Jọ̀wọ́ Tètè Lọ
Tètè lọ sọ́dọ̀ ta ni? Sọ́dọ̀ àwọn tó ń béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí tí wọ́n ní ká máa mú ìwé ìròyìn wá sọ́dọ̀ àwọn déédéé tàbí àwọn tó fẹ́ kí Ẹlẹ́rìí kan bẹ̀ wọ́n wò nílé wọn. Níbo làwọn ìbéèrè wọ̀nyí ti máa ń wá? Látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó ń kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí tẹlifóònù tàbí nípasẹ̀ àdírẹ́sì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nígbà táwọn kan bá fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn, ẹ̀ka iléeṣẹ́ máa ń sọ fún ìjọ tó wà ládùúgbò irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nípa lílo fọ́ọ̀mù S-70, ìyẹn fọ́ọ̀mù tó ní àkọlé náà, “Please Arrange for a Qualified Publisher to Call on This Person.” Bí àwọn alàgbà bá ti rí fọ́ọ̀mù S-70 náà gbà, kí wọ́n tètè fún akéde kan tó máa lè sa gbogbo ipá rẹ̀ láti túbọ̀ ran ẹni tó fìfẹ́ hàn náà lọ́wọ́. Bó bá ṣòro fún akéde náà láti bá ẹni náà nílé, ó lè gbìyànjú láti ké sí i lórí tẹlifóònù tàbí kó kọ àkọsílẹ̀ kékeré kan dè é lẹ́nu ọ̀nà àmọ́, kó fi ọgbọ́n ṣe èyí. Bí a bá ké sí ọ láti lọ bẹ ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn wò, jọ̀wọ́ rí i pé o tètè lọ bẹ ẹni náà wò.