Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni
1. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àyíká ti ọdún 2014, àwọn ìbéèrè wo la sì máa rí ìdáhùn sí ní àpéjọ náà?
1 Jèhófà ni “Olùkọ́ni [wa] Atóbilọ́lá,” òun sì ni olùkọ́ tó dára jù lọ láyé àtọ̀run. (Aísá. 30:20, 21) Àmọ́, ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà kọ́ wa? Ó ti fún wa ní ìwé tí kò láfiwé, ìyẹn Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí. Báwo ni ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ṣe lè ṣe wá láǹfààní nípa tara, ní ti bí a ṣe ń ronú, ní ti ìmọ̀lára àti nípa tẹ̀mí? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí ní àpéjọ àyíká wa ti ọdún 2014. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ náà ni: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni.” A gbé e ka 2 Tímótì 3:16.
2. Àwọn ìbéèrè wo làwọn kókó pàtàkì tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà máa jẹ́ ká rí ìdáhùn sí?
2 Wá Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Yìí: Àwọn ìbéèrè yìí dá lé àwọn kókó pàtàkì tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà:
• Ipa wo ni àwọn ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa ń ní lórí ìgbésí ayé wa? (Aísá. 48:17, 18)
• Tí a bá sapá láti ṣe àwọn ìyípadà kan ká lè ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, kí ni Jèhófà fi dá wa lójú? (Mál. 3:10)
• Kí ló yẹ ká ṣe tí a bá bá ‘àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàjèjì’ pàdé? (Héb. 13:9)
• Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ‘ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́’? (Mát. 7:28, 29)
• Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo àwa tí à ń kọ́ni nínú ìjọ máa kọ́ ara wa? (Róòmù 2:21)
• Àwọn ọ̀nà wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè gbà ṣe wá láǹfààní? (2 Tím. 3:16)
• Ipa wo ni bí Ọlọ́run ṣe ń ‘mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì’ ń ní lórí àwọn èèyàn? (Hág. 2:6, 7)
• Kí ló dá Jèhófà lójú nípa wa? (Éfé. 5:1)
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sa gbogbo ipá wa ká lè dúró nínú ẹ̀kọ́ Jèhófà? (Lúùkù 13:24)
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà níbi àpéjọ tó bọ́ sákòókò yìí ká sì tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́?
3 Nínú 2 Tímótì orí kẹta, kí Pọ́ọ̀lù tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ yìí dá lé, ó ṣàlàyé àwọn àmì tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tím. 3:13) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run kí á sì máa fi ṣèwàhù kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣì wá lọ́nà! Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé a máa wà níbi àpéjọ tó bọ́ sákòókò yìí, a sì máa tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́.