ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/12 ojú ìwé 4-7
  • Bá A Ṣe Lè Kọ́kọ́ Wá Àwọn Èèyàn Ká Tó Wàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Kọ́kọ́ Wá Àwọn Èèyàn Ká Tó Wàásù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Wà Lójúfò Láti Wá Àwọn Adití Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Yín Rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Máa Ṣìkẹ́ Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Rẹ Tó Jẹ́ Adití!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Bíbójú Tó Àìní Tẹ̀mí Àwọn Adití
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 7/12 ojú ìwé 4-7

Bá A Ṣe Lè Kọ́kọ́ Wá Àwọn Èèyàn Ká Tó Wàásù

1. Láwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ onírúurú èdè, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìjọ tó bá gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan la máa ń yan ìpínlẹ̀ ìwàásù náà fún?

1 Lẹ́yìn tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Kristẹni, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀” fún àwọn tó wá síbẹ̀ láti apá ibi tó jìnnà lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣe 2:4) Èyí mú kí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn ṣe ìrìbọmi lọ́jọ́ náà. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ó jọ pé ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì tó wà níbẹ̀ ló tún ní èdè kan pàtó tí wọ́n jọ ń sọ, ìyẹn èdè Hébérù tàbí Gíríìkì. Síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ kí olúkúlùkù wọn gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà ní èdè abínibí wọn. Ìdí ni pé ìhìn rere náà tètè máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn tí wọ́n bá gbọ́ ọ ní èdè abínibí wọn. Torí náà, láwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ onírúurú èdè lóde òní, ìjọ tó bá gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan la máa ń yan ìpínlẹ̀ ìwàásù náà fún. (Wo ìwé A Ṣètò Wa ojú ìwé 107, ìpínrọ̀ 2 àti 3.) A kì í yan ìpínlẹ̀ ìwàásù fún àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń wàásù fún àwọn tó bá ń sọ èdè wọn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ tó ń ṣètìlẹ́yìn fún wọn àti ní ìpínlẹ̀ ìwàásù àwọn ìjọ míì lágbègbè wọn.

2. (a) Báwo la ṣe lè wá àwọn tó ń sọ oríṣi èdè kan pàtó, ibo ni irú iṣẹ́ yìí sì ti lè pọn dandan? (b) Báwo ni àwọn ìjọ ṣe lè ran ara wọn lọ́wọ́ láti jọ ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn èèyàn ti ń sọ onírúurú èdè? (d) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá pàdé ẹnì kan tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa, àmọ́ tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́?

2 Tó o bá ń gbé níbi tí àwọn èèyàn ti ń sọ èdè kan náà, ó lè rọrùn láti máa wàásù láti ilé dé ilé. Ṣùgbọ́n ìyẹn lè má ṣeé ṣe tó bá jẹ́ pé ìlú ńlá kan tí àwọn èèyàn ti ń sọ onírúurú èdè lò ń gbé. Àwọn ìjọ tó ń sọ èdè míì lè máa wàásù ní àdúgbò kan náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìjọ míì lè fún yín ní ìsọfúnni nípa àwọn tí wọ́n rí lóde ẹ̀rí, tó ń sọ èdè yín, ojúṣe ìjọ tàbí àwùjọ yín ni láti wá àwọn èèyàn tó ń sọ èdè yín kí ẹ lè wàásù fún wọn. (Wo àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Bá A Ṣe Lè Máa Ran Ara Wa Lọ́wọ́.”) Torí náà, tá a bá ń wá àwọn tó ń sọ oríṣi èdè kan, ó lè gba pé ká má wádìí lọ́wọ́ àwọn èèyàn tá a bá pàdé nípa àwọn tó ń sọ èdè yẹn. Ọ̀nà wo wá ni a lè gbà máa wá àwọn tó ń sọ oríṣi èdè kan pàtó?

3. Kí ló ń pinnu ibi tí ìjọ tàbí àwùjọ kan ti máa wá àwọn èèyàn àti bí iye àkókò tí wọ́n máa lò lẹ́nu iṣẹ́ náà ṣe máa pọ̀ tó?

