ àti sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dáni.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ 3: 5 min: Arábìnrin ni ká máa yan iṣẹ́ yìí fún. A lè yan ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tá a fún ní iṣẹ́ yìí tàbí kí wọ́n fúnra wọn yan ọ̀kan lára ìgbékalẹ̀ tá a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 82 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a yàn fún un, kó sì lò ó lọ́nà tó máa bá onírúurú ọ̀nà tá a gbà ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ náà mu. Bí a ò bá kọ inú ìwé tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa láti lè mọ ohun tó máa sọ. Àwọn iṣẹ́ tá a kọ ibi tá a ti mú wọn jáde sí ni kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lógún jù lọ ni ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, bó ṣe mú kí onílé ronú lórí Ìwé Mímọ́ àti bó ṣe mú kó lóye àwọn kókó pàtàkì inú iṣẹ́ rẹ̀. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yan olùrànlọ́wọ́ kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ 4: 5 min: Kí akẹ́kọ̀ọ́ tá a yan iṣẹ́ yìí fún sọ̀rọ̀ lórí kókó tá a yàn fún un. Bá ò bá kọ ibi tá a ti mú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde síwájú iṣẹ́ náà, kí akẹ́kọ̀ọ́ lọ ṣèwádìí nínú àwọn ìwé wa. Bá a bá yàn án fún arákùnrin, kó sọ ọ́ bí àsọyé, kó sì darí ẹ̀ sí àwùjọ. Bó bá jẹ́ arábìnrin ni yóò bójú tó o, kó tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 3. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè gbé Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 4 fún arákùnrin nígbàkigbà tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé, bá a bá sàmì ìràwọ̀ (*) síwájú ẹṣin ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, àwọn arákùnrin ni ká yàn án fún kí wọ́n lè sọ ọ́ bí àsọyé. Nígbà tó bá yẹ, alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kẹ́ ẹ jẹ́ kó bójú tó irú àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí, ìyẹn bí àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà nínú ìjọ yín bá pọ̀ ju iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí iṣẹ́ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ.
ÌMỌ̀RÀN: 1 min: Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ò ní í sọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí akẹ́kọ̀ọ́ máa ṣiṣẹ́ lé lórí fún àwùjọ. Lẹ́yìn Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 2, 3 àti 4, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró lórí ohun kan tó kíyè sí pé ó dára nínú iṣẹ́ náà. Kì í ṣe pé kó kàn kí akẹ́kọ̀ọ́ pé “o ṣeun,” kàkà bẹ́ẹ̀, kó ṣàlàyé àwọn ìdí pàtó tí ohun tó kíyè sí nínú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà fi wúlò. Bó bá kíyè sí i pé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan kù síbì kan, bí ìpàdé bá parí tàbí nígbà míì, kó fún un nímọ̀ràn tó máa mú kó tẹ̀ síwájú.
ÀKÓKÒ: Akẹ́kọ̀ọ́ kankan kò gbọ́dọ̀ kọjá àkókò, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ náà má sì ṣe sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Ká fi ọgbọ́n dá Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 2 sí Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 4 dúró bí àkókò wọn bá ti pé. Bí àwọn arákùnrin tó máa bójú tó ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 1 tàbí àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà bá kọjá àkókò, ká fún wọn nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́. Kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ rí i pé àwọn ò kọjá àkókò. Àkókò tá ó fi darí Ilé Ẹ̀kọ́: 45 min: Láìsí orin àti àdúrà níbẹ̀.
ÌWÉ ÌMỌ̀RÀN Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Èyí wà nínú ìwé tá à ń lò fún ilé ẹ̀kọ́.
OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN: Bí alàgbà kan tó tóótun bá wà, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè yàn án pé kó máa ran alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Bí àwọn alàgbà bá pọ̀ nínú ìjọ, a lè máa lo alàgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó tóótun lọ́dọọdún. Ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn ni láti máa fún àwọn arákùnrin tó ń bójú tó Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ 1 àti kókó pàtàkì látinú Bíbélì nímọ̀ràn ní ìdákọ́ńkọ́, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kó jẹ́ pé gbogbo ìgbà táwọn alàgbà bíi tiẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá bójú tó àwọn iṣẹ́ yìí ni yóò máa gbà wọ́n nímọ̀ràn.
