Àpótí Ìbéèrè
◼ Ṣé ó yẹ ká kọ àdírẹ́sì táwa fúnra wa fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sórí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń fáwọn èèyàn lóde ẹ̀rí?
Àwọn akéde kan máa ń kọ àdírẹ́sì táwọn fúnra wọn fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sórí àwọn ìwé ìròyìn tàbí àṣàrò kúkúrú tí wọ́n ń fáwọn èèyàn lóde ẹ̀rí. Wọ́n máa ń fi òǹtẹ̀ tí wọ́n ti kọ àdírẹ́sì ọ̀hún sí lu àwọn ìwé ìròyìn wa tàbí kí wọ́n lẹ ìwé pélébé tó ní àdírẹ́sì ọ̀hún mọ́ ọn. Ìyẹn ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn tó gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà láti kọ̀wé sáwọn akéde ọ̀hún lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì fún àlàyé síwájú sí i. Òótọ́ ni pé kò sóhun tó burú nínú báwọn akéde wọ̀nyí ṣe ń fẹ́ ran àwọn tó fẹ́ gbọ́ ìhìn rere lọ́wọ́. Àmọ́, àdírẹ́sì ìkànnì tí “Watch Tower” ń lò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti wà lẹ́yìn àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn àṣàrò kúkúrú wa. Nítorí náà, ohun tó dáa jù ni pé ká má kọ àdírẹ́sì táwa fúnra wa fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sórí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa.
Tẹ́ ẹ bá sì wá fẹ́ fáwọn tẹ́ ẹ padà lọ bẹ̀ wò ní àdírẹ́sì tẹ́ ẹ fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ẹ lè pinnu láti kọ ọ́ sórí ìwé àjákọ. Àmọ́ ṣá o, ẹ má gbàgbé pé ojúṣe wa ni láti padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó gbọ́ ìhìn rere dípò ká máa retí pé kí wọ́n máa kọ̀wé béèrè fún ìsọfúnni síwájú sí i. Ó máa rọrùn fáwọn èèyàn láti fọkàn sóhun tá à ń bá wọn sọ, tá a bá wà pẹ̀lú wọn torí pé ojú lọ̀rọ̀ wà.