ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/15 ojú ìwé 2
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ẹ Ṣọ́ra fún Ewu Tó Wà Níbẹ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Èé Ṣe Tí O Ní Láti Ṣọ́ra?
    Jí!—1997
  • Iṣẹ́ Ìpèsè àti Orísun Ìsọfúnni Ìsokọ́ra Alátagbà Internet
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 7/15 ojú ìwé 2

Àpótí Ìbéèrè

◼ Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn akéde máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fi wàásù fún àwọn tí wọn ò mọ̀ rí tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè míì tàbí kí wọ́n fi máa bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Àwọn akéde kan ti lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa tàbí tí àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ò tó nǹkan. Èyí sì ti yọrí sí rere láwọn ibì kan. Àmọ́, ó léwu tí àwọn akéde bá ń fi lẹ́tà orí íńtánẹ́ẹ̀tì ránṣẹ́ sí àwọn tí wọn ò mọ̀ rí tàbí tí wọ́n bá ń fèròwérò pẹ̀lú wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 2007, ojú ìwé 3.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé torí kí arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè bá àwọn tó lọ́kàn rere sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, síbẹ̀ irú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí kíkẹ́gbẹ́ kẹ́gbẹ́ àgàgà pẹ̀lú àwọn apẹ̀yìndà. (1 Kọ́r. 1:19-25; Kól. 2:8) Bákan náà, ní àwọn ilẹ̀ kan tí ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ wa, àwọn aláṣẹ lè máa ṣọ́ bí àwọn èèyàn ṣe ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́. Èyí sì lè ṣàkóbá fún àwọn ará tó wà lágbègbè náà. Torí náà, kò yẹ kí àwọn akéde máa fi Íńtánẹ́ẹ̀tì wá àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì tí wọ́n fẹ́ wàásù fún.

Tá a bá bá ẹnì kan tí a kò mọ̀ rí tó wá láti orílẹ̀-èdè míì sọ̀rọ̀ lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, kò yẹ ká máa wá bí a ó ṣe máa bá ìjíròrò náà lọ pẹ̀lú onítọ̀hún nígbà tó bá padà délé, àyàfi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lágbègbè náà bá ní ká ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká fi bó ṣe lè lo ìkànnì jw.org hàn-án kó lè fi wá ìsọfúnni síwájú sí i tàbí kó kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lágbègbè rẹ̀. A tún lè gbà á níyànjú pé kó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ilé rẹ̀. Àmọ́ o, Gbọ̀ngàn Ìjọba lè má sí láwọn orílẹ̀-èdè kan. Tí ẹni náà bá fẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ̀ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, ó yẹ ká kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò (S-43), ká sì fún akọ̀wé, akọ̀wé á wá lo ìkànnì jw.org láti fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè ẹni tá a bá sọ̀rọ̀ náà mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí lórílẹ̀-èdè wọn, ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí náà ló sì máa ran ẹni náà lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2014, ojú ìwé 7 àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2011, ojú ìwé 4.

Tí ẹni tí à ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ bá lọ sí orílẹ̀-èdè míì tàbí tí a bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti fi bá ẹnì kan tó wà ní orílẹ̀-èdè míì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ìtọ́ni tó wà nínú àwọn ìpínrọ̀ tó ṣáájú èyí ni a ó máa tẹ̀ lé. Àmọ́, a ṣì lè máa bá ẹni náà sọ̀rọ̀ títí dìgbà tí akéde kan tó wà lágbègbè rẹ̀ á fi kàn sí i. Bó ti wù kó rí, ó gba ìṣọ́ra gan-an tá a bá ń fi lẹ́tà, tẹlifóònù tàbí ọnà èyíkéyìí míì bá ẹni kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.—Mát. 10:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́