ÀTÚNYẸ̀WÒ ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN: 30 min: Ní oṣù méjì-méjì, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò máa darí àtúnyẹ̀wò kan. Ṣáájú èyí, a óò gbọ́ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì, bá a ṣe ṣàlàyé lókè. Àwọn kókó tá a jíròrò nínú ilé ẹ̀kọ́ láàárín oṣù méjì sí àkókò yẹn, títí kan ti ọ̀sẹ̀ yẹn gan-an ni àtúnyẹ̀wò náà yóò dá lé. Bí àpéjọ àyíká yín bá bọ́ sí ọ̀sẹ̀ Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ẹ sún àtúnyẹ̀wò náà (àti ìyókù nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sẹ̀ yẹn) sí ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé àpéjọ àyíká yín. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé ti àpéjọ àyíká yín ni kẹ́ ẹ wá ṣe ní àpéjọ àyíká. Bí alábòójútó àyíká yóò bá bẹ ìjọ yín wò ní ọ̀sẹ̀ tí àtúnyẹ̀wò bọ́ sí, orin, ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì tó wà fún ọ̀sẹ̀ yẹn ni kẹ́ ẹ lò. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìtọ́ni (tó máa tẹ̀ lé ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ) tó wà fún ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e ni kẹ́ ẹ sọ. Ní ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò yẹn, ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ àtàwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì tó wà fún ọ̀sẹ̀ yẹn lẹ máa gbọ́, lẹ́yìn náà lẹ óò wá ṣe àtúnyẹ̀wò.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Jan. 7 Bíbélì kíkà: Mátíù 1-6 Orin 62
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣe Àlàyé Tó Bá Yẹ (be-YR ojú ìwé 228 ìpínrọ̀ 2 àti 3)
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìhìn Rere Mátíù—Apá 1 (w89-YR 7/15 ojú ìwé 24)
No. 2: Mátíù 5:1-20
No. 3: td-YR 35B Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Kristi
No. 4: Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
Jan. 14 Bíbélì kíkà: Mátíù 7-11 Orin 224
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ipò Ọkàn Onítọ̀hún Ṣe Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 228 ìpínrọ̀ 4 sí 6)
No. 1: Ní Inú Dídùn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 2: Mátíù 10:1-23
No. 3: Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Jẹ́ Olóòótọ́
No. 4: td-YR35D A Gbọ́dọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Tó Máa Fi Hàn Pé A Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Kristi
Jan. 21 Bíbélì kíkà: Mátíù 12-15 Orin 133
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ (be-YR ojú ìwé 230 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 1: Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́ (be-YR ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Mátíù 14:1-22
No. 3: td-YR 21A Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe fún Aráyé
No. 4: Ta Ni Aṣòdì-sí-Kristi?
Jan. 28 Bíbélì kíkà: Mátíù 16-21 Orin 176
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí Ìwádìí Ṣe Lè Mú Kí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: “Ẹ Máa Fiyè sí Bí Ẹ Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀” (be-YR ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Mátíù 17:1-20
No. 3: td-YR 21B Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ sí Í Ṣàkóso Nígbà Táwọn Ọ̀tá Kristi ṣì Wà Láàyè
No. 4: Àwọn Ohun Táwa Kristẹni Kà sí Mímọ́
Feb. 4 Bíbélì kíkà: Mátíù 22-25 Orin 151
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Máa Ṣàlàyé Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 4 àti 5)
No. 1: Fífetísílẹ̀ Láwọn Ìpàdé àti Láwọn Àpéjọ (be-YR ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 5)
No. 2: Mátíù 23:1-24
No. 3: Ìyè Àìnípẹ̀kun Ò Ní Sú Wa
No. 4: td-YR 21D Akitiyan Aráyé Kọ́ Ló Máa Fìdí Ìjọba Ọlọ́run Múlẹ̀
Feb. 11 Bíbélì kíkà: Mátíù 26-28 Orin 110
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 232 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìhìn Rere Mátíù—Apá 2 (w89-YR 7/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 2: Mátíù 27:1-22
