Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 30
Orin 5 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 9 ìpínrọ̀ 8 sí 20 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 14-16 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: “Ó Yẹ Ká Tètè Wá Wọn Lọ.” Àsọyé. Lẹ́yìn náà, lo àbá tó wà lójú ìwé 8 láti ṣe àṣefihàn ṣókí kan nípa bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù July.
20 min: Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ń Mú Ká Jẹ́ Òjíṣẹ́ Tó Dáńgájíá. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 27 sí 32. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan táwọn ará mọ̀ pé ó máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa.
Orin 69 àti Àdúrà