Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 21
Orin 33 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 15 ìpínrọ̀ 13 sí 20 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Tẹsalóníkà 1-5–2 Tẹsalóníkà 1-3 (10 min.)
No. 1: 1 Tẹsalóníkà 2:9-20 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ẹ̀kọ́ Wo La Rí Kọ́ Nínú Àwọn Ohun Rere Àtohun Búburú Tí Sólómọ́nì Ṣe?—Róòmù 15:4 (5 min.)
No. 3: Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìṣẹ̀dá Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mu—td 29A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ka Máàkù 1:40-42, Máàkù 7:32-35 àti Lúùkù 8:43-48. Kẹ́ ẹ sì jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè wúlò fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
15 min: “Máa Lo Ìkànnì Wa Láti Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ṣàlàyé ibi tí àwọn ará ti lè rí apá tá a pè ní “Parents’ Guide” kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ìtọ́ni tí wọ́n lè rí níbẹ̀. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí àwọn ará sọ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí wọ́n ti gbà lo ìkànnì wa nígbà ìjọsìn ìdílé wọn.
Orin 88 àti Àdúrà