No. 3: Ìdí Tí Ìgbàgbọ́ Fi Ju Pé Kéèyàn Kàn Gbà Pé Ọlọ́run Wà
No. 4: td-YR 39A Ohun Tí “Òpin Ayé” Túmọ̀ sí Gan-an
Feb. 18 Bíbélì kíkà: Máàkù 1-4 Orin 167
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Yéni (be-YR ojú ìwé 232 ìpínrọ̀ 2 sí 4)
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìhìn Rere Máàkù—Apá 1 (w89-YR 10/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí 8)
No. 2: Máàkù 2:1-17
No. 3: td-YR 39B Máa Kíyè Sáwọn Àmì Tó Fi Hàn Pé À Ń Gbé ní Ọjọ́ Ìkẹyìn
No. 4: Bí Ìfẹ́ Ṣe Ń Mú Kéèyàn Nígboyà
Feb. 25 Bíbélì kíkà: Máàkù 5-8 Orin 72
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Wíwá Àlàyé Tó Lè Ṣe Àwùjọ Láǹfààní (be-YR ojú ìwé 232 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 233 ìpínrọ̀ 4)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Mar. 3 Bíbélì kíkà: Máàkù 9-12 Orin 195
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ Jáde Láti Ibi Tá A Ti Yanṣẹ́ fún Ọ (be-YR ojú ìwé 234 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 235 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Já Fáfá (be-YR ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: Máàkù 11:1-18
No. 3: Ìdí Tí Ọlọ́run Kò Fi Lè Purọ́
No. 4: td-YR 33A Ọlọ́run Ṣèlérí Páwọn Tó Bá Pa Òfin Òun Mọ́ Á Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
Mar. 10 Bíbélì kíkà: Máàkù 13-16 Orin 87
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 236 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìhìn Rere Máàkù—Apá 2 (w89-YR 10/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 2: Máàkù 14:1-21
No. 3: td-YR 33B Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Máa Lọ Sọ́run
No. 4: Ìdí Tí ‘Ìrunú Èèyàn Kì Í Fi Í Ṣiṣẹ́ Yọrí sí Òdodo Ọlọ́run’ (Ják. 1:20)
Mar. 17 Bíbélì kíkà: Lúùkù 1-3 Orin 13
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Fi Ìbéèrè Nasẹ̀ Àwọn Kókó Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 237 ìpínrọ̀ 1 sí 2)
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìhìn Rere Lúùkù—Apá 1 (w89-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1 sí 8)
No. 2: Lúùkù 1:1-23
No. 3: Ìdí Tí ‘Ìgbàgbọ́ Láìsí Àwọn Iṣẹ́ Fi Jẹ́ Aláìṣiṣẹ́’ (Ják. 2:20)
No. 4: td-YR 33D Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ọ̀kẹ́ Àìmọye “Àgùntàn Mìíràn” Máa Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
Mar. 24 Bíbélì kíkà: Lúùkù 4-6 Orin 156
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Fi Ìbéèrè Ṣàlàyé Kókó Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 237 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Rántí Àwọn Nǹkan Tá A Ti Kọ́ (be-YR ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Lúùkù 4:1-21
No. 3: td-YR 19A Ẹ Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Máa Ní Ọlá
No. 4: Bá A Bá Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Lọ́kàn A Ò Ní Fẹ́ Máa Dẹ́ṣẹ̀
Mar. 31 Bíbélì kíkà: Lúùkù 7-9 Orin 122
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Fi Ìbéèrè Mọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Àwọn Èèyàn (be-YR ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 3 sí 5)
No. 1: Kí Nìdí Tá A Fi Ní Láti Fi Ara Wa fún Ìwé Kíkà? (be-YR ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Lúùkù 7:1-17
No. 3: Ẹ̀rí Tó Wà Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa àti Pé Ó Fẹ́ Kí Inú Wa Máa Dùn
No. 4: td-YR 19B Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Bọ̀wọ̀ fún Ìlànà Ipò Orí
Apr. 7 Bíbélì kíkà: Lúùkù 10-12 Orin 68
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Fi Ìbéèrè Tẹ Ọ̀rọ̀ Mọ́ni Lọ́kàn (be-YR ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 239 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Bó O Ṣe Lè Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà (be-YR ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Lúùkù 11:37-54
No. 3: td-YR 19D Ojúṣe Àwọn Kristẹni Òbí Sáwọn Ọmọ Wọn
No. 4: Kí Ni Ìtumọ̀ Ìṣípayá 17:17?
