Ó Yẹ Ká Tètè Wá Wọn Lọ
Látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo Ìkànnì wa tá a tún ṣe, iye àwọn tó ń béèrè pé ká wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti pọ̀ gan-an. Ọ̀nà tuntun tá a gbà ń wàásù láwọn ibi térò pọ̀ sí tún ń mú káwọn púpọ̀ sí i béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ sì la máa ṣiṣẹ́ lé e lórí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá lo ìkànnì jw.org láti béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lọ́pọ̀ ìgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì máa fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́ sí àwọn alàgbà tó ní ìpínlẹ̀ ìwàásù onítọ̀hún lẹ́yìn ọjọ́ méjì péré. Àmọ́, ìròyìn tá à ń rí gbà fi hàn pé nígbà míì, ẹnikẹ́ni kì í lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ ká wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́. Kí la lè ṣe ká lè ran àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kó tó pẹ́ jù?—Máàkù 4:14, 15.
Bí ẹnì kan tí kò gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín bá fẹ́ kí ẹnì kan wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kí o kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù padà-lọ-ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43) kó o sì rí i pé o fún akọ̀wé ìjọ yín ó pẹ́ tán ní ìpàdé tó kàn. Akọ̀wé ìjọ gbọ́dọ̀ fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì látorí ìkànnì jw.org ní ọjọ́ yẹn tàbí ní ọjọ́ kejì, kó lo apá tá a pè ní Congregation. Ó yẹ kí àwọn alàgbà máa yẹ Ìkànnì náà wò déédéé. Tí wọ́n bá ti rí ìsọfúnni gbà pé ẹnì kan fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kí wọ́n rán ẹnì kan lọ síbẹ̀. Akéde èyíkéyìí tí wọ́n bá rán lọ síbẹ̀ kò gbọ́dọ̀ fi falẹ̀ rárá. Tí ẹ ò bá bá onítọ̀hún nílé, ẹ lè kọ ìwé kan sílẹ̀ fún un, kí ẹ sì kọ bó ṣe lè kàn sí yín síbẹ̀.