Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Bó o bá kíyè sí i pé ẹni tó o fẹ́ wàásù fún kì í ṣe òbí, fún un ní ìwé Ẹ Máa Ṣọ́nà! December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Àwọn ìwé tá a lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Sún Mọ́ Jèhófà tàbí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tó bá ti wà ṣáájú ọdún 1991 tàbí ìwé tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tó bá wà lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! February: Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. March: Ẹ lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Níwọ̀n bí oṣù December ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣètìlẹ́yìn nípasẹ̀ ìwé sọ̀wédowó ní àpéjọ àgbègbè tàbí tẹ́ ẹ bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, “Watch Tower” ni kẹ́ ẹ kọ sórí ìwé sọ̀wédowó gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n máa sanwó náà fún. Ẹ jọ̀wọ́ kọ “Watch” àti “Tower” lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o.
◼ A rọ gbogbo àwọn akéde tí kò bá tíì kọ̀rọ̀ sínú káàdì DPA wọn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Káàdì DPA la fi ń fa àṣẹ ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn lé aṣojú ẹni lọ́wọ́, òun ló máa dáàbò bo ẹ̀tọ́ tó o ní láti kọ ìfàjẹ̀sínilára. Káwọn alàgbà ṣèrànwọ́ tó bá yẹ fáwọn akéde lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù December 2006.
◼ Àwọn akéde ò ní máa lo fọ́ọ̀mù S-3 mọ́ láti fi kọ ìròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Àmọ́, a ṣì gbọ́dọ̀ máa kọ iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a bá darí sínú fọ́ọ̀mù S-4. Ní báyìí, iye àwọn tó bá wá sípàdé ìjọ nìkan la óò máa kọ sórí fọ́ọ̀mù S-3.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:
Jí! (Ìdìpọ̀ ti ọdún 2006)—Gẹ̀ẹ́sì
Ilé Ìṣọ́ (Ìdìpọ̀ ti ọdún 2006)—Gẹ̀ẹ́sì