3 Bá A Ṣe Lè Ṣètò Iṣẹ́ Náà: Iye àkókò tá a máa lò fún iṣẹ́ wíwá àwọn èèyàn láwọn ibi tí wọ́n ti ń sọ onírúurú èdè sinmi lórí bí ipò nǹkan bá ṣe rí lágbègbè kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn mélòó ló gbọ́ èdè náà ládùúgbò yẹn? Akéde mélòó ló ń gbé níbẹ̀? Àdírẹ́sì ẹni mélòó lára àwọn tó ń sọ èdè yẹn ni ìjọ tàbí àwùjọ náà ti ní lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀? Kò pọn dandan kí ìjọ máa lọ sí gbogbo àdúgbò tó bá wà lágbègbè wọn, àmọ́ wọ́n lè túbọ̀ máa lọ sí àwọn ibi táwọn èèyàn pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn àtàwọn ibi tó túbọ̀ jìnnà sí wọn díẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ó ṣe pàtàkì pé ká ní ètò tó mọ́yán lórí fún wíwá àwọn èèyàn kí á bàa lè fún àwọn èèyàn tó pọ̀ tó láǹfààní láti ké pe orúkọ Jèhófà.—Róòmù 10:13, 14.

4. (a) Báwo ni a ṣe lè ṣètò iṣẹ́ yìí? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà máa wá àwọn tó ń sọ èdè kan pàtó?

4 Kó má bàa di pé ibi tí àwọn kan ti ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ni a tún ń lọ, kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà, ní pàtàkì alábòójútó iṣẹ́ ìsìn, ṣètò tó mọ́yán lorí kó sì ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà bó ṣe yẹ. (1 Kọ́r. 9:26) Ní àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, arákùnrin tó bá tóótun ni kó máa ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà, á dáa kẹ́ni náà jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ tó ń ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ náà yàn. Tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ìjọ tó ń ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ kan lè ṣètò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé kí gbogbo ìjọ lápapọ̀ tẹ̀ lé àwùjọ yẹn lọ sóde ẹ̀rí láti jọ wá àwọn tó ń sọ èdè wọn.—Wo àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Bó O Ṣe Lè Wá Àwọn Tó Ń Sọ Oríṣi Èdè Kan Pàtó.”

5. (a) Àwọn àbá wo ló wà fún àwọn akéde tó fẹ́ lọ wá àwọn tó ń sọ oríṣi èdè kan pàtó? (b) Kí la lè sọ tá a bá ń wá àwọn tó ń sọ oríṣi èdè kan pàtó ní ìpínlẹ̀ wa?

5 Ó yẹ ká ní ohun kan lọ́kàn tá a fẹ́ ṣe bá a ṣe ń kópa nínú wíwá àwọn tó ń sọ èdè kan pàtó. Torí pé iṣẹ́ yìí jẹ́ ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ṣe ló yẹ ká múra bíi pé a fẹ́ lọ wàásù. Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé tí àwọn bá ń fi ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn dánra wò, tí àwọn sì ń sọ èdè náà nígbà táwọn bá ń wá àwọn èèyàn, ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn lè lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ náà kí àwọn sì túbọ̀ mọ èdè náà sọ dáadáa. A lè ròyìn àkókò tá a fi ń wá àwọn èèyàn, àmọ́ a kò ní ròyìn àkókò tá a lò láti fi ṣètò àwọn ibi tí a ti fẹ́ lọ wàásù. Tí a bá pàdé ẹni tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa, ká gbìyànjú láti wàásù fún un, lẹ́yìn náà, ká sọ fún alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí ẹni tó bá yàn nípa ẹni tá a pàdé yẹn kí wọ́n lè fi orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni náà kún èyí tó wà lọ́wọ́ wọn. Yálà ẹni yẹn nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tàbí kò nífẹ̀ẹ́ sí i, ó yẹ ká sọ nípa ẹni náà fún alábòójútó iṣẹ́ ìsìn wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ wíwá àwọn èèyàn tó ń sọ oríṣi èdè kan pàtó ṣe pàtàkì, síbẹ̀ kì í ṣe ìyẹn nìkan la máa wá gbájú mọ́, ó yẹ ká tún rí i pé à ń kópa nínú àwọn apá yòókù tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pín sí.—Wo àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ohun Tá A Lè Sọ Tá A Bá Ń Wá Àwọn Tó Ń Sọ Oríṣi Èdè Kan Pàtó.”

6. Àwọn ìṣòro wo la lè ní nígbà tá a bá ń wá àwọn adití?

6 Bí A Ṣe Lè Wá Àwọn Adití: Àwọn ìṣòro kan wà tá a lè ní nígbà tá a bá ń wá àwọn tó jẹ́ adití ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, torí náà, èyí máa ń gba ìsapá tó ṣàrà ọ̀tọ̀, a ò sì ní jẹ́ kó sú wa. Pé èèyàn rí ẹnì kan tó ń fọwọ́ sọ orúkọ rẹ̀ kò fi hàn pé adití ni ẹni náà, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrísí tàbí ìmúra ẹnì kan kò tó láti fi hàn pé ó jẹ́ adití. Nítorí ìtìjú tàbí torí pé àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ àwọn tó jẹ́ adití kì í fẹ́ kí nǹkan tí kò dáa ṣẹlẹ̀ sí adití náà, wọ́n lè máa lọ́ tìkọ̀ láti sọ nípa adití náà fún àwọn akéde tó bá wá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn. Àwọn ìsọfúnni tó tẹ̀ lé e yìí wà fún àwọn tó bá ń wá àwọn adití, àmọ́ ó tún wúlò nígbà tá a bá ń wá àwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa.

7. (a) Báwo la ṣe lè béèrè nípa àwọn adití níbi tí ilé gbígbé pọ̀ sí? (b) Kí ni ohun tá a lè ṣe tí àwọn onílé kò fi ni máa fura sí wá?

7 Ìsapá tí àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ kan tó ń sọ èdè àwọn adití ṣe láti wá àwọn adití níbi tí ilé gbígbé pọ̀ sí ti kẹ́sẹ járí. O lè béèrè lọ́wọ́ onílé bóyá ó mọ ẹnì kan nínú ilé náà, ní àdúgbò yẹn, níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé rẹ̀ tó gbọ́ èdè àwọn adití. Ó ṣeé ṣe kó ti rí àmì kan lójú ọ̀nà tó jẹ́ kó mọ ibi tí àwọn adití wà. Ó sì lè ní mọ̀lẹ́bí kan tó jẹ́ adití. Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé àwọn èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí wa nípa wíwá tí à ń wá àwọn adití. Àmọ́ a lè fi onílé náà lọ́kàn balẹ̀ tá a bá bá a sọ̀rọ̀ bí ẹni bá ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀, tí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí, tá a sì ṣàlàyé ìdí tá a fi ń wá àwọn adití fún un. Àwọn kan máa ń fi fídíò Bíbélì tá a ṣe lédè àwọn adití tàbí àwọn ìtẹ̀jáde míì tó wà lórí àwo DVD ní èdè àwọn adití han onílé nígbà tí wọ́n bá ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó mọ ibi tí àwọn adití wà, èyí sì ti sèso rere. Lẹ́yìn náà ni wọ́n á sọ fún onílé pé àwọn fẹ́ bá àwọn adití náà sọ̀rọ̀ tó ń fúnni nírètí látinú Bíbélì. Tí onílé náà bá lọ́ tìkọ̀ láti sọ bá a ṣe lè rí àwọn adití, a lè fún un ní àdírẹ́sì wa tàbí ìwé ìkésíni wá sí ìpàdé ìjọ pé kó fún ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó bá jẹ́ adití.

8. Báwo ni àwọn ìjọ tó wà nítòsí ṣe lè ran àwọn ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití lọ́wọ́?

8 Ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀méjì lọ́dún, ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití lè ṣètò pé kí ìjọ tó bá wà nítòsí wọn tó ń sọ èdè míì wá ran àwọn lọ́wọ́ láti jọ wá àwọn adití ní àwọn ibi tí àwọn èèyàn pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn tó gbòòrò. Ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití ló máa darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, wọ́n lè ṣe àṣefihàn, kí wọ́n sì tún pèsè ìtọ́ni nípa iṣẹ́ náà. Akéde kan, ó kéré tán, látinú ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití lè wà nínú àwọn àwùjọ kéékèèké tẹ́ ẹ bá pín àwọn ará sí, ẹ sì lè fún un ní káàdì ìpínlẹ̀ tí àwùjọ náà ti máa lọ wàásù.

9. Báwo ni a ṣe lè ṣe iṣẹ́ yìí láwọn ibi tí àwọn adití máa ń kóra jọ sí láti ṣèpàdé tàbí ṣeré ìtura àti láwọn ibi tí wọ́n ti máa ń lọ gba ìrànlọ́wọ́?

9 A tún lè wá àwọn adití lọ sáwọn ibi tí wọ́n máa ń kóra jọ sí láti ṣèpàdé tàbí ṣeré ìtura àtàwọn ibi tí wọ́n ti máa ń lọ gba ìrànlọ́wọ́. Ó yẹ kí àwọn akéde múra lọ́nà tó bá ipò ibi tí wọ́n ti fẹ́ lọ wàásù mu. Á dáa ká lo ìfòyemọ̀ níbi tí àwọn èèyàn bá pọ̀ sì, ká bá ẹnì kan tàbí méjì lára wọn sọ̀rọ̀ dípò ká darí ọ̀rọ̀ wa sí àwùjọ yẹn lápapọ̀. Tí ẹni náà bá sì fìfẹ́ hàn, ká gba àdírẹ́sì rẹ̀ tàbí nọ́ńbà fóònù rẹ̀, ká sì fún un ní tiwa.

10. Báwo ni a ṣe lè ṣe iṣẹ́ yìí ní àwọn ibi ìṣòwò?

10 Láwọn ibi ìṣòwò kan, a lè béèrè bóyá wọ́n mọ àwọn oníbàárà wọn tó gbọ́ èdè àwọn adití. Tí ilé ẹ̀kọ́ àwọn adití bá wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, a lè fún wọn ní díẹ̀ lára àwọn ìtẹ̀jáde wa tó wà lédè àwọn adití tá a ṣe sórí àwo DVD pé kí wọ́n fi síbi ìkówèésí wọn.

11. Kí nìdí tí wíwá àwọn tó ń sọ oríṣi èdè kan pàtó fi jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì lára iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

11 Iṣẹ́ Pàtàkì Ni: Wíwá àwọn adití tàbí àwọn tó ń sọ oríṣi èdè kan pàtó jẹ́ iṣẹ́ tó máa ń gba àkókò. Àwọn èèyàn látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà ló máa ń wà láwọn àdúgbò míì torí bí àwọn kan ṣe ń kúrò níbẹ̀ ni àwọn míì ń kó wá síbẹ̀, èyí máa ń mú kó ṣòro láti ní ìsọfúnni tó kún rẹ́rẹ́ nípa irú ìpínlẹ̀ ìwàásù bẹ́ẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, láwọn ibi tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, apá pàtàkì lára iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni iṣẹ́ wíwá àwọn èèyàn tó ń sọ èdè kan pàtó jẹ́. Jèhófà tó gbé iṣẹ́ ìwàásù yìí lé wa lọ́wọ́ kì í ṣe ojúṣàájú. (Ìṣe 10:34) ‘Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’ (1 Tím. 2:3, 4) Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ara wa, ká lè rí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo tó ní “ọkàn-àyà àtàtà àti rere.”—Lúùkù 8:15.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Bá A Ṣe Lè Máa Ran Ara Wa Lọ́wọ́

Bí ìjọ tàbí àwùjọ kan bá máa nílò ìrànlọ́wọ́ láti wá àwọn tó ń sọ èdè kan pàtó tí wọ́n máa wàásù fún, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ìjọ tàbí àwùjọ náà lè kàn sí àwọn alàgbà tó wà ní àwọn ìjọ tó ń sọ èdè míì nítòsí wọn. Ohun tó máa dáa jù ni pé kẹ́ ẹ kàn sí kìkì àwọn ìjọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí yín tàbí tó ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè yẹn wà. Lẹ́yìn náà, àwọn ìjọ tí wọ́n bá kàn sí máa wá sọ fún àwọn akéde wọn pé kí wọ́n kọ àdírẹ́sì ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí tó ń sọ èdè náà, kí wọ́n sì fún alábòójútó iṣẹ́ ìsìn wọn kó bàa lè fi ránṣẹ́ sí ìjọ tàbí àwùjọ tó nílò ìrànlọ́wọ́ yín. Àwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn àwọn ìjọ tọ́rọ̀ náà kàn lè jọ ṣètò bí wọ́n á ṣe jọ máa ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n ti ń sọ onírúurú èdè, tí wọ́n á sì máa darí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ sí ìjọ tàbí àwùjọ tó bá yẹ.