Apr. 14 Bíbélì kíkà: Lúùkù 13-17 Orin 86
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Fi Ìbéèrè Tú Èrò Búburú Fó (be-YR ojú ìwé 239 ìpínrọ̀ 2 sí 4)
No. 1: Bá A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ (be-YR ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Lúùkù 16:1-15
No. 3: Ẹ̀kọ́ Tí Òfin Ọlọ́run Kọ́ Wa Nípa Pípèéṣẹ́ (Léf. 19:9, 10)
No. 4: td-YR 19E Ẹni Tó Bá Jẹ́ Kristẹni Bíi Tiwa La Gbọ́dọ̀ Bá Ṣègbéyàwó
Apr. 21 Bíbélì kíkà: Lúùkù 18-21 Orin 182
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àfiwé Tààrà àti Àfiwé Ẹlẹ́lọ̀ọ́ (be-YR ojú ìwé 240 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 241 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìhìn Rere Lúùkù—Apá 2 (w89-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 9 sí ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 5)
No. 2: Lúùkù 18:1-17
No. 3: td-YR 19Ẹ Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Ṣe Akóbìnrinjọ
No. 4: Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ohun Gbogbo “Láìsí Ìkùnsínú” (Fílí. 2:14)
Apr. 28 Bíbélì kíkà: Lúùkù 22-24 Orin 218
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Lo Àpẹẹrẹ (be-YR ojú ìwé 241 ìpínrọ̀ 2 sí 4)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
May 5 Bíbélì kíkà: Jòhánù 1-4 Orin 31
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àpẹẹrẹ Inú Ìwé Mímọ́ (be-YR ojú ìwé 242 ìpínrọ̀ 1 àti 2)
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìròyìn Rere Jòhánù—Apá 1 (w90-YR 3/15 ojú ìwé 24)
No. 2: Jòhánù 3:1-21
No. 3: Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Látinú Bí Dáfídì Ò Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Pa Sọ́ọ̀lù Ọba
No. 4: td-YR 23A Màríà Kì Í Ṣe “Ìyá Ọlọ́run”
May 12 Bíbélì kíkà: Jòhánù 5-7 Orin 150
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ǹjẹ́ Ó Máa Yé Àwọn Èèyàn? (be-YR ojú ìwé 242 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 243 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lérè (be-YR ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Jòhánù 6:1-21
No. 3: Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Látinú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ananíà àti Sáfírà
No. 4: td-YR 23B Bíbélì Fi Hàn Pé Màríà Kì Í Ṣe “Wúńdíá Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Rẹ̀”
May 19 Bíbélì kíkà: Jòhánù 8-11 Orin 102
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àpèjúwe Tá A Gbé Ka Ohun Táwọn Èèyàn Mọ̀ (be-YR ojú ìwé 244 ìpínrọ̀ 1 àti 2)
No. 1: Bá A Ṣe Lè Ṣèwádìí Látinú Bíbélì (be-YR ojú ìwé 33 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Jòhánù 11:38-57
No. 3: td-YR 28A Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Sọ Nípa Ìrántí Ikú Kristi
No. 4: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Ṣe Òfin Kẹwàá Níwọ̀n Bí Kò Ti Ṣeé Ṣe Láti Fìyà Jẹ Ẹni Tó Bá Rú Òfin Náà?
May 26 Bíbélì kíkà: Jòhánù 12-16 Orin 3
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àpèjúwe Tó Máa Yé Àwùjọ Tó Ò Ń Bá Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 244 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 245 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Kíkọ́ Láti Lo Àwọn Ohun Èlò Ìṣèwádìí Yòókù (be-YR ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 38 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Jòhánù 12:1-19
No. 3: td-YR 28B Máàsì Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
No. 4: Bá A Ṣe Ń Ju Ẹrù Ìnira Wa Sọ́dọ̀ Jèhófà (Sm. 55:22)
June 2 Bíbélì kíkà: Jòhánù 17-21 Orin 198
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 247 ìpínrọ̀ 1 àti 2)
No. 1: Àwọn Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìròyìn Rere Jòhánù—Apá 2 (w90-YR 3/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 2: Jòhánù 21:1-14
No. 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gba Ọlọ́run Tá Ò Lè Rí Gbọ́?
