Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 30
Orin 33 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 4 ìpínrọ̀ 5 sí 12 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 26-33 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 31:9-24 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Tó Fi Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣèwà Hù Nínú Bíbélì (5 min.)
No. 3: Gbígba Ẹ̀jẹ̀ Sára Rú Òfin Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀—td 11A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti fi ṣàṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù June. Fún gbogbo àwọn ará ní ìṣírí láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀.
15 min: Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìwádìí. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 33 sí 38. Ṣe àṣefihàn akéde kan tó ń dá sọ̀rọ̀, kó máa lo àwọn ohun èlò tá a fi ń ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè tẹ́nì kan béèrè nígbà tó wà lóde ẹ̀rí.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn ní Oṣù June. Ìjíròrò. Láàárín ìṣẹ́jú kan sí méjì, mẹ́nu ba ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn tá a máa lò. Lẹ́yìn náà, kó o yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta nínú àwọn ìwé ìròyìn náà, kó o wá ní kí àwùjọ sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
Orin 113 àti Àdúrà