Yẹra fún Lílépa “Àwọn Ohun Tí Kò Ní Láárí”
1 Ọ̀nà kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lónìí sábà máa ń lò láti fi ìsọfúnni ránṣẹ́ ni E-mail, ìyẹn nípasẹ̀ kọ̀ǹpútà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó burú nínú sísọ àwọn ìrírí àtàwọn ọ̀ràn ara ẹni mìíràn fún ìdílé wa tàbí àwọn ọ̀rẹ́ nípasẹ̀ ọ̀nà yìí, “àwọn ohun tí kò ní láárí” wo ló ṣeé ṣe ká máa lépa nídìí lílo lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà láìníjàánu?—Òwe 12:11.
2 Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Ṣọ́ra fún Nípa Fífi Ìsọfúnni Ránṣẹ́ Lórí Kọ̀ǹpútà: Àwọn kan sọ pé àwọn máa ń nímọ̀lára pé àwọ́n túbọ̀ sún mọ́ ètò àjọ Jèhófà nígbà tí àwọ́n bá gba àwọn ìsọfúnni tí wọ́n kà sí tuntun nípasẹ̀ kọ̀ǹpútà. Lára ìsọfúnni ọ̀hún lè jẹ́ ìrírí, ìròyìn nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, ìròyìn nípa ìjábá tàbí inúnibíni, kódà ó tún lè jẹ́ àwọn ìsọfúnni tó ṣì jẹ́ àṣírí, èyí tí a kéde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ó jọ pé ara àwọn kan kì í balẹ̀ bí wọn kò bá tíì fi irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́, wọ́n máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé ẹnu wọn làwọn ọ̀rẹ́ wọn ti máa kọ́kọ́ gbọ́ irú ìròyìn bẹ́ẹ̀.
3 Nígbà míì, wọ́n máa ń bù mọ́ àwọn ìsọfúnni tàbí ìrírí náà tàbí kí wọ́n sọ ọ́ lásọdùn. Tàbí kẹ̀, níbi tí àwọn kan ti ń gbìyànjú láti mú kí ìròyìn ọ̀hún máa ṣeni ní kàyéfì kó sì ru ìmọ̀lára sókè, èrò èké gbáà ni wọ́n máa gbìn sọ́kàn àwọn tó gbà á. Àwọn tó máa ń hára gàgà láti ṣí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ payá kì í sábà mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn. (Òwe 29:20) Nínú àwọn ọ̀ràn kan, kódà bí ọ̀rọ̀ kan bá tiẹ̀ ṣòroó gbà gbọ́ pàápàá, wọ́n á ṣì fi ránṣẹ́ láti fi ṣe pé ojú àwọn ló tó o. Irú àwọn ìròyìn tí kò péye tàbí tó ń ṣini lọ́nà bẹ́ẹ̀ jẹ́ “àwọn ìtàn èké,” èyí tí kì í gbé ojúlówó ìfọkànsin Ọlọ́run lárugẹ.—1 Tím. 4:6, 7.
4 Bó o bá fi ìsọfúnni kan ránṣẹ́ síni àmọ́ tó wá lọ jẹ́ pé kò péye, ìwọ lo máa jẹ̀bi ìbànújẹ́ tàbí ìdàrúdàpọ̀ tí èyí bá dá sílẹ̀. Nígbà tí Dáfídì gba ìròyìn kan tó jẹ́ àbùmọ́ pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ńṣe ló “gbọn aṣọ ara rẹ̀ ya” nítorí ìdààmú ọkàn tó bá a. Àmọ́, ní ti gidi, ọ̀kan ṣoṣo lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ló kú. Ọ̀ràn ìbànújẹ́ lèyí náà lóòótọ́, ṣùgbọ́n, bíbù tí wọ́n bù mọ́ ọ̀rọ̀ yìí mú kí ẹ̀dùn ọkàn Dáfídì pọ̀ sí i. (2 Sám. 13:30-33) Ó dájú pé, a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó lè ṣi èyíkéyìí lára àwọn arákùnrin wa lọ́nà tàbí tó lè mú wọn rẹ̀wẹ̀sì.
5 Ipa Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Yàn fún Fífi Ìsọfúnni Ránṣẹ́: Rántí pé Baba wa ọ̀run ní ipa ọ̀nà kan tí òún ti yàn fún fífi ìsọfúnni ránṣẹ́, èyí ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” “Ẹrú” yẹn ló ni ẹrù iṣẹ́ láti pinnu irú ìsọfúnni tó yẹ kó pèsè fún àwọn tó wà nínú agboolé ìgbàgbọ́, àti “àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” láti pín in fún wọn. Kìkì ètò àjọ tí Ọlọ́run ń ṣàkóso nìkan ló lè pèsè oúnjẹ tẹ̀mí yìí. Ipa ọ̀nà tí Ọlọ́run yàn fún fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ yẹn ló yẹ ká máa gbára lé fún ìsọfúnni tó ṣeé fọkàn tẹ̀, dípò tí a ó fi máa gba ìsọfúnni látọ̀dọ̀ onírúurú èèyàn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Mát. 24:45.
6 Ibùdó Ìsọfúnni Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì: A ní Ibùdó Ìsọfúnni orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan tó bófin mu, èyí tí àdírẹ́sì rẹ̀ jẹ́: www.watchtower.org. Ibùdó ìsọfúnni yìí ti tó láti pèsè ìsọfúnni fún gbogbo èèyàn. Kò sídìí fún ẹnikẹ́ni, ìgbìmọ̀ èyíkéyìí, tàbí ìjọ èyíkéyìí láti tún lọ ṣètò ibùdó ìsọfúnni kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nítorí ọ̀ràn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn kan ti fi àwọn ìsọfúnni inú àwọn ìtẹ̀jáde wa pẹ̀lú gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtọ́kasí tá a ṣe nínú wọn ránṣẹ́, kódà wọ́n tilẹ̀ tún fi àwọn ẹ̀dà ìsọfúnni tó jẹ́ ti àpéjọ àgbègbè lọ àwọn tó fẹ́ ṣètọrẹ. Yálà èyí jẹ́ nítorí èrè tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣíṣe àdàkọ àwọn ìtẹ̀jáde Watchtower àti pípín wọn kiri nípasẹ̀ lílo àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ jẹ́ rírú òfin jíjẹ́-oníǹkan. Bí àwọn kan bá tilẹ̀ ka èyí sí pé ńṣe làwọ́n ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ará, a kò fọwọ́ sí i rárá, nítorí náà, ẹ gbọ́dọ̀ dáwọ́ àṣà yìí dúró.
7 Lílo ìfòyemọ̀ àti ìyèkooro èrò inú nígbà tá a bá ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti fi àwọn “ohun oníyelórí tí ó ṣeyebíye tí ó sì wuni” kún inú ọkàn wa.—Òwe 24:4.