No. 4: td-YR 37A Gbogbo Kristẹni Ló Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Òjíṣẹ́
June 9 Bíbélì kíkà: Ìṣe 1-4 Orin 92
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí Jésù Ṣe Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí (be-YR ojú ìwé 247 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Àwọn Onítara Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Báṣẹ́ Nìṣó!—Apá 1 (w90-YR 5/15 ojú ìwé 24 àti 25, láìsí àpótí)
No. 2: Ìṣe 1:1-14
No. 3: td-YR 37B Béèyàn Ṣe Lè Tóótun Láti Ṣiṣẹ́ Ìwàásù
No. 4: Kí Ni “Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ” Túmọ̀ Sí (Héb. 3:6)
June 16 Bíbélì kíkà: Ìṣe 5-7 Orin 2
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tí A Lè Fojú Rí (be-YR ojú ìwé 248 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Bá A Ṣe Lè Kó Ọ̀rọ̀ Tá A Máa Sọ Jọ (be-YR ojú ìwé 39 sí 42)
No. 2: Ìṣe 5:1-16
No. 3: td-YR 6A Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe Inúnibíni Sáwọn Kristẹni
No. 4: Lọ́nà Wo Ni Ìbẹ̀rù Jèhófà Gbà Jẹ́ Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ọgbọ́n? (Sm. 111:10)
June 23 Bíbélì kíkà: Ìṣe 8-10 Orin 116
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Lo Àwòrán, Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àtàwọn Fídíò Tí Ètò Jèhófà Ṣe (be-YR ojú ìwé 248 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 249 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Bá A Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 43 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Ìṣe 8:1-17
No. 3: Bí Jésù Ṣe Máa ‘Dá Àwọn Òtòṣì Nídè’ (Sm. 72:12)
No. 4: td-YR 6B Aya Kò Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Kí Ọkọ Mú Òun Pa Ìjọsìn Ọlọ́run Tì
June 30 Bíbélì kíkà: Ìṣe 11-14 Orin 79
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ohun Tí A Lè Fojú Rí Níwájú Àwùjọ Ńlá (be-YR ojú ìwé 249 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 250 ìpínrọ̀ 1)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
July 7 Bíbélì kíkà: Ìṣe 15-17 Orin 203
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìdí Tí Fífi Èrò Wérò Fi Ṣe Pàtàkì (be-YR ojú ìwé 251 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Mímúra Iṣẹ́ Tó Ní Ẹṣin Ọ̀rọ̀ àti Ìgbékalẹ̀ (be-YR ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 46 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Ìṣe 16:1-15
No. 3: Àwọn Ohun Tó Ń Mú Ká Máa Sin Jèhófà Láìbẹ̀rù
No. 4: td-YR 6D Ọkọ Kò Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Kí Aya Dí Òun Lọ́wọ́ Láti Máa Sin Ọlọ́run
July 14 Bíbélì kíkà: Ìṣe 18-21 Orin 32
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ibi Tó Yẹ Kó O Ti Bẹ̀rẹ̀ (be-YR ojú ìwé 251 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 252 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 47 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: Ìṣe 20:1-16
No. 3: td-YR 1A Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́
No. 4: Ẹ̀kọ́ Wo Lohun Tí Òfin Ọlọ́run Kà Léèwọ̀ Nínú Ẹ́kísódù 23:19b Kọ́ Wa?
July 21 Bíbélì kíkà: Ìṣe 22-25 Orin 200
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìgbà Tó Yẹ Kó O Juwọ́ Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 252 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 253 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Bá A Ṣe Lè Máa Múra Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Àtàwọn Iṣẹ́ Míì Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 51 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Ìṣe 22:1-16
No. 3: Ọ̀nà Wo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Gbà Mú Jòhánù 13:34, 35 Ṣẹ?
No. 4: td-YR 1B Ìdí Táwọn Àdúrà Kan Kì Í Fi Í Gbà
July 28 Bíbélì kíkà: Ìṣe 26-28 Orin 29
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Máa Béèrè Ìbéèrè Ká sì Máa Ṣàlàyé Ìdí Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 253 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 254 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Àwọn Onítara Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Báṣẹ́ Nìṣó!—Apá 2 (w90-YR 5/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 sí 4 àtàwọn àpótí ojú ìwé 25 àti 26)
No. 2: Ìṣe 26:1-18
No. 3: td-YR 7A Àyànmọ́ Kọ́ Ló Ń Darí Ẹ̀dá
No. 4: Ìdí Tí Jèhófà Fi Ń Ní Sùúrù
Aug. 4 Bíbélì kíkà: Róòmù 1-4 Orin 170
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ẹ̀rí Yíyèkooro Tó Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 255 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 256 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Àwọn Ará Róòmù Rí Ìhìn Dídára Jù Lọ Gbà—Apá 1 (w90-YR 8/1 ojú ìwé 23 àti 24 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Róòmù 3:1-20
No. 3: Báwọn Áńgẹ́lì Ṣe Ń Fún Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Lókun Tí Wọ́n sì Ń Dáàbò Bò Wọ́n
No. 4: td-YR 27A Ìwàláàyè Jésù bí Èèyàn Mú Kí “Ìràpadà fún Gbogbo Ènìyàn” Ṣeé Ṣe
Aug. 11 Bíbélì kíkà: Róòmù 5-8 Orin 207
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè fi Àfikún Ẹ̀rí Ti Ọ̀rọ̀ Lẹ́yìn (be-YR ojú ìwé 256 ìpínrọ̀ 3 sí 5)
No. 1: Mímúra Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 52 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 54 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: Róòmù 6:1-20
No. 3: td-YR 27B Ìdí Tó Fi Ṣeé Ṣe fún Jésù Láti San Ìràpadà
No. 4: Bí Òdodo Ṣe Lè Dáàbò Bò Wá
Aug. 18 Bíbélì kíkà: Róòmù 9-12 Orin 152
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Mú Ẹ̀rí Tó Pọ̀ Tó Jáde (be-YR ojú ìwé 257 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: Àwọn Ará Róòmù Rí Ìhìn Dídára Jù Lọ Gbà—Apá 2 (w90-YR 8/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Róòmù 9:1-18
No. 3: Àwọn Ewu Wo Ló Wà Nínú Sísọ̀rọ̀ Ẹ̀yìn àti Títan Òfófó Kálẹ̀?
