Àpótí Ìbéèrè
◼ Ta ló yẹ kó kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó máa ń wà lẹ́yìn àwọn ìwé ìròyìn wa àti ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
Àwọn ìwé wa sábà máa ń ní fọ́ọ̀mù kan téèyàn lè kọ ọ̀rọ̀ sí, kó sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì láti béèrè ìwé tàbí kó ní kí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Láfikún sí i, ẹnì kan lè béèrè pé ká wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípasẹ̀ Ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì www.watchtower.org. Ìṣètò yìí máa ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́ ṣá o, ìṣòro máa ń tìdí ẹ̀ yọ bí àwọn akéde bá lo irinṣẹ́ yìí láti ṣètò bí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn míì á ṣe máa rí ìwé wa gbà tàbí pé kí ẹnì kan máa lọ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àwọn kan lára àwọn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fi ìwé tí wọn kò béèrè fún ránṣẹ́ sí máa ń ṣàròyé, wọ́n máa ń sọ pé ètò wa ń yọ àwọn lẹ́nu, pé a fi orúkọ àwọn sára àwọn tá a kàn lè máa fi ìwé ránṣẹ́ sí. Àwọn akéde tá a fún ní ìsọfúnni pé kí wọ́n lọ wo ẹnì kan tí kò dìídì sọ pé ká wá òun wá máa ń bá ara wọn ní ipò tí kò bára dé, nígbà tí onítọ̀hún kò bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n bá wá. Fún ìdí yìí, àwọn tí wọ́n bá fẹ́ gba ìwé tàbí tí wọ́n fẹ́ ká wá máa kọ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan la fẹ́ kó máa kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà tàbí sórí Ìkànnì wa, a kò fẹ́ kí àwọn akéde máa kọ ọ̀rọ̀ sí i lórúkọ àwọn ẹlòmíì. Tó bá hàn pé ẹnì kan ló kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà lórúkọ ẹlòmíì, a kò ní ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀.
Báwo wá la ṣe lè ran mọ̀lẹ́bí wa tàbí ojúlùmọ̀ wa lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí? Tó o bá fẹ́ kó gba ìwé wa, o lè kúkú fi ránṣẹ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ rẹ. Tí ẹni náà bá ti sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, tó sì fẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí wá òun wá, àmọ́ ti o kò mọ bó o ṣe lè kàn sí àwọn alàgbà ìjọ tó wà ní àdúgbò tí ẹni náà ń gbé, ńṣe ni kó o kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù pa dà lọ ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43), kó o sì fún akọ̀wé ìjọ rẹ, ó máa ṣàyẹ̀wò rẹ̀, á sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Àmọ́ bó bá jẹ́ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n, àtìmọ́lé, ibi tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn ọ̀daràn tàbí ilé ìwòsàn ìjọba ni ẹni náà wà, ẹ má ṣe kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì nítorí irú ẹni bẹ́ẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kẹ́ ẹ sọ fún un pé kó bá arákùnrin tó máa ń wá síbẹ̀ sọ̀rọ̀ tàbí kó fúnra rẹ̀ kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì.