ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 23
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2011 | May
    • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 23

      Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 23

      Orin 39 àti Àdúrà

      □ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

      bt orí 4, àpótí tó wà lójú ìwé 33 (25 min.)

      □ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

      Bíbélì kíkà: Sáàmù 19-25 (10 min.)

      No. 1: Sáàmù 23:1–24:10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

      No. 2: Gbogbo Èèyàn Ni Bíbélì Wà Fún—td 8D (5 min.)

      No. 3: Báwo Ni Róòmù 8:21 Ṣe Máa Ní Ìmúṣẹ, Ìgbà Wo Ló sì Máa Ní Ìmúṣẹ? (5 min.)

      □ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

      Orin 78

      10 min: Àwọn Ìfilọ̀. “Bá A Ṣe Lè Lo Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò, Ìyẹn Please Follow Up (S-43).” Ìjíròrò.

      10 min: Ohun Mẹ́ta Tó Lè Mú Kí Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Gbéṣẹ́. Àsọyé tá a gbé ka ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 2, ìpínrọ̀ 1. Lẹ́yìn tó o bá ti parí ìjíròrò náà, ṣe àṣefihàn méjì nípa bá a ṣe lè nasẹ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù June.

      15 min: Ǹjẹ́ O Ti Gbìyànjú Ẹ̀ Wò? Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ àwọn àbá tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn àwọn àbá tó jáde nínú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Àwọn Àpilẹ̀kọ Tuntun Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì” (km 12/10) àti “Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé” (km 1/11). Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà sílò àti àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí.

      Orin 56 àti Àdúrà

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 30
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2011 | May
    • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 30

      Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 30

      Orin 33 àti Àdúrà

      □ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

      bt orí 4 ìpínrọ̀ 5 sí 12 (25 min.)

      □ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

      Bíbélì kíkà: Sáàmù 26-33 (10 min.)

      No. 1: Sáàmù 31:9-24 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

      No. 2: Àwọn Tó Fi Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣèwà Hù Nínú Bíbélì (5 min.)

      No. 3: Gbígba Ẹ̀jẹ̀ Sára Rú Òfin Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀—td 11A (5 min.)

      □ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

      Orin 38

      10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti fi ṣàṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù June. Fún gbogbo àwọn ará ní ìṣírí láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

      15 min: Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìwádìí. Ìjíròrò tó dá lórí ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 33 sí 38. Ṣe àṣefihàn akéde kan tó ń dá sọ̀rọ̀, kó máa lo àwọn ohun èlò tá a fi ń ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè tẹ́nì kan béèrè nígbà tó wà lóde ẹ̀rí.

      10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn ní Oṣù June. Ìjíròrò. Láàárín ìṣẹ́jú kan sí méjì, mẹ́nu ba ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn tá a máa lò. Lẹ́yìn náà, kó o yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta nínú àwọn ìwé ìròyìn náà, kó o wá ní kí àwùjọ sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.

      Orin 113 àti Àdúrà

  • Bá A Ṣe Lè Lo Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò, Ìyẹn Please Follow Up (S-43)
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2011 | May
    • Bá A Ṣe Lè Lo Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò, Ìyẹn Please Follow Up (S-43)

      Kó o kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù yìí nígbà tó o bá pàdé ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn, àmọ́ tí kì í gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, tàbí tó ń sọ èdè míì (ti orílẹ̀-èdè yín tàbí tilẹ̀ òkèèrè). Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ tá a bá ti pàdé àwọn èèyàn tó ń sọ èdè míì yálà wọ́n fìfẹ́ hàn tàbí wọn ò fìfẹ́ hàn, la máa ń lo fọ́ọ̀mù yìí, ní báyìí kìkì ìgbà tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá fìfẹ́ hàn nìkan la ó máa lò ó. Ohun tó kàn máa yàtọ̀ ni tẹ́ni náà bá jẹ́ adití. Tá a bá pàdé adití, yálà ó fìfẹ́ hàn tàbí kò fìfẹ́ hàn, a gbọ́dọ̀ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù S-43.

      Kí la máa ṣe sí fọ́ọ̀mù náà lẹ́yìn tá a bá ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú rẹ̀? A ó mú un fún akọ̀wé ìjọ. Tó bá mọ ìjọ tó lè fi ránṣẹ́ sí, irú bí ìjọ tó ń sọ èdè yẹn lágbègbè wọn, ó lè kúkú fi ránṣẹ́ sí àwọn alàgbà ìjọ yẹn, kí wọ́n lè ṣètò bí wọ́n á ṣe ran ẹni tó fìfẹ́ hàn náà lọ́wọ́. Bí akọ̀wé kò bá mọ ìjọ tó lè fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí, kó fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì.

      Bí ẹni tó fìfẹ́ hàn yìí bá ń sọ èdè míì, (ti orílẹ̀-èdè yín tàbí tilẹ̀ òkèèrè), tó sì jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìjọ yín ló ń gbé, ẹ lè máa pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ìfẹ́ tó ní lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, títí akéde tó gbọ́ èdè rẹ̀ láti ìjọ míì á fi kàn sí i. Nígbà míì, ó lè ṣẹlẹ̀ pé kò sí ìjọ kankan lágbègbè yín tó ń sọ èdè tí ẹni yẹn ń sọ. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ máa pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni náà láti mú kí ìfẹ́ rẹ̀ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, kẹ́ ẹ máa fún un ní àwọn ìtẹ̀jáde èyíkéyìí tó bá wà ní èdè rẹ̀, tó bá sì ṣeé ṣe kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹni náà.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù November 2009, ojú ìwé 4.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́