No. 4: td-YR 14A Bá A Ṣe Lè Dá Ìsìn Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Tó Wà Mọ̀
Aug. 25 Bíbélì kíkà: Róòmù 13-16 Orin 16
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Rí I Dájú Pé Ọ̀rọ̀ Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn (be-YR ojú ìwé 258 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Sept. 1 Bíbélì kíkà: 1 Kọ́ríńtì 1-9 Orin 199
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Mú Káwọn Èèyàn Sọ Ohun Tó Wà Lọ́kàn Wọn (be-YR ojú ìwé 259 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run”—Apá 1 (w90-YR 9/15 ojú ìwé 24 àti 25 ìpínrọ̀ 1, láìsí àwọn àpótí)
No. 2: 1 Kọ́ríńtì 4:1-17
No. 3: td-YR 14A Ṣó Burú Kéèyàn Sọ Pé Ẹ̀kọ́ Èké Kò Tọ̀nà?
No. 4: Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Sọni Di Ọlọ́rọ̀?
Sept. 8 Bíbélì kíkà: 1 Kọ́ríńtì 10-16 Orin 35
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Ń Gbin Ẹ̀mí Rere Sọ́kàn Olùgbọ́ (be-YR ojú ìwé 259 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 260 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run”—Apá 2 (w90-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí 6, àtàwọn àpótí)
No. 2: 1 Kọ́ríńtì 13:1-14:6
No. 3: Ìdí Tínú Àwọn Olùṣe Ọ̀rọ̀ Náà Fi Máa Ń Dùn
No. 4: td-YR 14D Ìgbà Wo Ni Inú Ọlọ́run Máa Ń Dùn sí I Pé Kéèyàn Yí Ẹ̀sìn Pa Dà?
Sept. 15 Bíbélì kíkà: 2 Kọ́ríńtì 1-7 Orin 58
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́ Láti Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 260 ìpínrọ̀ 2 àti 3)
No. 1: “Ẹ Máa Dán Ara Yín Wò Bóyá Ẹ Wà Nínú Ìgbàgbọ́”—Apá 1 (w90-YR 9/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 sí 5 sí ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1, àti àpótí)
No. 2: 2 Kọ́ríńtì 1:1-14
No. 3: td-YR 14E Ṣé Gbogbo Ẹ̀sìn ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?
No. 4: Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Fi Ń Láyọ̀ Bí Wọ́n Bá Ń Ṣenúnibíni sí Wọn
Sept. 22 Bíbélì kíkà: 2 Kọ́ríńtì 8-13 Orin 12
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ojú Pàtàkì ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ohun Tá À Ń Hù Níwà (be-YR ojú ìwé 260 ìpínrọ̀ 4 àti 5)
No. 1: “Ẹ Máa Dán Ara Yín Wò Bóyá Ẹ Wà Nínú Ìgbàgbọ́”—Apá 2 (w90-YR 9/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 2 sí 5, àti àpótí)
No. 2: 2 Kọ́ríńtì 9:1-15
No. 3: Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Ṣe Apá Kan Ayé
No. 4: td-YR 3A Àwọn Wo Ló Máa Jíǹde?
Sept. 29 Bíbélì kíkà: Gálátíà 1-6 Orin 163
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ríran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Yẹ Ara Wọn Wò (be-YR ojú ìwé 261 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Ẹ Dúró Ṣinṣin Nínú Òmìnira Kristẹni! (w90-YR 11/15 ojú ìwé 23)
No. 2: Gálátíà 1:1-17
No. 3: td-YR 3B Ibo Làwọn Òkú Máa Jíǹde Sí?
