‘Kí Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ’
1. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2012, kí sì nìdí tó fi yẹ ká gbé kókó náà yẹ̀ wò?
1 Jèhófà dá wa nítorí ìfẹ́ rẹ̀. (Ìṣí. 4:11) Torí náà, kò lè ṣeé ṣe fún wa láti gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́, bí a kò bá kọ́kọ́ mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ká sì máa ṣe é. A lè máa wò ó pé kò sóhun tó le nínú ìyẹn, àmọ́ kì í ṣe ohun tó rọrùn, níwọ̀n ìgbà tá a bá ṣì ní láti jìjàkadì pẹ̀lú èrò inú wa láti ṣe “àwọn ohun tí ẹran ara fẹ́ àti ti àwọn ìrònú” tàbí láti ṣe “ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè.” (Éfé. 2:3; 1 Pét. 4:3; 2 Pét. 2:10) Láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a lè di ẹni tí Èṣù ‘mú láàyè láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.’ (2 Tím. 2:26) Àpéjọ àkànṣe wa ti ọdún 2012 máa ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ ká lè máa ṣe ohun tó bá ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ kẹta nínú àdúrà àwòṣe mu, ìyẹn, “kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.”—Mát. 6:9, 10.
2. Àwọn ìbéèrè wo la máa rí ìdáhùn sí ní àpéjọ náà?
2 Àwọn Ìbéèrè Tá A Máa Rí Ìdáhùn Sí: Bó o ṣe ń fọkàn bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lọ, wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí: Kí lohun míì tó tún ṣe pàtàkì bíi kéèyàn máa tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Báwo la ṣe lè máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ fún wa? Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti ran gbogbo onírúurú ènìyàn lọ́wọ́? Báwo la ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ tó sì dára jù lọ? Ẹ̀yin ọ̀dọ́, kí lẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ kó dá Jèhófà lójú nípa yín? Èrè wo ló wà nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú pé ká gbé àwọn míì ró, ká sì fún wọn ní ìṣírí?
3. Báwo la ṣe lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ní àpéjọ àkànṣe yìí?
3 Rí i dájú pé o wà níbẹ̀, kó o sì fọkàn sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà dáadáa. A máa ní àlejò tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tàbí alábòójútó arìnrìn-àjò. Kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn ìpàdé, o lè bá àlejò náà sọ̀rọ̀, tó bá sì ní ìyàwó, o lè bá òun àti ìyàwó rẹ̀ sọ̀rọ̀. Tó o bá pa dà délé, má ṣe di “olùgbọ́ tí ń gbàgbé,” àmọ́ ńṣe ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ̀ jọ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tẹ́ ẹ kọ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, kẹ́ ẹ sì jíròrò bẹ́ ẹ ṣe lè túbọ̀ máa ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.—Ják. 1:25.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa?
4 Láìpẹ́, àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ inú ara wọn, tí wọ́n sì kọ̀ láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà máa pa run. (1 Jòh. 2:17) Torí náà, a dúpẹ́ pé Jèhófà ti pèsè àwọn ìsọfúnni tó bọ́ sákòókò yìí kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa!