ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/01 ojú ìwé 1
  • Wà Lójúfò Láti Wá Àwọn Adití Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Yín Rí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wà Lójúfò Láti Wá Àwọn Adití Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Yín Rí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Jèhófà Ti Mú Kí Ojú Rẹ̀ Tàn sí Wọn Lára’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Máa Ṣìkẹ́ Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Rẹ Tó Jẹ́ Adití!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jèhófà Fi Èrè sí Iṣẹ́ Mi
    Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àwọn Adití Ń yin Jèhófà
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 6/01 ojú ìwé 1

Wà Lójúfò Láti Wá Àwọn Adití Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Yín Rí

1 Jèhófà ń ṣe ìkésíni náà pé: “‘Máa bọ̀!’ . . . Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣí. 22:17) Ńṣe ni iye àwọn adití tó wà lára àwọn tó ń dáhùn sí ìkésíni yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí èyí, láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá, a ti dá àwọn àwùjọ kan tó ń sọ èdè àwọn adití sílẹ̀ ní Nàìjíríà.

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí àwọn àwùjọ tí ń sọ èdè àwọn adití gbájú mọ́ ni wíwàásù fún àwọn adití tàbí àwọn tí kò lè gbọ́ràn dáadáa tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ ìjọ tí a yan àwọn àwùjọ náà sí, ọ̀pọ̀ irú àwọn bẹ́ẹ̀ ṣì wà ní orílẹ̀-èdè yìí tí a ṣì ní láti wá rí kí a sì wàásù fún wọn.

3 Báwo Lo Ṣe Lè Ṣèrànwọ́? Nígbà tí o bá wà níbi táwọn èèyàn wà, ǹjẹ́ o ti kíyè sí i táwọn èèyàn ń sọ èdè àwọn adití? Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan níbi iṣẹ́ rẹ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́ rẹ tí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ̀ jẹ́ adití? Wà lójúfò láti máa ṣàwárí àwọn tó jẹ́ adití bí o ti ń bá ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ rẹ nìṣó. Ṣùgbọ́n báwo lo ṣe lè rí i dájú pé a jẹ́rìí fún wọn nípa Ìjọba náà?

4 Jíjẹ́rìí fún Wọn: Sọ ibi tí adití náà wà fún àwùjọ tí ń sọ èdè àwọn adití tó sún mọ́ ọ jù lọ. Ọ̀pọ̀ adití lo máa ń tètè tẹ̀ síwájú nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà tí wọ́n bá lè péjọ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ adití nínú ìjọ níbi tí a ti ń túmọ̀ àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà. Nítorí náà, bí àwùjọ kan tí ń sọ èdè adití bá wà ní àdúgbò yín, kí akọ̀wé ìjọ yín fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí ìjọ wọn nípa gbogbo adití tó wà ní ìpínlẹ̀ yín.

5 Ká wá ní kò sí ẹnikẹ́ni nítòsí tí yóò ran àwọn adití tó wà ní àgbègbè rẹ lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí ńkọ́? Báwo lo ṣe lè ṣèrànwọ́? Kí nìdí tí o kò fi ṣe ìpadàbẹ̀wò kí o sì bá àwọn tó lè gbọ́ràn nínú ilé wọn sọ̀rọ̀? Sọ pé o fẹ́ ṣàfihàn fídíò tó lo èdè adití kí o lè fi ru ìfẹ́ adití náà sókè. Àní àwọn akéde kan tiẹ̀ ti kọ́ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà kí wọ́n lè túbọ̀ máa bá àwọn adití jíròrò dáadáa. (Ìṣe 16:9, 10) Fídíò ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀ wà ní Èdè Àwọn Adití lọ́nà ti Amẹ́ríkà. Dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní lílo àwọn irinṣẹ́ wọ̀nyí ti mú ọ̀pọ̀ àbájáde rere wá.

6 Nípa wíwà lójúfò láti wá àwọn adití tó wà ní àgbègbè rẹ rí, o lè mú kí wọ́n láǹfààní láti gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.—Mát. 10:11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́