No. 4: Bí Ìfẹ́ Ṣe Lè Mú Kéèyàn Ṣẹ́pá Ìbẹ̀rù Èèyàn
Oct. 6 Bíbélì kíkà: Éfésù 1-6 Orin 99
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Èèyàn Láti Máa Ṣègbọràn Látọkànwá (be-YR ojú ìwé 261 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 262 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Ó Dájú Pé Kristi Lè Mú Ká Wà Níṣọ̀kan (w90-YR 11/15 ojú ìwé 24)
No. 2: Éfésù 3:1-19
No. 3: Kì Í Ṣe Ojo Èèyàn Ló Máa Ń Tọrọ Àforíjì
No. 4: td-YR 26A Àwọn Èèyàn Ò Ní Fi Ojúyòójú Rí Kristi Nígbà Tó Bá Padà Wá
Oct. 13 Bíbélì kíkà: Fílípì 1–Kólósè 4 Orin 123
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Pẹ̀lú Jèhófà Kí Ọ̀rọ̀ Wa Lè Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn (be-YR ojú ìwé 262 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Ẹ Máa Sa Eré Ìje Náà Nìṣó! (w90-YR 11/15 ojú ìwé 25)
No. 2: Fílípì 3:1-16
No. 3: td-YR 26B Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tá A Lè Fojú Rí Ló Jẹ́ Ká Mọ̀gbà Tí Kristi Padà Wá
No. 4: a Ẹ Má Ṣe Dẹ́kun Níní Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọ́run àti Kristi (w90-YR 11/15 ojú ìwé 26)
Oct. 20 Bíbélì kíkà: 1 Tẹsalóníkà 1–2 Tẹsalóníkà 3 Orin 161
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Béèyàn Ò Ṣe Ní Kọjá Àkókò Nígbà Tó Bá Níṣẹ́ (be-YR ojú ìwé 263 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 264 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Ẹ Wà Ní Sẹpẹ́ De Ọjọ́ Jèhófà! Kẹ́ Ẹ Má sì Ṣe Dẹ́kun Ṣíṣe Ohun Tó Tọ́ (w91-YR 1/15 ojú ìwé 22 àti 23)
No. 2: 1 Tẹsalóníkà 1:1-2:8
No. 3: td-YR 42A Kò Pọn Dandan Káwọn Kristẹni Pa Sábáàtì Mọ́
No. 4: b Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ àti Ẹ̀rí Ọkàn Rere, Kẹ́ Ẹ sì Gbára Lé Okun Tí Ọlọ́run Ń Fúnni (w91-YR 1/15 ojú ìwé 30 àti 31)
Oct. 27 Bíbélì kíkà: 1 Tímótì 1–2 Tímótì 4 Orin 69
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Gbígbani-níyànjú Lọ́nà tó Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 265 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 266 ìpínrọ̀ 1)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Nov. 3 Bíbélì kíkà: Títù 1–Fílémónì Orin 149
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Máa Fìfẹ́ Gbani Níyànjú (be-YR ojú ìwé 266 ìpínrọ̀ 2 sí 5)
No. 1: Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Ba Ìgbàgbọ́ Yín Jẹ́ (w91-YR 2/15 ojú ìwé 22)
No. 2: Títù 1:1-16
No. 3: td-YR 42B Kì Í Ṣe Àwọn Kristẹni Ni Òfin Sábáàtì Wà Fún
No. 4: c Ìfẹ́ Ará Má Ń Mú Ká Ṣe Ohun Tó Tọ́ (w91-YR 2/15 ojú ìwé 23)
Nov. 10 Bíbélì kíkà: Hébérù 1-8 Orin 144
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé Mímọ́ Gbani Níyànjú (be-YR ojú ìwé 267 ìpínrọ̀ 1 àti 2)
No. 1: Ìdí Tí Ìjọsìn Kristẹni Fi Yàtọ̀ Gedegbe—Apá 1 (w91-YR 2/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1 sí 6, láìfi àpótí ojú ìwé 24 kún un)
No. 2: Hébérù 3:1-19
No. 3: td-YR 42D Ìgbà Tí Ìsinmi Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ àti Ìgbà Tó Parí
No. 4: Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ojúlówó Ìrẹ̀lẹ̀ àti Ìrẹ̀lẹ̀ Ojú Lásán
Nov. 17 Bíbélì kíkà: Hébérù 9-13 Orin 28
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Ní Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ (be-YR ojú ìwé 267 ìpínrọ̀ 3 sí 4)
No. 1: Ìdí Tí Ìjọsìn Kristẹni Fi Yàtọ̀ Gedegbe—Apá 2 (w91-YR 2/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 3, àti àpótí tó wà lójú ìwé 24)
