Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 23
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 23
Orin 39 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 4, àpótí tó wà lójú ìwé 33 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 19-25 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 23:1–24:10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Gbogbo Èèyàn Ni Bíbélì Wà Fún—td 8D (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Róòmù 8:21 Ṣe Máa Ní Ìmúṣẹ, Ìgbà Wo Ló sì Máa Ní Ìmúṣẹ? (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. “Bá A Ṣe Lè Lo Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò, Ìyẹn Please Follow Up (S-43).” Ìjíròrò.
10 min: Ohun Mẹ́ta Tó Lè Mú Kí Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Gbéṣẹ́. Àsọyé tá a gbé ka ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 2, ìpínrọ̀ 1. Lẹ́yìn tó o bá ti parí ìjíròrò náà, ṣe àṣefihàn méjì nípa bá a ṣe lè nasẹ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù June.
15 min: Ǹjẹ́ O Ti Gbìyànjú Ẹ̀ Wò? Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ àwọn àbá tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn àwọn àbá tó jáde nínú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Àwọn Àpilẹ̀kọ Tuntun Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” (km 12/10) àti “Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé” (km 1/11). Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà sílò àti àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí.
Orin 56 àti Àdúrà