Bá A Ṣe Lè Lo Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò, Ìyẹn Please Follow Up (S-43)
Kó o kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù yìí nígbà tó o bá pàdé ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn, àmọ́ tí kì í gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, tàbí tó ń sọ èdè míì (ti orílẹ̀-èdè yín tàbí tilẹ̀ òkèèrè). Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ tá a bá ti pàdé àwọn èèyàn tó ń sọ èdè míì yálà wọ́n fìfẹ́ hàn tàbí wọn ò fìfẹ́ hàn, la máa ń lo fọ́ọ̀mù yìí, ní báyìí kìkì ìgbà tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá fìfẹ́ hàn nìkan la ó máa lò ó. Ohun tó kàn máa yàtọ̀ ni tẹ́ni náà bá jẹ́ adití. Tá a bá pàdé adití, yálà ó fìfẹ́ hàn tàbí kò fìfẹ́ hàn, a gbọ́dọ̀ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù S-43.
Kí la máa ṣe sí fọ́ọ̀mù náà lẹ́yìn tá a bá ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú rẹ̀? A ó mú un fún akọ̀wé ìjọ. Tó bá mọ ìjọ tó lè fi ránṣẹ́ sí, irú bí ìjọ tó ń sọ èdè yẹn lágbègbè wọn, ó lè kúkú fi ránṣẹ́ sí àwọn alàgbà ìjọ yẹn, kí wọ́n lè ṣètò bí wọ́n á ṣe ran ẹni tó fìfẹ́ hàn náà lọ́wọ́. Bí akọ̀wé kò bá mọ ìjọ tó lè fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí, kó fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì.
Bí ẹni tó fìfẹ́ hàn yìí bá ń sọ èdè míì, (ti orílẹ̀-èdè yín tàbí tilẹ̀ òkèèrè), tó sì jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìjọ yín ló ń gbé, ẹ lè máa pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ìfẹ́ tó ní lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, títí akéde tó gbọ́ èdè rẹ̀ láti ìjọ míì á fi kàn sí i. Nígbà míì, ó lè ṣẹlẹ̀ pé kò sí ìjọ kankan lágbègbè yín tó ń sọ èdè tí ẹni yẹn ń sọ. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ máa pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni náà láti mú kí ìfẹ́ rẹ̀ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, kẹ́ ẹ máa fún un ní àwọn ìtẹ̀jáde èyíkéyìí tó bá wà ní èdè rẹ̀, tó bá sì ṣeé ṣe kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹni náà.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù November 2009, ojú ìwé 4.