No. 2: Hébérù 10:1-17
No. 3: td-YR 18A Nípasẹ̀ Kristi Nìkan Ṣoṣo Ni Ọlọ́run Fi Mú Kí Ìgbàlà Ṣeé Ṣe
No. 4: Bí Ìdáríjì Ṣe Ń Mú Ká Wà Níṣọ̀kan
Nov. 24 Bíbélì kíkà: Jákọ́bù 1-5 Orin 88
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Fáwọn Ẹlòmíì Níṣìírí (be-YR ojú ìwé 268 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Ní Ìgbàgbọ́ àti Ọgbọ́n (w91-YR 3/15 ojú ìwé 23)
No. 2: Jákọ́bù 1:1-21
No. 3: td-YR 18B “Ìgbàlà Lẹ́ẹ̀kan, Ìgbàlà Gbogbo Ìgbà” Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
No. 4: Bí “Àánú” Ṣe Ń “Yọ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Lórí Ìdájọ́” (Ják. 2:13)
Dec. 1 Bíbélì kíkà: 1 Pétérù 1–2 Pétérù 3 Orin 18
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Rírántí Àwọn Ohun Tí Jèhófà Ti Ṣe (be-YR ojú ìwé 268 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 269 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Ẹ Máa Dúró Ṣinṣin Nínú Ìgbàgbọ́ (w91-YR 3/15 ojú ìwé 30)
No. 2: 1 Pétérù 2:1-17
No. 3: td-YR 18D “Ìgbàlà Gbogbo Ayé” Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
No. 4: d Ẹ Kíyè sí Asọtẹ́lẹ̀ Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! (w91-YR 3/15 ojú ìwé 31)
Dec. 8 Bíbélì kíkà: 1 Jòhánù 1–Júdà Orin 50
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ Ọ̀nà Tí Jèhófà Ti Gbà Ran Àwọn Èèyàn Ẹ̀ Lọ́wọ́ (be-YR ojú ìwé 269 ìpínrọ̀ 3 sí 5)
No. 1: Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Rírìn Nínú Ìmọ́lẹ̀ àti Ìfẹ́, Kẹ́ Ẹ sì Máa Rìn Gẹ́gẹ́ bí Àwọn Alájùmọ̀ṣiṣẹ́pọ̀ Nínú Òtítọ́ (w91-YR 4/15 ojú ìwé 29 àti 30)
No. 2: 1 Jòhánù 4:1-16
No. 3: td-YR 15A Ohun Tó Ń Jẹ́ Ẹ̀ṣẹ̀
No. 4: e Ẹ Ṣọ́ra fún Àwọn Apẹ̀yìndà! (w91-YR 4/15 ojú ìwé 31)
Dec. 15 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 1-6 Orin 219
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bá A Ṣe Lè Fi Hàn Pé Inú Wa Dùn sí Ohun Tí Ọlọ́run Ń Ṣe Nísinsìnyí (be-YR ojú ìwé 270 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 271 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Àwọn Ìran Atanijí Tí Ń fún Ìgbàgbọ́ Lókun—Apá 1 (w91-YR 5/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 4, àti àpótí tó wà lójú ìwé 21)
No. 2: Ìṣípayá 3:1-13
No. 3: td-YR 15B Ohun Tó Mú Kí Gbogbo Èèyàn Máa Jìyà Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù
No. 4: Ìdí Tó Fi Níbi Tí Sùúrù àti Àánú Mọ
Dec. 22 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 7-14 Orin 21
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jàǹfààní Kíkún Látinú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (be-YR ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Àwọn Ìran Atanijí Tí Ń fún Ìgbàgbọ́ Lókun—Apá 2 (w91-YR 5/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 8)
No. 2: Ìṣípayá 8:1-13
No. 3: td-YR 15D Kí Ni Èso Tí Ọlọ́run Kà Léèwọ̀?
No. 4: Kí Ni Gbólóhùn Náà “Ọlọ́run Tóbi Ju Ọkàn-Àyà Wa Lọ” Túmọ̀ Sí? (1 Jòhánù 3:20)
Dec. 29 Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 15-22 Orin 60
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Kíkàwé Lọ́nà Tó Tọ́ (be-YR ojú ìwé 83 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
b Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
c Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
d Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
e Àwọn arákùnrin nìkan ni ká yan iṣẹ́ yìí fún, ó sàn kí wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.