Tí àwọn akéde bá pàdé ẹnì kan tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn, àmọ́ tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ (tàbí tí wọ́n bá pàdé ẹnì kan tó jẹ́ adití), kí wọ́n tètè kọ ìsọfúnni tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù padà-lọ-ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43), kí wọ́n sì fún akọ̀wé ìjọ wọn ní fọ́ọ̀mù náà. Èyí á jẹ́ kí ẹni náà lè tètè rí ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tó yẹ gbà.—Wo km 5/11 ojú ìwé 3.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Bó O Ṣe Lè Wá Àwọn Tó Ń Sọ Oríṣi Èdè Kan Pàtó

• Wádìí lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì, béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìbátan rẹ, àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn míì.

• Fọgbọ́n wádìí láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń lò sí, irú bí ilé ìkàwé tó wà ládùúgbò, àwọn ọ́fíìsì ìjọba tàbí àwọn ilé ẹ̀kọ́ girama.

• Ka àwọn ìwé ìròyìn bóyá o lè rí ìsọfúnni nípa àwọn ohun tí àwọn tó ń sọ oríṣi èdè kan fẹ́ ṣe.

• Lọ sí àwọn ilé ìtajà àtàwọn ibi ìṣòwò tí àwọn tó ń sọ àwọn èdè ilẹ̀ òkèèrè máa ń lò sí.

• Ẹ lè gba àyè lọ́dọ̀ àwọn tó ń bójú tó ibi ìṣòwò, ilé ẹ̀kọ́ gíga tàbí ibùdókọ̀ táwọn tó ń sọ èdè náà máa ń lò sí láti gbé tábìlì kan kalẹ̀ níbẹ̀ tẹ́ ẹ máa fi to àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa sí fún àwọn tó bá gbọ́ èdè náà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Ohun Tá A Lè Sọ Tá A Bá Ń Wá Àwọn Tó Ń Sọ Oríṣi Èdè Kan Pàtó

Tá a bá sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, tí a sì sọ ohun tá a ní lọ́kàn lọ́nà tó ṣe tààràtà, ìyẹn kò ní jẹ́ káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí wa. Ó máa ń dáa tá a bá kọ́kọ́ fi ìwé ìròyìn tó wà lédè yẹn hàn wọ́n.

Lẹ́yìn tí a bá ti kí onílé, a lè sọ pé: “À ń wá àwọn tó ń sọ èdè ․․․․․ ká lè bá wọn sọ̀rọ̀ tó ń fúnni nírètí látinú Bíbélì. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kankan tó ń sọ èdè yẹn?”

Tó bá jẹ́ àwọn adití ni à ń wá, lẹ́yìn tá a bá ti kí onílé, a lè sọ pé: “Ǹjẹ́ mo lè fi fídíò yìí hàn ọ́? [O lè lo ẹ̀rọ kékeré kan tá a fi ń wo fídíò láti fi ẹsẹ Bíbélì kan hàn án látinú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà lórí àwo DVD.] Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà la fi ka Bíbélì sórí àwo yìí. Yàtọ̀ sí èyí, a tún ní àwọn ìtẹ̀jáde míì tá a ṣe sórí àwo DVD láti fi ran àwọn adití lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. A kì í ta àwọn fídíò náà. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kankan tó jẹ́ adití tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́rọ̀ dáadáa tó sì gbọ́ èdè àwọn adití?” Tí onílé náà kò bá rántí ẹnì kankan, a lè fún un ní àpẹẹrẹ àwọn ibi tó ṣeé ṣe kó ti rí àwọn tó jẹ́ adití bóyá níbi iṣẹ́, nílé ẹ̀kọ́ tàbí ládùúgbò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́